Mat 26:17-30

Mat 26:17-30 Bibeli Mimọ (YBCV)

Nigba ọjọ ikini ajọ aiwukara, awọn ọmọ-ẹhin Jesu tọ̀ ọ wá, nwọn si wi fun u pe, Nibo ni iwọ nfẹ ki a pèse silẹ dè ọ lati jẹ irekọja? O si wipe, Ẹ wọ̀ ilu lọ si ọdọ ọkunrin kan bayi, ẹ si wi fun u pe, Olukọni wipe, Akokò mi sunmọ etile; emi o ṣe ajọ irekọja ni ile rẹ pẹlu awọn ọmọ-ẹhin mi. Awọn ọmọ-ẹhin na si ṣe gẹgẹ bi Jesu ti fi aṣẹ fun wọn; nwọn si pèse irekọja silẹ. Nigbati alẹ si lẹ, o joko pẹlu awọn mejila. Bi nwọn si ti njẹun, o wipe, Lõtọ, ni mo wi fun nyin, ọkan ninu nyin yio fi mi hàn. Nwọn si kãnu gidigidi, olukuluku wọn bẹ̀rẹ si ibi i lẽre pe, Oluwa, emi ni bi? O si dahùn wipe, Ẹniti o bá mi tọwọ bọ inu awo, on na ni yio fi mi hàn. Ọmọ-enia nlọ bi a ti kọwe nipa tirẹ̀: ṣugbọn egbé ni fun ọkunrin na, lati ọdọ ẹniti a gbé ti fi Ọmọ-enia hàn! iba san fun ọkunrin na, bi o ṣepe a ko bí i. Nigbana ni Judasi, ti o fi i hàn, dahùn wipe, Rabbi, emi ni bi? O si wi fun u pe, Iwọ wi i. Bi nwọn si ti njẹun, Jesu mu akara, o si sure, o si bu u, o si fifun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o wipe, Gbà, jẹ; eyiyi li ara mi. O si mu ago, o dupẹ, o si fifun wọn, o wipe, Gbogbo nyin ẹ mu ninu rẹ̀; Nitori eyi li ẹ̀jẹ mi ti majẹmu titun, ti a ta silẹ fun ọ̀pọ enia fun imukuro ẹ̀ṣẹ. Ṣugbọn mo wi fun nyin, lati isisiyi lọ emi kì yio mu ninu eso ajara yi mọ́, titi yio fi di ọjọ na, nigbati emi o si bá nyin mu titun ni ijọba Baba mi. Nigbati nwọn si kọ orin kan tan, nwọn jade lọ sori òke Olifi.

Mat 26:17-30 Yoruba Bible (YCE)

Ní ọjọ́ kinni Àjọ̀dún Àìwúkàrà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wá sọ́dọ̀ Jesu, wọ́n bi í pé, “Níbo ni o fẹ́ kí á tọ́jú fún ọ láti jẹ àsè Ìrékọjá?” Ó bá dáhùn pé, “Ẹ lọ sí ọ̀dọ̀ ọkunrin kan báyìí nígboro kí ẹ sọ fún un pé, ‘Olùkọ́ni ní: Àkókò mi súnmọ́ tòsí; ní ilé rẹ ni èmi ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi yóo ti jẹ àsè Ìrékọjá.’ ” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà ṣe bí Jesu ti pàṣẹ fún wọn. Wọ́n sì tọ́jú gbogbo nǹkan fún àsè Ìrékọjá. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, ó jókòó láti jẹun pẹlu àwọn mejila. Bí wọ́n ti ń jẹun, ó wí fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ọ̀kan ninu yín yóo fi mí fún àwọn ọ̀tá.” Ọkàn wọn dàrú pupọ; ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ń bèèrè pé, “Kò sá lè jẹ́ èmi ni, Oluwa?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹni tí ó ń fi òkèlè run ọbẹ̀ ninu àwo kan náà pẹlu mi ni ẹni náà tí yóo fi mí fún àwọn ọ̀tá. Ọmọ-Eniyan ń lọ gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ nípa rẹ̀. Ṣugbọn ẹni tí ó fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ gbé! Ìbá sàn fún un bí a kò bá bí i.” Nígbà náà ni Judasi, ẹni tí ó fi í fún àwọn ọ̀tá, bi í pé, “Àbí èmi ni, Olùkọ́ni?” Jesu dá a lóhùn pé, “O ti fi ẹnu ara rẹ sọ ọ́.” Nígbà tí wọn ń jẹun, Jesu mú burẹdi, ó gbadura sí i, ó bù ú, ó bá fi fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀; ó ní, “Ẹ gbà, ẹ jẹ ẹ́, èyí ni ara mi.” Nígbà tí ó mú ife, ó dúpẹ́, ó fi fún wọn, ó ní “Gbogbo yín ẹ mu ninu rẹ̀. Èyí ni ẹ̀jẹ̀ mi tí a fi dá majẹmu, ẹ̀jẹ̀ tí a ta sílẹ̀ fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ ọpọlọpọ eniyan. Mo sọ fun yín, n kò ní mu ọtí èso àjàrà mọ́ títí di ọjọ́ náà tí n óo mu ún pẹlu yín ní ọ̀tun ní ìjọba Baba mi.” Lẹ́yìn náà, wọ́n kọ orin kan, wọ́n bá jáde lọ sórí Òkè Olifi.

Mat 26:17-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní ọjọ́ kìn-ín-ní àjọ àìwúkàrà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tọ Jesu wá pé, “Níbo ni ìwọ fẹ́ kí a pèsè sílẹ̀ láti jẹ àsè ìrékọjá?” Jesu sì dáhùn pé, “Ẹ wọ ìlú lọ, ẹ̀yin yóò rí ọkùnrin kan, ẹ wí fún un pé, ‘Olùkọ́ wa wí pé: Àkókò mi ti dé. Èmi yóò sì jẹ àsè ìrékọjá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi ní ilé rẹ.’ ” Nítorí náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà ṣe gẹ́gẹ́ bí Jesu ti sọ fún wọn. Wọ́n sì tọ́jú oúnjẹ àsè ti ìrékọjá níbẹ̀. Ní àṣálẹ́ ọjọ́ kan náà, bí Jesu ti jókòó pẹ̀lú àwọn méjìlá, nígbà tí wọ́n sì ń jẹun, ó wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ọ̀kan nínú yín yóò fi mí hàn.” Ìbànújẹ́ sì bo ọkàn wọn nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bi í pé, “Olúwa, èmi ni bí?” Jesu dáhùn pé, “Ẹni ti ó bá mi tọwọ́ bọ inú àwo, ni yóò fi mi hàn. Ọmọ Ènìyàn ń lọ bí a ti kọ̀wé nípa rẹ̀: ṣùgbọ́n ègbé ni fún ọkùnrin náà lọ́wọ́ ẹni tí a ó ti fi Ọmọ ènìyàn hàn! Ìbá kúkú sàn fún ẹni náà, bí a kò bá bí.” Judasi, ẹni tí ó fi í hàn pẹ̀lú béèrè pé, “Rabbi, èmi ni bí?” Jesu sì dá a lóhùn pé, “Ìwọ wí i.” Bí wọ́n ti ń jẹun, Jesu sì mú ìwọ̀n àkàrà kékeré kan, lẹ́yìn tí ó ti gbàdúrà sí i, ó bù ú, Ó fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Ó wí pé, “Gbà, jẹ; nítorí èyí ni ara mi.” Bákan náà, ó sì mú ago wáìnì, ó dúpẹ́ fún un, ó sì gbé e fún wọn. Ó wí pé, “Kí gbogbo yín mu nínú rẹ̀. Nítorí èyí ni ẹ̀jẹ̀ mi tí májẹ̀mú tuntun, tí a ta sílẹ̀ fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn. Sì kíyèsi àwọn ọ̀rọ̀ mi. Èmi kì yóò tún mu nínú ọtí wáìnì yìí mọ́ títí di ọjọ́ náà tí èmi yóò mu ún ní tuntun pẹ̀lú yín ní ìjọba Baba mi.” Wọ́n sì kọ orin kan, lẹ́yìn náà wọ́n lọ sórí òkè Olifi.