Mat 27:1-14
Mat 27:1-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBATI o di owurọ̀, gbogbo awọn olori alufa ati awọn àgbãgba gbìmọ si Jesu lati pa a: Nigbati nwọn si dè e tan, nwọn mu u lọ, nwọn si fi i le Pontiu Pilatu lọwọ ti iṣe Bãlẹ. Nigbana ni Judasi, ẹniti o fi i hàn, nigbati o ri pe a dá a lẹbi, o ronupiwada, o si mu ọgbọ̀n owo fadaka na pada wá ọdọ awọn olori alufa ati awọn àgbãgba. O wipe, emi ṣẹ̀ li eyiti mo fi ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ hàn. Nwọn si wipe, Kò kàn wa, mã bojuto o. O si dà owo fadaka na silẹ ni tẹmpili, o si jade, o si lọ iso. Awọn olori alufa si mu owo fadaka na, nwọn si wipe, Ko tọ́ ki a fi i sinu iṣura, nitoripe owo ẹ̀jẹ ni. Nwọn si gbìmọ, nwọn si fi rà ilẹ amọ̀koko, lati ma sinkú awọn alejò ninu rẹ̀. Nitorina li a ṣe npè ilẹ na ni Ilẹ ẹ̀jẹ, titi di ọjọ oni. Nigbana li eyi ti Jeremiah wolĩ sọ wá ṣẹ, pe, Nwọn si mu ọgbọ̀n owo fadaka na, iye owo ẹniti a diyele, ẹniti awọn ọmọ Israeli diyele; Nwọn si fi rà ilẹ, amọ̀koko, gẹgẹ bi Oluwa ti làna silẹ fun mi. Jesu si duro niwaju Bãlẹ: Bãlẹ si bi i lẽre, wipe, Iwọ ha li Ọba awọn Ju? Jesu si wi fun u pe, Iwọ wi i. Nigbati a si nkà si i lọrùn lati ọwọ́ awọn olori alufa, ati awọn àgbãgba wá, on kò dahùn kan. Nigbana ni Pilatu wi fun u pe, Iwọ ko gbọ́ ọ̀pọ ohun ti nwọn njẹri si ọ? On kò si dá a ni gbolohun kan; tobẹ̃ ti ẹnu yà Bãlẹ gidigidi.
Mat 27:1-14 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, gbogbo àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbà ìlú jọ forí-korí nípa ọ̀ràn Jesu, kí wọ́n lè pa á. Wọ́n dè é, wọ́n bá fà á lọ láti fi lé Pilatu, gomina, lọ́wọ́. Nígbà tí Judasi, ẹni tí ó fi Jesu fún àwọn ọ̀tá rí i pé a dá Jesu lẹ́bi, ó ronupiwada. Ó bá lọ dá ọgbọ̀n owó fadaka pada fún àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbà. Ó ní, “Mo ṣẹ̀ ní ti pé mo ṣe ikú pa aláìṣẹ̀.” Wọ́n bá dá a lóhùn pé, “Èwo ló kàn wá ninu rẹ̀? Ẹjọ́ tìrẹ ni.” Judasi bá da owó náà sílẹ̀ ninu Tẹmpili, ó jáde, ó bá lọ pokùnso. Àwọn olórí alufaa mú owó fadaka náà, wọ́n ní, “Kò tọ́ fún wa láti fi í sinu àpò ìṣúra Tẹmpili mọ́ nítorí owó ẹ̀jẹ̀ ni.” Lẹ́yìn tí wọ́n ti forí-korí, wọ́n fi owó náà ra ilẹ̀ amọ̀kòkò fún ìsìnkú àwọn àlejò. Ìdí nìyí ti a fi ń pe ilẹ̀ náà ní, “Ilẹ̀ ẹ̀jẹ̀” títí di òní olónìí. Báyìí ni ohun tí wolii Jeremaya, wí ṣẹ, nígbà tí ó sọ pé, “Wọ́n mú ọgbọ̀n owó fadaka náà, iye tí a dá lé orí ẹ̀mí náà, nítorí iye tí àwọn ọmọ Israẹli ń dá lé eniyan lórí nìyí, wọ́n lo owó náà fún ilẹ̀ amọ̀kòkò, gẹ́gẹ́ bí Oluwa ti pàṣẹ fún mi.” Jesu bá dúró siwaju gomina. Gomina bi í pé, “Ìwọ ni ọba àwọn Juu bí?” Jesu ní, “O ti fi ẹnu ara rẹ sọ ọ́.” Ṣugbọn bí àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbà ti ń fi ẹ̀sùn kàn án tó, kò fèsì rárá. Nígbà náà ni Pilatu sọ fún un pé, “O kò gbọ́ irú ẹ̀sùn tí wọn ń fi kàn ọ́ ni?” Ṣugbọn Jesu kò dá a lóhùn gbolohun kan ṣoṣo, tí ó fi jẹ́ pé ẹnu ya gomina pupọ.
Mat 27:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní òwúrọ̀, gbogbo àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà Júù tún padà láti gbìmọ̀ bí wọn yóò ti ṣe pa Jesu. Lẹ́yìn èyí, wọ́n fi ẹ̀wọ̀n dè é, wọ́n sì jọ̀wọ́ rẹ̀ fún Pilatu tí i ṣe gómìnà. Nígbà tí Judasi, ẹni tí ó fi í hàn, rí i wí pé a ti dá a lẹ́bi ikú, ó yí ọkàn rẹ̀ padà, ó sì káàánú nípa ohun tí ó ṣe. Ó sì mú ọgbọ̀n owó fàdákà tí ó gba náà wá fún àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà Júù. Ó wí pé, “Mo ti ṣẹ̀ nítorí tí mo ti ta ẹ̀jẹ̀ aláìlẹ́ṣẹ̀ sílẹ̀.” Wọ́n dá a lóhùn pẹ̀lú ìbínú pé, “Èyí kò kàn wá! Wàhálà tìrẹ ni!” Nígbà náà ni Judasi da owó náà sílẹ̀ nínú tẹmpili. Ó jáde, ó sì lọ pokùnso. Àwọn olórí àlùfáà sì mú owó náà. Wọ́n wí pé, “Àwa kò lè fi owó yìí sínú owó ìkójọpọ̀. Ní ìwọ̀n ìgbà tí ó lòdì sí òfin wa nítorí pé owó ẹ̀jẹ̀ ni.” Wọ́n sì gbìmọ̀, wọ́n sì fi ra ilẹ̀ amọ̀kòkò, láti máa sin òkú àwọn àjèjì nínú rẹ̀. Ìdí nìyìí tí à ń pe ibi ìsìnkú náà ní “Ilẹ̀ Ẹ̀jẹ̀” títí di òní. Èyí sì jẹ́ ìmúṣẹ èyí tí a ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu wòlíì Jeremiah wí pé, “Wọ́n sì mú ọgbọ̀n owó fàdákà tí àwọn ènìyàn Israẹli díye lé e. Wọ́n sì fi ra ilẹ̀ kan lọ́wọ́ àwọn amọ̀kòkò gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ.” Nígbà náà ni Jesu dúró níwájú baálẹ̀ láti gba ìdájọ́. Baálẹ̀ sì béèrè pé, “Ṣe ìwọ ni ọba àwọn Júù?” Jesu dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, nítorí tí ìwọ wí i.” Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà Júù fi gbogbo ẹ̀sùn wọn kàn án, Jesu kò dáhùn kan. Nígbà náà ni Pilatu, béèrè lọ́wọ́ Jesu pé, “Àbí ìwọ kò gbọ́ ẹ̀rí tí wọn ń wí nípa rẹ ni?” Jesu kò sì tún dáhùn kan. Èyí sì ya baálẹ̀ lẹ́nu.