Mat 25:14-18
Mat 25:14-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori ijọba ọrun dabi ọkunrin kan ti o nlọ si àjo, ẹniti o pè awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, o si kó ẹrù rẹ̀ fun wọn. O si fi talenti marun fun ọkan, o fi meji fun ẹnikeji, ati ọkan fun ẹnikẹta; o fifun olukuluku gẹgẹ bi agbara rẹ̀ ti ri; lẹsẹkanna o mu ọ̀na àjo rẹ̀ pọ̀n. Nigbana li eyi ti o gbà talenti marun lọ, ọ fi tirẹ̀ ṣòwo, o si jère talenti marun miran. Gẹgẹ bẹ̃li eyi ti o gbà meji, on pẹlu si jère meji miran. Ṣugbọn eyi ti o gbà talenti kan lọ, o wà ilẹ, o si rì owo oluwa rẹ̀.
Mat 25:14-18 Yoruba Bible (YCE)
“Nígbà náà ìjọba ọ̀run yóo tún rí báyìí. Ọkunrin kan ń lọ sí ìdálẹ̀. Ó bá pe àwọn ẹrú rẹ̀, ó fi àwọn dúkìá rẹ̀ lé wọn lọ́wọ́. Ó fún ọ̀kan ni àpò owó marun-un, ó fún ekeji ní àpò meji, ó fún ẹkẹta ní àpò kan. Ó fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn bí agbára rẹ̀ ti tó; ó bá lọ sí ìdálẹ̀. Kíá, bí ó ti lọ tán, ẹni tí ó gba àpò marun-un lọ ṣòwò, ó bá jèrè àpò marun-un. Bákan náà ni ẹni tí ó gba àpò meji. Òun náà jèrè àpò meji. Ṣugbọn ẹni tí ó gba àpò kan lọ wa ilẹ̀, ó bá bo owó oluwa rẹ̀ mọ́lẹ̀.
Mat 25:14-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“A sì tún fi ìjọba ọ̀run wé ọkùnrin kan tí ó ń lọ sí ìrìnàjò. Ó pe àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì kó ohun ìní rẹ̀ fún wọn. Ó fún ọ̀kan ni tálẹ́ǹtì márùn-ún, ó fún èkejì ni tálẹ́ǹtì méjì, ó sì fún ẹ̀kẹta ni tálẹ́ǹtì kan, ó fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ ti mọ, ó sì lọ ìrìnàjò tirẹ̀. Ọkùnrin tí ó gba tálẹ́ǹtì márùn-ún bẹ̀rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láti fi owó náà ṣòwò. Láìpẹ́, ó sì jèrè márùn-ún mìíràn. Ọkùnrin tí ó gba tálẹ́ǹtì méjì náà fi tirẹ̀ ṣòwò. Láìpẹ́, ó sì jèrè tálẹ́ǹtì méjì mìíràn. Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí ò gba tálẹ́ǹtì kan, ó wa ihò ní ilẹ̀, ó sì bo owó ọ̀gá mọ́ ibẹ̀.