Mat 24:15-21
Mat 24:15-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitorina nigbati ẹnyin ba ri irira isọdahoro, ti a ti ẹnu wolĩ Danieli sọ, ti o ba duro ni ibi mimọ́, (ẹniti o ba kà a, ki òye ki o yé e:) Nigbana ni ki awọn ti mbẹ ni Judea ki o sálọ si ori òke: Ki ẹniti mbẹ lori ile ki o maṣe sọkalẹ wá imu ohunkohun jade ninu ile rẹ̀: Ki ẹniti mbẹ li oko maṣe pada sẹhin wá lati mu aṣọ rẹ̀. Ṣugbọn egbé ni fun awọn ti o lóyun, ati fun awọn ti o nfi ọmú fun ọmọ mu ni ijọ wọnni! Ẹ si mã gbadura ki sisá nyin ki o máṣe jẹ igba otutù, tabi ọjọ isimi: Nitori nigbana ni ipọnju nla yio wà, irú eyi ti kò si lati igba ibẹrẹ ọjọ ìwa di isisiyi, bẹ̃kọ, irú rẹ̀ kì yio si si.
Mat 24:15-21 Yoruba Bible (YCE)
“Nígbà náà ni ẹ óo rí ohun ẹ̀gbin tí wolii Daniẹli ti sọ tẹ́lẹ̀, tí ó dúró ní ibi mímọ́ (ìwọ olùkàwé yìí, jẹ́ kí ohun tí ò ń kà yé ọ). Tí èyí bá ti ṣẹlẹ̀, kí àwọn tí ó wà ní Judia sálọ sí orí òkè. Ẹni tí ó wà lókè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì kò gbọdọ̀ sọ̀kalẹ̀ wọlé lọ mú àwọn ohun ìní rẹ̀. Ẹni tí ó bá wà lóko kò gbọdọ̀ pada sẹ́yìn láti lọ mú ẹ̀wù rẹ̀ tí ó bọ́ sílẹ̀. Ó ṣe! Fún àwọn aboyún ati fún àwọn tí wọn bá ń tọ́ ọmọ lọ́wọ́ ní ọjọ́ náà. Ẹ gbadura pé kí sísá yín má bọ́ sí ìgbà òtútù nini, tabi sí Ọjọ́ Ìsinmi. Nítorí ìpọ́njú yóo pọ̀ ní àkókò náà, irú èyí tí kò sí rí láti ìbẹ̀rẹ̀ ayé títí di ìsinsìnyìí; irú rẹ̀ kò sì tún ní sí mọ́.
Mat 24:15-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Nítorí náà, nígbà tí ẹ̀yin bá rí ìríra ìsọdahoro, tí a ti ẹnu wòlíì Daniẹli sọ, tí ó bá dúró ní ibi mímọ́, (ẹni tí ó bá kà á, kí òye kí ó yé e). Nítorí náà, jẹ́ kí àwọn tí ó wà ní Judea sálọ sí àwọn orí òkè. Kí ẹni tí ó wà lórí ilé rẹ̀ má ṣe sọ̀kalẹ̀ wá mú ohunkóhun jáde nínú ilé rẹ̀. Kí àwọn tí ó sì wà lóko má ṣe darí wá sí ilé láti mú àwọn aṣọ wọn. Ṣùgbọ́n àánú ṣe mí fún àwọn obìnrin ti ó lóyún, àti fún àwọn tí ó ń fún ọmọ loyan ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì! Ẹ sì máa gbàdúrà kí sísá yín má ṣe jẹ́ ìgbà òtútù, tàbí ọjọ́ ìsinmi. Nítorí ìpọ́njú ńlá yóò wà, irú èyí tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ láti ìgbà ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ ayé wá títí di ìsinsin yìí irú rẹ̀ kì yóò sì ṣí.