Mat 21:2-5
Mat 21:2-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
O wi fun wọn pe, Ẹ lọ si iletò ti o kọju si nyin, lọgan ẹnyin o ri kẹtẹkẹtẹ kan ti a so ati ọmọ rẹ̀ pẹlu: ẹ tú wọn, ki ẹ si fà wọn fun mi wá. Bi ẹnikẹni ba si wi nkan fun nyin, ẹnyin o wipe, Oluwa ni ifi wọn ṣe; lọgán ni yio si rán wọn wá. Gbogbo eyi li a ṣe, ki eyi ti a ti sọ lati ẹnu wolĩ wá ki o le ṣẹ, pe, Ẹ sọ fun ọmọbinrin Sioni pe, Kiyesi i, Ọba rẹ mbọ̀ wá sọdọ rẹ, o ni irẹlẹ, o joko lori kẹtẹkẹtẹ, ati lori ọmọ kẹtẹkẹtẹ.
Mat 21:2-5 Yoruba Bible (YCE)
Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ lọ sí ìletò tí ó wà ní ọ̀kánkán yín yìí. Bí ẹ bá ti wọ inú rẹ̀, ẹ óo rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí wọ́n so mọ́lẹ̀, pẹlu ọmọ rẹ̀. Ẹ tú wọn, kí ẹ mú wọn wá fún mi. Bí ẹnìkan bá bi yín ní nǹkankan, ẹ dá a lóhùn pé, ‘Oluwa nílò wọn.’ Lẹsẹkẹsẹ wọn yóo jẹ́ kí ẹ mú wọn wá.” Kí ọ̀rọ̀ tí wolii nì sọ lè ṣẹ pé, “Ẹ sọ fún ọdọmọbinrin, Sioni, pé, Wo ọba rẹ tí ó ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ; pẹlu ìrẹ̀lẹ̀, ó gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àní ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ẹranko tí à ń lò láti rẹrù.”
Mat 21:2-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sí ìletò tó wà ni tòsí yín, ẹ̀yin yóò rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan ti wọ́n so pẹ̀lú ọmọ rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ẹ tú wọn, kí ẹ sì mú wọn wá fún mi. Bí ẹnikẹ́ni bá sì béèrè ìdí tí ẹ fi ń ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ sá à wí pé, Olúwa fẹ́ lo wọn, òun yóò sì rán wọn lọ.” Èyí ṣẹlẹ̀ láti mú àsọtẹ́lẹ̀ wòlíì ṣẹ pé: “Ẹ sọ fún ọmọbìnrin Sioni pé, ‘Wò ó, ọba rẹ ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, ní ìrẹ̀lẹ̀, ó ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àti lórí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.’ ”