Mat 25:35-36
Mat 25:35-36 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori ebi pa mi, ẹnyin si fun mi li onjẹ: ongbẹ gbẹ mi, ẹnyin si fun mi li ohun mimu: mo jẹ alejò, ẹnyin si gbà mi si ile: Mo wà ni ìhoho, ẹnyin si daṣọ bò mi: mo ṣe aisan, ẹnyin si bojuto mi: mo wà ninu tubu, ẹnyin si tọ̀ mi wá.
Pín
Kà Mat 25Mat 25:35-36 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí nígbà tí ebi ń pa mí, ẹ fún mi ní oúnjẹ. Nígbà tí òùngbẹ ń gbẹ mí, ẹ fún mi ní omi mu. Nígbà tí mo jẹ́ àlejò, ẹ gbà mí sílé. Nígbà tí mo wà níhòòhò, ẹ daṣọ bò mí. Nígbà tí mo ṣàìsàn, ẹ wá wò mí. Nígbà tí mo wà lẹ́wọ̀n, ẹ wá sọ́dọ̀ mi.’
Pín
Kà Mat 25Mat 25:35-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí ebi pa mi, ẹ̀yin sì fún mi ní oúnjẹ, òǹgbẹ gbẹ mí, ẹ̀yin sì fún mi ní omi. Mo jẹ́ àlejò, ẹ̀yin sì pè mí sínú ilé yín. Mo wà ní ìhòhò, ẹ̀yin sì daṣọ bò mí. Nígbà tí mo ṣe àìsàn ẹ ṣe ìtójú mi, àti ìgbà tí mo wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n ẹ̀yin bẹ̀ mí wò.’
Pín
Kà Mat 25