Mat 25:14-15
Mat 25:14-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori ijọba ọrun dabi ọkunrin kan ti o nlọ si àjo, ẹniti o pè awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, o si kó ẹrù rẹ̀ fun wọn. O si fi talenti marun fun ọkan, o fi meji fun ẹnikeji, ati ọkan fun ẹnikẹta; o fifun olukuluku gẹgẹ bi agbara rẹ̀ ti ri; lẹsẹkanna o mu ọ̀na àjo rẹ̀ pọ̀n.
Mat 25:14-15 Yoruba Bible (YCE)
“Nígbà náà ìjọba ọ̀run yóo tún rí báyìí. Ọkunrin kan ń lọ sí ìdálẹ̀. Ó bá pe àwọn ẹrú rẹ̀, ó fi àwọn dúkìá rẹ̀ lé wọn lọ́wọ́. Ó fún ọ̀kan ni àpò owó marun-un, ó fún ekeji ní àpò meji, ó fún ẹkẹta ní àpò kan. Ó fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn bí agbára rẹ̀ ti tó; ó bá lọ sí ìdálẹ̀.
Mat 25:14-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“A sì tún fi ìjọba ọ̀run wé ọkùnrin kan tí ó ń lọ sí ìrìnàjò. Ó pe àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì kó ohun ìní rẹ̀ fún wọn. Ó fún ọ̀kan ni tálẹ́ǹtì márùn-ún, ó fún èkejì ni tálẹ́ǹtì méjì, ó sì fún ẹ̀kẹta ni tálẹ́ǹtì kan, ó fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ ti mọ, ó sì lọ ìrìnàjò tirẹ̀.