Mat 2:1-11

Mat 2:1-11 Bibeli Mimọ (YBCV)

NIGBATI a si bí Jesu ni Betlehemu ti Judea, nigba aiye Herodu ọba, kiyesi, awọn amoye kan ti ìha ìla-õrùn wá si Jerusalemu, Nwọn mbère wipe, Nibo li ẹniti a bí ti iṣe ọba awọn Ju wà? nitori awa ti ri irawọ rẹ̀ ni ìla-õrùn, awa si wá lati foribalẹ fun u. Nigbati Herodu ọba si gbọ́, ara rẹ̀ kò lelẹ, ati gbogbo awọn ará Jerusalemu pẹlu rẹ̀. Nigbati o si pè gbogbo awọn olori alufa ati awọn akọwe awọn enia jọ, o bi wọn lẽre ibiti a o gbé bí Kristi. Nwọn si wi fun u pe, Ni Betlehemu ti Judea ni: nitori bẹ̃li a kọwe rẹ̀ lati ọwọ́ woli nì wá, Iwọ Betlehemu ni ilẹ Judea, iwọ kò kere julọ ninu awọn ọmọ alade Juda, nitori lati inu rẹ ni Bãlẹ kan yio ti jade, ti yio ṣe itọju Israeli awọn enia mi. Nigbana ni Herodu pè awọn amoye na si ìkọkọ, o sì bi wọn lẹsọlẹsọ akokò ti irawọ na hàn. O si rán wọn lọ si Betlehemu, o wipe, Ẹ lọ íwadi ti ọmọ-ọwọ na lẹsọlẹsọ; nigbati ẹnyin ba si ri i, ẹ pada wá isọ fun mi, ki emi ki o le wá iforibalẹ fun u pẹlu. Nigbati nwọn si gbọ́ ọ̀rọ ọba, nwọn lọ; si wò o, irawọ ti nwọn ti ri lati ìha ìla-õrùn wá, o ṣãju wọn, titi o fi wá iduro loke ibiti ọmọ-ọwọ na gbé wà. Nigbati nwọn si ri irawọ na, nwọn yọ̀ ayọ nlanla. Nigbati nwọn si wọ̀ ile, nwọn ri ọmọ-ọwọ na pẹlu Maria iya rẹ̀, nwọn wolẹ, nwọn si foribalẹ fun u: nigbati nwọn si tú iṣura wọn, nwọn ta a lọrẹ wura, ati turari, ati ojia.

Mat 2:1-11 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà tí wọ́n bí Jesu ní Bẹtilẹhẹmu ní ilẹ̀ Judia, ní ayé Hẹrọdu ọba, àwọn amòye kan wá sí Jerusalẹmu láti ìhà ìlà oòrùn. Wọ́n bèèrè pé, “Níbo ni ọmọ tí a bí tí yóo jẹ ọba àwọn Juu wà? A ti rí ìràwọ̀ rẹ̀ ní ìlà oòrùn, nítorí náà ni a ṣe wá láti júbà rẹ̀.” Nígbà tí Hẹrọdu gbọ́, ara rẹ̀ kò balẹ̀, ara gbogbo eniyan ìlú Jerusalẹmu náà kò sì balẹ̀. Ọba bá pe gbogbo àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin láàrin àwọn eniyan, ó wádìí nípa ibi tí a óo ti bí Kristi lọ́wọ́ wọn. Wọ́n sọ fún un pé, “Ní Bẹtilẹhẹmu ti ilẹ̀ Judia ni. Nítorí bẹ́ẹ̀ ni ó wà ní àkọsílẹ̀ wolii nì pé. ‘Àní ìwọ Bẹtilẹhẹmu ilẹ̀ Juda, o kì í ṣe ìlú tí ó rẹ̀yìn jùlọ ninu àwọn olú-ìlú Juda. Nítorí láti inú rẹ ni aṣiwaju kan yóo ti jáde, tí yóo jẹ́ olùṣọ́-aguntan fún Israẹli, eniyan mi.’ ” Hẹrọdu bá pe àwọn amòye náà síkọ̀kọ̀, ó fọgbọ́n wádìí àkókò tí ìràwọ̀ náà yọ lọ́dọ̀ wọn. Ó bá rán wọn lọ sí Bẹtilẹhẹmu. Ó ní, “Ẹ lọ, kí ẹ fẹ̀sọ̀ wádìí nípa ọmọ náà. Nígbà tí ẹ bá rí i, ẹ wá ròyìn fún mi kí èmi náà lè lọ júbà rẹ̀.” Nígbà tí wọn gbọ́ ọ̀rọ̀ ọba, wọ́n lọ. Bí wọ́n ti ń lọ, ìràwọ̀ tí wọ́n ti rí ní ìlà oòrùn bẹ̀rẹ̀ sí lọ níwájú wọn títí ó fi dúró ní ọ̀gangan ibi tí ọmọ náà wà. Nígbà tí wọ́n rí ìràwọ̀ náà, inú wọn dùn gan-an. Bí wọ́n ti wọlé, wọ́n rí ọmọ náà pẹlu Maria ìyá rẹ̀, wọ́n kúnlẹ̀, wọ́n sì júbà rẹ̀. Wọ́n ṣí àpótí ìṣúra wọn, wọ́n fún un ní ẹ̀bùn: wúrà, turari ati òjíá.

Mat 2:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Lẹ́yìn ìgbà tí a bí Jesu ní Bẹtilẹhẹmu ti Judea, ni àkókò ọba Herodu, àwọn amòye ti ìlà-oòrùn wá sí Jerusalẹmu. Wọ́n si béèrè pé, “Níbo ni ẹni náà tí a bí tí í ṣe ọba àwọn Júù wà? Àwa ti rí ìràwọ̀ rẹ̀ ní ìlà-oòrùn, a sì wá láti foríbalẹ̀ fún un.” Nígbà tí ọba Herodu sì gbọ́ èyí, ìdààmú bá a àti gbogbo àwọn ara Jerusalẹmu pẹ̀lú rẹ̀ Nígbà tí ó sì pe àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin jọ, ó bi wọ́n léèrè níbi ti a ó gbé bí Kristi? Wọ́n sì wí pé, “Ní Bẹtilẹhẹmu ti Judea, èyí ni ohun tí wòlíì ti kọ ìwé rẹ̀ pé: “ ‘Ṣùgbọ́n ìwọ Bẹtilẹhẹmu, ní ilẹ̀ Judea, ìwọ kò kéré jù láàrín àwọn ọmọ-aládé Juda; nítorí láti inú rẹ ni Baálẹ̀ kan yóò ti jáde, Ẹni ti yóò ṣe ìtọ́jú Israẹli, àwọn ènìyàn mi.’ ” Nígbà náà ni Herodu ọba pe àwọn amòye náà sí ìkọ̀kọ̀, ó sì wádìí ni ọwọ́ wọn, àkókò náà gan an tí wọ́n kọ́kọ́ rí ìràwọ̀. Ó sì rán wọn lọ sí Bẹtilẹhẹmu, ó sì wí pé, “Ẹ lọ ṣe ìwádìí fínní fínní ní ti ọmọ náà tí a bí. Lẹ́yìn tí ẹ bá sì rí i, ẹ padà wá sọ fún mi, kí èmi náà le lọ foríbalẹ̀ fún un.” Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ọba, wọ́n mú ọ̀nà wọn pọ̀n, sì wò ó, ìràwọ̀ tí wọ́n ti rí láti ìhà ìlà-oòrùn wá, ó ṣáájú wọn, títí tí ó fi dúró lókè ibi tí ọmọ náà gbé wà. Nígbà tí wọ́n sì rí ìràwọ̀ náà, ayọ̀ kún ọkàn wọn. Bí wọ́n tí wọ inú ilé náà, wọn rí ọmọ ọwọ́ náà pẹ̀lú Maria ìyá rẹ̀, wọ́n wólẹ̀, wọ́n foríbalẹ̀ fún un. Nígbà náà ni wọ́n tú ìṣúra wọn, wọ́n sì ta Jesu lọ́rẹ: wúrà, tùràrí àti òjìá.