Mat 21:18-22
Mat 21:18-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati o di owurọ̀, bi o ti npada bọ̀ si Jerusalemu, ebi npa a. Nigbati o ri igi ọ̀pọtọ li ọ̀na, o lọ sibẹ̀, kò si ri ohun kan lori rẹ̀, bikoṣe kìki ewé, o si wi fun u pe, Ki eso ki o má so lori rẹ lati oni lọ titi lailai. Lojukanna igi ọpọtọ na gbẹ. Nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ri i, ẹnu yà wọn, nwọn wipe, Igi ọpọtọ yi mà tete gbẹ? Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, Bi ẹnyin ba ni igbagbọ́, ti ẹ kò ba si ṣiyemeji, ẹnyin kì yio ṣe kìki eyi ti a ṣe si igi ọpọtọ yi, ṣugbọn bi ẹnyin ba tilẹ wi fun òke yi pe, Ṣidi, ki o si bọ́ sinu okun, yio ṣẹ. Ohunkohun gbogbo ti ẹnyin ba bère ninu adura pẹlu igbagbọ́, ẹnyin o ri gbà.
Mat 21:18-22 Yoruba Bible (YCE)
Lówùúrọ̀ ọjọ́ keji, bí ó ti ń pada lọ sinu ìlú, ebi ń pa á. Bí ó ti rí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan lọ́nà, ó yà lọ sí ìdí rẹ̀, ṣugbọn, kò rí nǹkankan lórí rẹ̀ àfi kìkì ewé. Ó bá sọ fún un pé, “O kò ní so mọ́ laelae.” Lẹsẹkẹsẹ ni igi ọ̀pọ̀tọ́ náà bá gbẹ! Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rí i, ẹnu yà wọ́n. Wọ́n ń sọ pé, “Báwo ni igi ọ̀pọ̀tọ́ náà ṣe gbẹ lẹsẹkẹsẹ.” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, bí ẹ bá ní igbagbọ, láì ṣiyèméjì, ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí igi ọ̀pọ̀tọ́ yìí nìkan kọ́ ni ẹ óo ṣe, ṣugbọn bí ẹ bá sọ fún òkè yìí pé, ‘Dìde, kí o lọ rì sinu òkun,’ bẹ́ẹ̀ ni yóo rí. Ohunkohun tí ẹ bá bèèrè ninu adura, bí ẹ bá gbàgbọ́, ẹ óo rí i gbà.”
Mat 21:18-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní òwúrọ̀ bí ó ṣe ń padà sí ìlú, ebi ń pa á. Ó sì ṣàkíyèsí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan lẹ́bàá ojú ọ̀nà, ó sì lọ wò ó bóyá àwọn èso wà lórí rẹ̀, ṣùgbọ́n kò sí ẹyọ kan, ewé nìkan ni ó wà lórí rẹ̀. Nígbà náà ni ó sì wí fún igi náà pé, “Kí èso má tún so lórí rẹ mọ́ láti òní lọ àti títí láé.” Lójúkan náà igi ọ̀pọ̀tọ́ náà sì gbẹ. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ rí èyí, ẹnu yà wọn, wọ́n béèrè pé, “Báwo ni igi ọ̀pọ̀tọ́ náà ṣe gbẹ kíákíá?” Jesu wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, bí ẹ̀yin bá lè ní ìgbàgbọ́ láìṣiyèméjì, nígbà náà ẹ̀yin yóò lè ṣe irú ohun tí a ṣe sí igi ọ̀pọ̀tọ́, Ẹ̀yin yóò lè sọ fún òkè yìí pé, ‘Yí ipò padà sínú Òkun,’ yóò sì rí bẹ́ẹ̀. Bí ẹ̀yin bá gbàgbọ́, ẹ̀yin lè rí ohunkóhun tí ẹ bá béèrè nínú àdúrà gbà.”