Mat 20:29-34
Mat 20:29-34 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi nwọn ti nti Jeriko jade, ọ̀pọ enia tọ̀ ọ lẹhin. Si kiyesi i, awọn ọkunrin afọju meji joko leti ọ̀na, nigbati nwọn gbọ́ pe Jesu nrekọja, nwọn kigbe soke, wipe, Oluwa, iwọ Ọmọ Dafidi, ṣãnu fun wa. Awọn enia si ba wọn wi, nitori ki nwọn ki o ba le pa ẹnu wọn mọ́: ṣugbọn nwọn kigbe jù bẹ̃ lọ, wipe, Oluwa, iwọ Ọmọ Dafidi, ṣãnu fun wa. Jesu si dẹsẹ duro, o pè wọn, o si wipe, Kili ẹnyin nfẹ ki emi ki o ṣe fun nyin? Nwọn wi fun u pe, Oluwa, ki oju wa ki o le là. Bẹ̃ni Jesu ṣãnu fun wọn, o si fi ọwọ́ tọ́ wọn li oju: lọgan oju wọn si là, nwọn si tọ̀ ọ lẹhin.
Mat 20:29-34 Yoruba Bible (YCE)
Bí Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti ń jáde kúrò ní Jẹriko, ọ̀pọ̀ eniyan tẹ̀lé e. Àwọn afọ́jú meji kan jókòó lẹ́bàá ọ̀nà. Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé Jesu ń kọjá lọ, wọ́n kígbe pé, “Ọmọ Dafidi, ṣàánú wa.” Ṣugbọn àwọn eniyan bá wọn wí pé kí wọ́n panu mọ́. Ṣugbọn ńṣe ni wọ́n túbọ̀ ń kígbe pé, “Oluwa ṣàánú wa, ọmọ Dafidi.” Jesu bá dúró, ó pè wọ́n, ó ní, “Kí ni ẹ fẹ́ kí n ṣe fun yín?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Oluwa, a fẹ́ kí ojú wa là ni.” Àánú wọn ṣe Jesu, ó bá fi ọwọ́ kàn wọ́n lójú. Wọ́n ríran lẹsẹkẹsẹ, wọ́n bá ń tẹ̀lé e.
Mat 20:29-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti ń fi ìlú Jeriko sílẹ̀, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì wọ́ tẹ̀lé e lẹ́yìn. Àwọn ọkùnrin afọ́jú méjì sì jókòó lẹ́bàá ọ̀nà, nígbà tí wọ́n sí gbọ́ pé Jesu ń kọjá lọ, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe pé, “Olúwa, Ọmọ Dafidi, ṣàánú fún wa!” Àwọn ènìyàn sí bá wọn wí pé kí wọn dákẹ́, ṣùgbọ́n wọ́n kígbe sókè sí i. “Olúwa, ọmọ Dafidi, ṣàánú fún wa!” Jesu dúró lójú ọ̀nà, ó sì pè wọ́n, Ó béèrè pé, “Kí ni ẹ̀yin fẹ́ kí èmi ṣe fún yín?” Wọ́n dáhùn pé, “Olúwa, àwa fẹ́ kí a ríran.” Àánú wọn sì ṣe Jesu, ó fi ọwọ́ kan ojú wọn. Lójúkan náà, wọ́n sì ríran, wọ́n sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.