Mat 25:24-26
Mat 25:24-26 Bibeli Mimọ (YBCV)
Eyi ti o gbà talenti kan si wá, o ni, Oluwa, mo mọ̀ ọ pe onroro enia ni iwọ iṣe, iwọ nkore nibiti iwọ kò gbe funrugbin si, iwọ si nṣà nibiti iwọ kò fẹ́ka si: Emi si bẹ̀ru, mo si lọ pa talenti rẹ mọ́ ninu ilẹ: wo o, nkan rẹ niyi. Oluwa rẹ̀ si dahùn o wi fun u pe, Iwọ ọmọ-ọdọ buburu ati onilọra, iwọ mọ̀ pe emi nkore nibiti emi kò funrugbin si, emi si nṣà nibiti emi kò fẹ́ka si
Mat 25:24-26 Yoruba Bible (YCE)
“Lẹ́yìn náà, ẹni tí ó gba àpò kan wá, ó ní, ‘Alàgbà mo mọ̀ pé eniyan líle ni ọ́. Ibi tí o kò fúnrúgbìn sí ni o tí ń kórè. Ibi tí o kò fi nǹkan pamọ́ sí ni ò ń fojú wá a sí. Ẹ̀rù rẹ bà mí, mo bá lọ fi àpò kan rẹ pamọ́ sinu ilẹ̀. Òun nìyí, gba nǹkan rẹ!’ “Olúwa rẹ̀ dá a lóhùn pé, ‘Ìwọ olubi ati onímẹ̀ẹ́lẹ́ ẹrú yìí. O mọ̀ pé èmi a máa kórè níbi tí n kò fúnrúgbìn sí, ati pé èmi a máa fojú wá nǹkan níbi tí n kò fi pamọ́ sí.
Mat 25:24-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Níkẹyìn, ọkùnrin tí a fún ní tálẹ́ǹtì kan wá, ó wí pé, ‘Olúwa, mo mọ̀ pé òǹrorò ènìyàn ni ìwọ ń ṣe ìwọ ń kórè níbi tí ìwọ kò gbìn sí, ìwọ ń kójọ níbi tí ìwọ kò ó ká sí. Èmi bẹ̀rù, mo sì lọ pa tálẹ́ǹtì rẹ mọ́ sínú ilẹ̀. Wò ó, nǹkan rẹ nìyìí.’ “Ṣùgbọ́n olúwa rẹ̀ dáhùn pé, ‘Ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ búburú, ìwọ mọ̀ pé èmi ń kórè níbi tí èmi kò fúnrúgbìn sì, èmi sì ń kójọ níbi tí èmi kò fọ́nká ká sí.