Mat 23:1-36

Mat 23:1-36 Bibeli Mimọ (YBCV)

NIGBANA ni Jesu wi fun ijọ enia, ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, Pe, Awọn akọwe pẹlu awọn Farisi joko ni ipò Mose: Nitorina ohunkohun gbogbo ti nwọn ba wipe ki ẹ kiyesi, ẹ mã kiyesi wọn ki ẹ si mã ṣe wọn; ṣugbọn ẹ má ṣe gẹgẹ bi iṣe wọn: nitoriti nwọn a ma wi, ṣugbọn nwọn ki iṣe. Nitori nwọn a di ẹrù wuwo ti o si ṣoro lati rù, nwọn a si gbé e kà awọn enia li ejika; ṣugbọn awọn tikarawọn ko jẹ fi ika wọn kàn ẹrù na. Ṣugbọn gbogbo iṣẹ wọn ni nwọn nṣe nitori ki awọn enia ki o ba le ri wọn: nwọn sọ filakteri wọn di gbigbòro, nwọn fi kún iṣẹti aṣọ wọn. Nwọn fẹ ipò ọlá ni ibi ase, ati ibujoko ọla ni sinagogu, Ati ikíni li ọjà, ati ki awọn enia mã pè wọn pe, Rabbi, Rabbi. Ṣugbọn ki a máṣe pè ẹnyin ni Rabbi: nitoripe ẹnikan ni Olukọ nyin, ani Kristi; ará si ni gbogbo nyin. Ẹ má si ṣe pè ẹnikan ni baba nyin li aiye: nitori ẹnikan ni Baba nyin, ẹniti mbẹ li ọrun. Ki a má si ṣe pè nyin ni olukọni: nitori ọkan li Olukọni nyin, ani Kristi. Ṣugbọn ẹniti o ba pọ̀ju ninu nyin, on ni yio jẹ iranṣẹ nyin. Ẹnikẹni ti o ba si gbé ara rẹ̀ ga, li a o rẹ̀ silẹ; ẹnikẹni ti o ba si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ li a o gbé ga. Ṣugbọn egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi, agabagebe; nitoriti ẹnyin sé ijọba ọrun mọ́ awọn enia: nitori ẹnyin tikaranyin kò wọle, bẹ̃li ẹnyin kò jẹ ki awọn ti nwọle ki o wọle. Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi, agabagebe; nitoriti ẹnyin jẹ ile awọn opó run, ati nitori aṣehan, ẹ ngbadura gigun: nitorina li ẹnyin o ṣe jẹbi pọ̀ju. Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi, agabagebe; nitoriti ẹnyin nyi okun ati ilẹ ká lati sọ enia kan di alawọṣe; nigbati o ba si di bẹ̃ tan, ẹnyin a sọ ọ di ọmọ ọrun apadi nigba meji ju ara nyin lọ. Egbé ni fun nyin, ẹnyin amọ̀na afọju, ti o nwipe, Ẹnikẹni ti o ba fi tẹmpili bura, kò si nkan; ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba fi wura tẹmpili bura, o di ajigbese. Ẹnyin alaimoye ati afọju: ewo li o pọ̀ju, wura, tabi tẹmpili ti nsọ wura di mimọ́? Ati pe, Ẹnikẹni ti o ba fi pẹpẹ bura, kò si nkan; ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba fi ẹ̀bun ti o wà lori rẹ̀ bura, o di ajigbese. Ẹnyin alaimoye ati afọju: ewo li o pọ̀ju, ẹ̀bun, tabi pẹpẹ ti nsọ ẹ̀bun di mimọ́? Njẹ ẹniti o ba si fi pẹpẹ bura, o fi i bura, ati ohun gbogbo ti o wà lori rẹ̀. Ẹniti o ba si fi tẹmpili bura, o fi i bura, ati ẹniti o ngbé inu rẹ̀. Ẹniti o ba si fi ọrun bura, o fi itẹ́ Ọlọrun bura, ati ẹniti o joko lori rẹ̀. Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi agabagebe; nitoriti ẹnyin ngbà idamẹwa minti, ati anise, ati kumini, ẹnyin si ti fi ọ̀ran ti o tobiju ninu ofin silẹ laiṣe, idajọ, ãnu, ati igbagbọ́: wọnyi li o tọ́ ti ẹnyin iba ṣe, laisi fi iyoku silẹ laiṣe. Ẹnyin afọju amọ̀na, ti nsẹ́ kantikanti ti o si ngbé ibakasiẹ mì. Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi, agabagebe; nitoriti ẹnyin nfọ̀ ode ago ati awopọkọ́ mọ́, ṣugbọn inu wọn kún fun irẹjẹ ati wọ̀bia. Iwọ afọju Farisi, tetekọ fọ̀ eyi ti mbẹ ninu ago ati awopọkọ́ mọ́ na, ki ode wọn ki o le mọ́ pẹlu. Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi, agabagebe; nitoriti ẹnyin dabi ibojì funfun, ti o dara li ode, ṣugbọn ninu nwọn kún fun egungun okú, ati fun ẹgbin gbogbo. Gẹgẹ bẹ̃li ẹnyin pẹlu farahàn li ode bi olododo fun enia, ṣugbọn ninu ẹ kún fun agabagebe ati ẹ̀ṣẹ. Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi, agabagebe; nitoriti ẹnyin kọ́ ibojì awọn wolĩ, ẹnyin si ṣe isà okú awọn olododo li ọṣọ, Ẹnyin si wipe, Awa iba wà li ọjọ awọn baba wa, awa kì ba li ọwọ́ ninu ẹ̀jẹ awọn wolĩ. Njẹ ẹnyin li ẹlẹri fun ara nyin pe, ẹnyin li awọn ọmọ awọn ẹniti o pa awọn wolĩ. Njẹ ẹnyin kuku kún òṣuwọn baba nyin de oke. Ẹnyin ejò, ẹnyin ọmọ paramọlẹ, ẹnyin o ti ṣe yọ ninu ẹbi ọrun apadi? Nitorina ẹ kiyesi i, Emi rán awọn wolĩ, ati amoye, ati akọwe si nyin: omiran ninu wọn li ẹnyin ó pa, ti ẹnyin ó si kàn mọ agbelebu; ati omiran ninu wọn li ẹnyin o nà ni sinagogu nyin, ti ẹnyin o si ṣe inunibini si lati ilu de ilu: Ki gbogbo ẹ̀jẹ awọn olõtọ, ti a ti ta silẹ li aiye, ba le wá sori nyin, lati ẹ̀jẹ Abeli olododo titi de ẹ̀jẹ Sakariah ọmọ Barakiah, ẹniti ẹnyin pa larin tẹmpili ati pẹpẹ. Lõtọ ni mo wi fun nyin, Gbogbo nkan wọnyi ni yio wá sori iran yi.

Mat 23:1-36 Yoruba Bible (YCE)

Jesu bá sọ fún àwọn eniyan ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Àwọn amòfin ati àwọn Farisi ni olùtúmọ̀ òfin Mose. Nítorí náà, ohun gbogbo tí wọ́n bá sọ fun yín ni kí ẹ ṣe. Ṣugbọn ẹ má ṣe tẹ̀lé ìwà wọn, nítorí ọ̀tọ̀ ni ohun tí wọn óo sọ, ọ̀tọ̀ ni ohun tí wọn óo ṣe. Wọn á di ẹrù wúwo, wọn á gbé e ka àwọn eniyan lórí, bẹ́ẹ̀ ni àwọn fúnra wọn kò sì jẹ́ fi ọwọ́ wọn kan ẹrù náà. Gbogbo ohun tí wọn ń ṣe, wọ́n ń ṣe é kí eniyan lè rí wọn ni. Wọn á di tírà pàlàbà-pàlàbà mọ́ iwájú. Wọn á ṣe waja-waja ńláńlá sí etí aṣọ wọn. Wọ́n fẹ́ràn ìjókòó ọlá níbi àsè. Wọ́n fẹ́ràn àga iwájú ní ilé ìpàdé. Wọ́n fẹ́ràn kí eniyan máa kí wọn láàrin ọjà ati kí àwọn eniyan máa pè wọ́n ní ‘Olùkọ́ni.’ Ṣugbọn ẹ̀yin ní tiyín, ẹ má jẹ́ kí wọ́n pè yín ní ‘Olùkọ́ni,’ nítorí ẹnìkan ṣoṣo ni olùkọ́ni yín; arakunrin ni gbogbo yín jẹ́. Ẹ má pe ẹnìkan ní ‘Baba’ ní ayé, nítorí ẹnìkan ṣoṣo ni Baba yín, ẹni tí ó wà ní ọ̀run. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni pè yín ní ‘Ọ̀gá,’ nítorí ọ̀gá kanṣoṣo ni ẹ ní, òun ni Mesaya. Ẹni tí ó bá lọ́lá jùlọ láàrin yín ni kí ó ṣe iranṣẹ yín. Ẹni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a óo rẹ̀ sílẹ̀; ẹni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ni a óo gbé ga. “Ẹ gbé! Ẹ̀yin amòfin ati ẹ̀yin Farisi, ẹ̀yin alárèékérekè wọnyi. Nítorí ẹ ti ìlẹ̀kùn ìjọba ọ̀run mọ́ àwọn eniyan, ẹ̀yin fúnra yín kò wọlé, bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí wọ́n fẹ́ wọlé, ẹ kò jẹ́ kí wọ́n wọlé. [ “Ẹ gbé! Ẹ̀yin amòfin ati Farisi, alaiṣootọ; nítorí ẹ̀ ń jẹ ilé àwọn opó run; ẹ̀ ń fi adura gígùn ṣe ìbòjú. Nítorí èyí, ẹ óo gba ìdálẹ́bi pupọ.”] “Ẹ gbé! Ẹ̀yin amòfin ati ẹ̀yin Farisi, ẹ̀yin aláṣehàn, nítorí ẹ̀ ń la òkun ati oríṣìíríṣìí ìlú kọjá láti mú ẹyọ ẹnìkan láti orílẹ̀-èdè mìíràn wọ ẹ̀sìn yín. Nígbà tí ó bá ti wọ ẹ̀sìn tán, ẹ wá sọ ọ́ di ẹni ọ̀run àpáàdì ní ìlọ́po meji ju ẹ̀yin alára lọ. “Ẹ gbé! Ẹ̀yin afọ́jú tí ń fọ̀nà han eniyan. Ẹ̀ ń sọ pé, ‘Bí eniyan bá fi Tẹmpili búra, kò ṣe nǹkankan. Ṣugbọn bí eniyan bá fi wúrà tí ó wà ninu Tẹmpili búra, olúwarẹ̀ níláti mú ìbúra rẹ̀ ṣẹ.’ Ẹ̀yin afọ́jú òmùgọ̀ wọnyi! Èwo ni ó ṣe pataki jù! Wúrà ni tabi Tẹmpili tí a fi sọ wúrà di ohun ìyàsọ́tọ̀? Ẹ tún sọ pé, ‘Bí eniyan bá fi pẹpẹ ìrúbọ búra, kò ṣe nǹkankan. Ṣugbọn bí eniyan bá fi ọrẹ tí ó wà lórí pẹpẹ ìrúbọ búra, olúwarẹ̀ níláti mú ìbúra rẹ̀ ṣẹ.’ Ẹ̀yin afọ́jú wọnyi! Èwo ni ó ṣe pataki jù, ọrẹ ni, tabi pẹpẹ ìrúbọ tí ó sọ ọ́ di ohun ìyàsọ́tọ̀? Nítorí náà ẹni tí ó bá fi pẹpẹ ìrúbọ búra, ati pẹpẹ ati ohun gbogbo tí ó wà lórí rẹ̀ ni ó fi búra. Ẹni tí ó bá fi Tẹmpili búra, ohun tí ó wà ninu rẹ̀ ati Ọlọrun tí ó ń gbé inú rẹ̀ ni ó fi búra pẹlu. Ẹni tí ó bá fi ọ̀run búra, ó fi ìtẹ́ Ọlọrun ati Ọlọrun tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà búra pẹlu. “Ẹ gbé! Ẹ̀yin amòfin ati ẹ̀yin Farisi, ẹ̀yin aláṣehàn wọnyi! Ẹ̀ ń san ìdámẹ́wàá àwọn èròjà ọbẹ̀ tí wọ́n jẹ́ eléwé, nígbà tí ẹ gbàgbé àwọn ohun tí ó ṣe pataki ninu òfin: bíi ìdájọ́ òdodo, àánú, ati igbagbọ. Àwọn ohun tí ẹ̀ bá mójútó nìyí, láì gbàgbé ìdámẹ́wàá. Ẹ̀yin afọ́jú tí ń fọ̀nà han eniyan! Ẹ̀ ń yọ kòkòrò tín-tìn-tín kúrò ninu ohun tí ẹ̀ ń mu, ṣugbọn ẹ̀ ń gbé ràkúnmí mì mọ́ omi yín! “Ẹ gbé! Ẹ̀yin amòfin ati ẹ̀yin Farisi, ẹ̀yin aláṣehàn. Ẹ̀ ń fọ òde ife ati òde àwo oúnjẹ nígbà tí inú wọn kún fún àwọn ohun tí ẹ fi ìwà olè ati ìwà ìmọ-tara-ẹni-nìkan já gbà. Ìwọ afọ́jú Farisi! Kọ́kọ́ fọ inú ife ná, òde rẹ̀ náà yóo sì mọ́. “Ẹ gbé! Ẹ̀yin amòfin ati ẹ̀yin Farisi, ẹ̀yin aláṣehàn wọnyi. Ẹ dàbí àwọn ibojì tí a kùn ní funfun, tí ó dùn-ún wò lóde, ṣugbọn inú wọn kún fún egungun òkú ati oríṣìíríṣìí ohun ẹ̀gbin. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni ẹ̀yin náà rí lóde, lójú àwọn eniyan ẹ dàbí ẹni rere, ṣugbọn ẹ kún fún àṣehàn ati ìwà burúkú. “Ẹ gbé! Ẹ̀yin amòfin ati ẹ̀yin Farisi, ẹ̀yin aláṣehàn wọnyi. Ẹ̀ ń ṣe ibojì fún àwọn wolii, ẹ sì ń ṣe ibojì àwọn eniyan rere lọ́ṣọ̀ọ́. Ẹ wá ń sọ pé, ‘Bí ó bá jẹ́ pé a wà ní ìgbà àwọn baba wa, àwa kò bá tí lọ́wọ́ ninu ikú àwọn wolii.’ Nípa gbolohun yìí, ẹ̀ ń jẹ́rìí sí ara yín pé ọmọ àwọn tí ó pa àwọn wolii ni yín. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin náà ẹ múra, kí ẹ parí ohun tí àwọn baba yín ṣe kù! Ẹ̀yin ejò, ìran paramọ́lẹ̀! Báwo ni ẹ kò ti ṣe ní gba ìdájọ́ ọ̀run àpáàdì? Nítorí èyí ni mo fi rán àwọn wolii, àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ati àwọn amòfin si yín. Ẹ óo pa òmíràn ninu wọn, ẹ óo sì kan òmíràn mọ́ agbelebu. Ẹ óo na àwọn mìíràn ninu wọn ní ilé ìpàdé yín, ẹ óo sì máa lépa wọn láti ìlú dé ìlú. Ẹ óo ṣe gbogbo nǹkan wọnyi kí ẹ lè fi orí gba ẹ̀bi ikú gbogbo eniyan rere tí ẹ ti ta ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀; ohun tí ó ṣẹ̀ láti orí Abeli, ẹni rere títí fi dé orí Sakaraya, ọmọ Berekaya, tí ẹ pa láàrin àgọ́ mímọ́ ati pẹpẹ ìrúbọ. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ìran yìí ni yóo fi orí fá gbogbo ẹ̀bi yìí.

Mat 23:1-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà náà ni Jesu wí fún ọ̀pọ̀ ènìyàn àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Àwọn olùkọ́ òfin àti àwọn Farisi jókòó ní ipò Mose, Nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ gbọ́ tiwọn, kí ẹ sì ṣe ohun gbogbo tí wọ́n bá sọ fún yín. Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe ohun tí wọ́n ṣe, nítorí àwọn pàápàá kì í ṣe ohun tí wọn kọ́ yín láti ṣe. Wọ́n á di ẹrù wúwo tí ó sì ṣòro láti rù, wọ́n a sì gbé e le àwọn ènìyàn léjìká, ṣùgbọ́n àwọn tìkára wọn kò jẹ́ fi ìka wọn kan an. “Ohun gbogbo tí wọ́n ń ṣe, wọ́n ń ṣe é kí àwọn ènìyàn ba à lè rí wọn ni: Wọ́n ń sọ filakteri wọn di gbígbòòrò. Wọ́n tilẹ̀ ń bùkún ìṣẹ́tí aṣọ oyè wọn nígbà gbogbo kí ó ba à lè máa tóbi sí i. Wọ́n fẹ́ ipò ọlá ní ibi àsè, àti níbi ìjókòó ìyàsọ́tọ̀ ni Sinagọgu. Wọ́n fẹ́ kí ènìyàn máa kí wọn ní ọjà, kí àwọn ènìyàn máa pè wọ́n ní ‘Rabbi.’ “Ṣùgbọ́n kí a má ṣe pè yín ni Rabbi, nítorí pé ẹnìkan ni Olùkọ́ yín, àní Kristi, ará sì ni gbogbo yín. Ẹ má ṣe pe ẹnikẹ́ni ní baba yín ni ayé yìí, nítorí baba kan náà ni ẹ ní tí ó ń bẹ ní ọ̀run. Kí a má sì ṣe pè yín ní Olùkọ́ nítorí Olùkọ́ kan ṣoṣo ni ẹ̀yin ní, òun náà ni Kristi. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá pọ̀jù nínú yín, ni yóò jẹ́ ìránṣẹ́ yín. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a ó sì rẹ̀ sílẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì rẹ ara wọn sílẹ̀ ni a ó gbéga. “Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin olùkọ́ òfin àti Farisi, ẹ̀yin àgàbàgebè! Ẹ̀yin sé ìjọba ọ̀run mọ́ àwọn ènìyàn nítorí ẹ̀yin tìkára yín kò wọlé, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò jẹ́ kí àwọn tí ó fẹ́ wọlé ó wọlé. “Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin olùkọ́ òfin àti Farisi, ẹ̀yin àgàbàgebè! Nítorí ẹ̀yin jẹ ilé àwọn opó run, àti nítorí àṣehàn, ẹ̀ ń gbàdúrà gígùn, nítorí náà ni ẹ̀yin yóò ṣe jẹ̀bi púpọ̀. “Ègbé ni fún yín ẹ̀yin olùkọ́ òfin àti Farisi, ẹ̀yin àgàbàgebè! Nítorí ẹ̀yin rin yí ilẹ̀ àti Òkun ká láti yí ẹnìkan lọ́kàn padà, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ń sọ ọ́ di ọmọ ọ̀run àpáàdì ní ìlọ́po méjì ju ẹ̀yin pàápàá. “Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin afọ́jú ti ń fi ọ̀nà han afọ́jú! Tí ó wí pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó ba fi tẹmpili búra kò sí nǹkan kan, ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá fi wúrà inú tẹmpili búra, ó di ajigbèsè.’ Ẹ̀yin aláìmòye afọ́jú: èwo ni ó ga jù, wúrà tàbí tẹmpili tí ó ń sọ wúrà di mímọ́? Àti pé, Ẹnikẹ́ni tó bá fi pẹpẹ búra, kò jámọ́ nǹkan, ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni tí ó ba fi ẹ̀bùn tí ó wà lórí rẹ̀ búra, ó di ajigbèsè. Ẹ̀yin aláìmòye afọ́jú wọ̀nyí! Èwo ni ó pọ̀jù: ẹ̀bùn tí ó wà lórí pẹpẹ ni tàbí pẹpẹ fúnrarẹ̀ tí ó sọ ẹ̀bùn náà di mímọ́? Nítorí náà ẹnikẹ́ni tí ó bá ń fi pẹpẹ búra, ó fi í búra àti gbogbo ohun tí ó wà lórí rẹ̀. Àti pé, ẹni tí ó bá fi tẹmpili búra, ó fi í búra àti ẹni tí ń gbé inú rẹ̀. Àti pé, ẹni tí ó bá sì fi ọ̀run búra, ó fi ìtẹ́ Ọlọ́run àti ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ búra. “Ègbé ni fún yín ẹ̀yin olùkọ́ òfin àti Farisi, ẹ̀yin àgàbàgebè! Nítorí ẹ̀yin ń gba ìdámẹ́wàá minti, dili àti kumini, ẹ̀yin sì ti fi ohun tí ó ṣe pàtàkì jùlọ nínú òfin sílẹ̀ láìṣe, ìdájọ́, àánú àti ìgbàgbọ́: Wọ̀nyí ni ó tọ́ tí ẹ̀yin ìbá ṣe, ẹ̀yin kò bá fi wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀ láìṣe. Ẹ̀yin afọ́jú tó ń fi afọ́jú mọ̀nà! Ẹ tu kòkòrò-kantíkantí tó bọ́ sì yín lẹ́nu nù, ẹ gbé ìbákasẹ mì. “Ègbé ni fún yín ẹ̀yin Farisi àti ẹ̀yin olùkọ́ òfin, ẹ̀yin àgàbàgebè. Ẹ̀yin ń fọ òde ago àti àwo ṣùgbọ́n inú rẹ̀ kún fún ìrẹ́jẹ àti ẹ̀gbin gbogbo. Ìwọ afọ́jú Farisi, tètè kọ́ fọ inú ago àti àwo, gbogbo ago náà yóò sì di mímọ́. “Ègbé ni fún yín ẹ̀yin Farisi àti ẹ̀yin olùkọ́ òfin, ẹ̀yin àgàbàgebè. Ẹ dàbí ibojì funfun tí ó dára ní wíwò, ṣùgbọ́n tí ó kún fún egungun ènìyàn àti fún ẹ̀gbin àti ìbàjẹ́. Ẹ̀yin gbìyànjú láti farahàn bí ènìyàn mímọ́, olódodo, lábẹ́ aṣọ mímọ́ yín ni ọkàn tí ó kún fún ìbàjẹ́ pẹ̀lú oríṣìíríṣìí àgàbàgebè àti ẹ̀ṣẹ̀ wà. “Ègbé ni fún yín ẹ̀yin olùkọ́ òfin àti Farisi, ẹ̀yin àgàbàgebè, nítorí ẹ̀yin kọ́ ibojì àwọn wòlíì tí í ṣe ibojì àwọn olódodo ní ọ̀ṣọ́. Ẹ̀yin sì wí pé, Àwa ìbá wà ní àsìkò àwọn baba wa, àwa kì bá ní ọwọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì. Ǹjẹ́ ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí fún ara yín pé, ẹ̀yin ni ọmọ àwọn tí ó pa àwọn wòlíì. Àti pé, ẹ̀yin ń tẹ̀lé ìṣísẹ̀ àwọn baba yín. Ẹ̀yin ń kún òṣùwọ̀n ìwà búburú wọn dé òkè. “Ẹ̀yin ejò! Ẹ̀yin paramọ́lẹ̀! Ẹ̀yin yóò ti ṣe yọ nínú ẹ̀bi ọ̀run àpáàdì? Nítorí náà èmi yóò rán àwọn wòlíì àti àwọn ọlọ́gbọ́n ọkùnrin tí ó kún fún ẹ̀mí mímọ́, àti àwọn akọ̀wé sí yín. Ẹ̀yin yóò pa àwọn kan nínú wọn nípa kíkàn wọ́n mọ́ àgbélébùú. Ẹ̀yin yóò fi pàṣán na àwọn ẹlòmíràn nínú Sinagọgu yín, tí ẹ̀yin yóò sì ṣe inúnibíni sí wọn láti ìlú dé ìlú. Kí ẹ̀yin lè jẹ̀bi gbogbo ẹ̀jẹ̀ àwọn olódodo tí ẹ ta sílẹ̀ ní ayé, láti ẹ̀jẹ̀ Abeli títí dé ẹ̀jẹ̀ Sekariah ọmọ Berekiah ẹni tí ẹ pa nínú tẹmpili láàrín ibi pẹpẹ àti ibi ti ẹ yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò wà sórí ìran yìí.