Mat 25:28-30
Mat 25:28-30 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitorina ẹ gbà talenti na li ọwọ́ rẹ̀, ẹ si fifun ẹniti o ni talenti mẹwa. Nitori ẹnikẹni ti o ba ni, li a o fifun, yio si ni lọpọlọpọ: ṣugbọn li ọwọ́ ẹniti kò ni li a o tilẹ gbà eyi ti o ni. Ẹ si gbé alailere ọmọ-ọdọ na sọ sinu òkunkun lode: nibẹ li ẹkún on ipahinkeke yio gbé wà.
Mat 25:28-30 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà, ẹ gba àpò kan náà lọ́wọ́ rẹ̀, kí ẹ fún ẹni tí ó ní àpò mẹ́wàá. Nítorí ẹni tí ó bá ní, òun ni a óo túbọ̀ fún, kí ó lè ní sí i. Lọ́wọ́ ẹni tí kò ní ni a óo sì ti gba ìwọ̀nba díẹ̀ tí ó ní. Kí ẹ mú ẹrú tí kò wúlò yìí kí ẹ tì í sinu òkùnkùn biribiri. Níbẹ̀ ni ẹkún ati ìpayínkeke yóo wà.’
Mat 25:28-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“ ‘Ó sì pàṣẹ kí a gba tálẹ́ǹtì náà lọ́wọ́ rẹ̀, kí a sì fún ọkùnrin tí ó ní tálẹ́ǹtì mẹ́wàá. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ní a ó fún sí i, yóò sí tún ní sí lọ́pọ̀lọpọ̀. Ṣùgbọ́n láti ọwọ́ ẹni tí kò ní ni a ó ti gbà èyí tí ó ní. Nítorí ìdí èyí, gbé aláìlérè ọmọ ọ̀dọ̀, jù ú sínú òkùnkùn lóde, ibẹ̀ ni ẹ̀kún òun ìpayínkeke yóò gbé wà.’