Mat 2:13-21

Mat 2:13-21 Yoruba Bible (YCE)

Lẹ́yìn tí àwọn amòye ti pada lọ, angẹli Oluwa kan fara han Josẹfu ní ojú àlá, ó sọ fún un pé, “Dìde, gbé ọmọ náà ati ìyá rẹ̀, kí o sálọ sí Ijipti, kí o sì wà níbẹ̀ títí di ìgbà tí mo bá sọ fún ọ, nítorí Hẹrọdu yóo máa wá ọmọ náà láti pa á.” Josẹfu bá dìde ní òru, ó gbé ọmọ náà ati ìyá rẹ̀, ó lọ sí Ijipti. Níbẹ̀ ni ó wà títí Hẹrọdu fi kú. Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí àsọtẹ́lẹ̀ nì lè ṣẹ pé, “Láti Ijipti ni mo ti pe ọmọ mi.” Nígbà tí Hẹrọdu rí i pé àwọn amòye tan òun jẹ ni, inú bí i pupọ. Ó bá pàṣẹ pé kí wọn máa pa gbogbo àwọn ọmọ-ọwọ́ lọkunrin ní Bẹtilẹhẹmu ati ní gbogbo agbègbè ibẹ̀ láti ọmọ ọdún meji wálẹ̀ títí di ọmọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí, gẹ́gẹ́ bí àkókò tí ó fọgbọ́n wádìí lọ́wọ́ àwọn amòye. Èyí ṣẹlẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí wolii Jeremaya sọ lè ṣẹ pé, “A gbọ́ ohùn kan ní Rama, ẹkún ati ọ̀fọ̀ gidi. Rakẹli ń sunkún nítorí àwọn ọmọ rẹ̀; ó kọ̀, kò gba ìpẹ̀, nítorí wọn kò sí mọ́.” Lẹ́yìn tí Hẹrọdu ti kú, angẹli Oluwa kan fara han Josẹfu ní ojú àlá ní Ijipti. Ó sọ fún un pé, “Dìde, gbé ọmọ náà ati ìyá rẹ́, kí o pada lọ sí ilẹ̀ Israẹli, nítorí àwọn tí wọ́n fẹ́ pa ọmọ náà ti kú.” Josẹfu bá dìde, ó gbé ọmọ náà ati ìyá rẹ̀ pada sí ilẹ̀ Israẹli.

Mat 2:13-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà tí wọn ti lọ, angẹli Olúwa fi ara hàn Josẹfu ní ojú àlá pé, “Dìde, gbé ọmọ ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀, kí ó sì sálọ sí Ejibiti. Dúró níbẹ̀ títí tí èmi yóò fi sọ fún ọ, nítorí Herodu yóò wá ọ̀nà láti pa ọmọ ọwọ́ náà.” Nígbà náà ni ó sì dìde, ó mú ọmọ ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀ ní òru, ó sì lọ sí Ejibiti, ó sì wà níbẹ̀ títí tí Herodu fi kú. Èyí jẹ́ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí Olúwa sọ láti ẹnu wòlíì pé: “Mo pe ọmọ mi jáde láti Ejibiti wá.” Nígbà tí Herodu rí í pé àwọn amòye náà ti tan òun jẹ, ó bínú gidigidi, ó sì pàṣẹ kí a pa gbogbo àwọn ọmọkùnrin tí ó wà ní Bẹtilẹhẹmu àti ní ẹkùn rẹ̀ láti àwọn ọmọ ọdún méjì sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bi àkókò tí ó ti fi ẹ̀sọ̀ ẹ̀sọ̀ béèrè lọ́wọ́ àwọn amòye náà. Nígbà náà ni èyí tí a ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu wòlíì Jeremiah wá ṣẹ pé: “A gbọ́ ohùn kan ní Rama, ohùn réré ẹkún àti ọ̀fọ̀ ńlá, Rakeli ń sọkún àwọn ọmọ rẹ̀. Ó kọ̀ láti gbìpẹ̀ nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ kò sí mọ́.” Lẹ́yìn ikú Herodu, angẹli Olúwa fi ara hàn Josẹfu lójú àlá ní Ejibiti Ó sì wí fún un pé, “Dìde gbé ọmọ ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀ padà sí ilẹ̀ Israẹli, nítorí àwọn tí ń wá ẹ̀mí ọmọ ọwọ́ náà láti pa ti kú.” Nítorí náà, o sì dìde, ó gbé ọmọ ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀ ó sì wá sí ilẹ̀ Israẹli.