Mat 26:6-10
Mat 26:6-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati Jesu si wà ni Betani ni ile Simoni adẹtẹ̀, Obinrin kan tọ̀ ọ wá ti on ti ìgò ororo ikunra alabasta iyebiye, o si ndà a si i lori, bi o ti joko tì onjẹ. Ṣugbọn nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ri i, inu wọn ru, nwọn wipe, Nitori kili a ṣe nfi eyi ṣòfo? A ba sá tà ikunra yi ni owo iyebiye, a ba si fifun awọn talakà. Nigbati Jesu mọ̀, o wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi mba obinrin na wi? nitori iṣẹ rere li o ṣe si mi lara.
Mat 26:6-10 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Jesu wà ní Bẹtani, ninu ilé Simoni tí ó dẹ́tẹ̀ nígbà kan rí, obinrin kan wọlé tọ̀ ọ́ wá tí ó ní ìgò òróró iyebíye olóòórùn dídùn, ni ó bá bẹ̀rẹ̀ sí tú u sí orí Jesu níbi tí ó ti ń jẹun. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu rí i, inú bí wọn. Wọ́n ní, “Kí ni ìdí irú òfò báyìí? Nítorí títà ni à bá ta òróró yìí ní owó iyebíye tí à bá fi fún àwọn talaka.” Jesu mọ ohun tí wọn ń sọ, nítorí náà, ó wí fún wọn pé, “Kí ni ẹ̀ ń da obinrin yìí láàmú sí? Nítorí iṣẹ́ rere ni ó ṣe sí mi lára.
Mat 26:6-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí Jesu wà ní Betani ní ilé ọkùnrin tí à ń pè ní Simoni adẹ́tẹ̀; Bí ó ti ń jẹun, obìnrin kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú alabasita òróró ìkunra iyebíye, ó sì dà á sí i lórí. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rí i, inú bí wọn. Wọ́n wí pé, “Irú ìfowóṣòfò wo ni èyí? Èéha ti ṣe, obìnrin yìí ìbá tà á ní owó púpọ̀, kí a sì fi owó náà fún àwọn aláìní.” Jesu ti mọ èrò ọkàn wọn, ó wí pé, “Èéṣe ti ẹ̀yin fi ń dá obìnrin yìí lẹ́bi? Ó ṣe ohun tí ó dára fún mi