Mat 25:19-30

Mat 25:19-30 Bibeli Mimọ (YBCV)

Lẹhin igba ti o pẹ titi, oluwa awọn ọmọ-ọdọ wọnni de, o ba wọn ṣiro. Eyi ti o gbà talenti marun si wá, o si mu talenti marun miran wá pẹlu, o wipe, Oluwa, iwọ fi talenti marun fun mi: si wò o, mo jère talenti marun miran. Oluwa rẹ̀ wi fun u pe, O ṣeun, iwọ ọmọ-ọdọ rere ati olõtọ: iwọ ṣe olõtọ, ninu ohun diẹ, emi o mu ọ ṣe olori ohun pipọ: iwo bọ́ sinu ayọ̀ Oluwa rẹ. Eyi ti o gbà talenti meji pẹlu si wá, o wipe, Oluwa, iwọ fi talenti meji fun mi: wo o, mo jère talenti meji miran. Oluwa rẹ̀ si wi fun u pe, O ṣeun, iwọ ọmọ-ọdọ rere ati olõtọ; iwọ ṣe olõtọ ninu ohun diẹ, emi o mu ọ ṣe olori ohun pipọ: iwọ bọ́ sinu ayọ̀ oluwa rẹ. Eyi ti o gbà talenti kan si wá, o ni, Oluwa, mo mọ̀ ọ pe onroro enia ni iwọ iṣe, iwọ nkore nibiti iwọ kò gbe funrugbin si, iwọ si nṣà nibiti iwọ kò fẹ́ka si: Emi si bẹ̀ru, mo si lọ pa talenti rẹ mọ́ ninu ilẹ: wo o, nkan rẹ niyi. Oluwa rẹ̀ si dahùn o wi fun u pe, Iwọ ọmọ-ọdọ buburu ati onilọra, iwọ mọ̀ pe emi nkore nibiti emi kò funrugbin si, emi si nṣà nibiti emi kò fẹ́ka si: Nitorina iwọ iba fi owo mi si ọwọ́ awọn ti npowodà, nigbati emi ba de, emi iba si gbà nkan mi pẹlu elé. Nitorina ẹ gbà talenti na li ọwọ́ rẹ̀, ẹ si fifun ẹniti o ni talenti mẹwa. Nitori ẹnikẹni ti o ba ni, li a o fifun, yio si ni lọpọlọpọ: ṣugbọn li ọwọ́ ẹniti kò ni li a o tilẹ gbà eyi ti o ni. Ẹ si gbé alailere ọmọ-ọdọ na sọ sinu òkunkun lode: nibẹ li ẹkún on ipahinkeke yio gbé wà.

Mat 25:19-30 Yoruba Bible (YCE)

“Lẹ́yìn ọjọ́ pípẹ́, oluwa àwọn ẹrú náà dé, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí bi wọ́n bí wọ́n ti ṣe sí. Nígbà tí ẹni tí ó gba àpò marun-un dé, ó gbé àpò marun-un mìíràn wá, ó ní, ‘Alàgbà, àpò marun-un ni o fún mi. Mo ti jèrè àpò marun-un lórí rẹ̀.’ Oluwa rẹ̀ wí fún un pé, ‘O ṣeun, ìwọ olóòótọ́ ẹrú, eniyan rere ni ọ́. O ti ṣe olóòótọ́ ninu nǹkan kékeré, a óo fi ọ́ ṣe alámòójútó nǹkan pupọ. Bọ́ sinu ayọ̀ oluwa rẹ.’ “Bẹ́ẹ̀ náà ni ẹni tí ó gba àpò meji wá, ó ní ‘Alàgbà, àpò meji ni o fún mi. Mo ti jèrè àpò meji lórí rẹ̀!’ Oluwa rẹ̀ sọ fún un pé, ‘O ṣeun, ìwọ olóòótọ́ ẹrú, eniyan rere ni ọ́. O ti ṣe olóòótọ́ ninu nǹkan kékeré, n óo fi ọ́ ṣe alámòójútó nǹkan pupọ. Bọ́ sinu ayọ̀ oluwa rẹ.’ “Lẹ́yìn náà, ẹni tí ó gba àpò kan wá, ó ní, ‘Alàgbà mo mọ̀ pé eniyan líle ni ọ́. Ibi tí o kò fúnrúgbìn sí ni o tí ń kórè. Ibi tí o kò fi nǹkan pamọ́ sí ni ò ń fojú wá a sí. Ẹ̀rù rẹ bà mí, mo bá lọ fi àpò kan rẹ pamọ́ sinu ilẹ̀. Òun nìyí, gba nǹkan rẹ!’ “Olúwa rẹ̀ dá a lóhùn pé, ‘Ìwọ olubi ati onímẹ̀ẹ́lẹ́ ẹrú yìí. O mọ̀ pé èmi a máa kórè níbi tí n kò fúnrúgbìn sí, ati pé èmi a máa fojú wá nǹkan níbi tí n kò fi pamọ́ sí. Nígbà tí o mọ̀ bẹ́ẹ̀, kí ni kò jẹ́ kí o fi owó mi fún àwọn agbowó-pamọ́ pé nígbà tí mo bá dé, kí n lè gba owó mi pada pẹlu èlé? Nítorí náà, ẹ gba àpò kan náà lọ́wọ́ rẹ̀, kí ẹ fún ẹni tí ó ní àpò mẹ́wàá. Nítorí ẹni tí ó bá ní, òun ni a óo túbọ̀ fún, kí ó lè ní sí i. Lọ́wọ́ ẹni tí kò ní ni a óo sì ti gba ìwọ̀nba díẹ̀ tí ó ní. Kí ẹ mú ẹrú tí kò wúlò yìí kí ẹ tì í sinu òkùnkùn biribiri. Níbẹ̀ ni ẹkún ati ìpayínkeke yóo wà.’

Mat 25:19-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Lẹ́yìn ọjọ́ pípẹ́, olúwa àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ dé láti àjò rẹ̀. Ó pè wọ́n jọ láti bá wọn ṣírò owó rẹ̀. Ọkùnrin tí ó gba tálẹ́ǹtì márùn-ún, mú márùn-ún mìíràn padà wá, ó wí pé, ‘olúwa, ìwọ ti fi tálẹ́ǹtì márùn-ún fún mi, mo sì ti jèrè márùn-ún mìíràn pẹ̀lú rẹ̀.’ “Olúwa rẹ̀ wí fún un pé, ‘O ṣeun ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ rere àti olóòtítọ́: ìwọ ṣe olóòtítọ́ nínú ohun díẹ̀, èmi yóò fi ọ́ ṣe olórí ohun púpọ̀, bọ́ sínú ayọ̀ olúwa rẹ.’ “Èyí tí ó gba tálẹ́ǹtì méjì wí pé ‘Olúwa, ìwọ fún mi ní tálẹ́ǹtì méjì láti lò, èmi sì ti jèrè tálẹ́ǹtì méjì mìíràn.’ “Olúwa rẹ̀ sì wí fún un pé ‘O ṣeun, ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ rere àti olóòtítọ́. Ìwọ ti jẹ́ olóòtítọ́ nínú ohun díẹ̀, èmi yóò fi ọ ṣe olórí ohun púpọ̀. Ìwọ bọ́ sínú ayọ̀ olúwa rẹ.’ “Níkẹyìn, ọkùnrin tí a fún ní tálẹ́ǹtì kan wá, ó wí pé, ‘Olúwa, mo mọ̀ pé òǹrorò ènìyàn ni ìwọ ń ṣe ìwọ ń kórè níbi tí ìwọ kò gbìn sí, ìwọ ń kójọ níbi tí ìwọ kò ó ká sí. Èmi bẹ̀rù, mo sì lọ pa tálẹ́ǹtì rẹ mọ́ sínú ilẹ̀. Wò ó, nǹkan rẹ nìyìí.’ “Ṣùgbọ́n olúwa rẹ̀ dáhùn pé, ‘Ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ búburú, ìwọ mọ̀ pé èmi ń kórè níbi tí èmi kò fúnrúgbìn sì, èmi sì ń kójọ níbi tí èmi kò fọ́nká ká sí. Nígbà náà ìwọ ìbá kúkú fi owó mi sí ilé ìfowópamọ́ tí èmi bá dé èmi ìbá le gba owó mi pẹ̀lú èrè. “ ‘Ó sì pàṣẹ kí a gba tálẹ́ǹtì náà lọ́wọ́ rẹ̀, kí a sì fún ọkùnrin tí ó ní tálẹ́ǹtì mẹ́wàá. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ní a ó fún sí i, yóò sí tún ní sí lọ́pọ̀lọpọ̀. Ṣùgbọ́n láti ọwọ́ ẹni tí kò ní ni a ó ti gbà èyí tí ó ní. Nítorí ìdí èyí, gbé aláìlérè ọmọ ọ̀dọ̀, jù ú sínú òkùnkùn lóde, ibẹ̀ ni ẹ̀kún òun ìpayínkeke yóò gbé wà.’