Mat 19:1-15

Mat 19:1-15 Bibeli Mimọ (YBCV)

O si ṣe, nigbati Jesu pari ọ̀rọ wọnyi tan, o kuro ni Galili, o si lọ si ẹkùn Judea li oke odò Jordani. Ọpọ ijọ enia si tọ̀ ọ lẹhin, o si mu wọn larada nibẹ̀. Awọn Farisi si wá sọdọ rẹ̀, nwọn ndán a wò, nwọn si wi fun u pe, O ha tọ́ fun ọkunrin ki o kọ̀ aya rẹ̀ silẹ nitori ọ̀ran gbogbo? O dahùn o si wi fun wọn pe, Ẹnyin ko ti kà a pe, ẹniti o dá wọn nigba àtetekọṣe o da wọn ti akọ ti abo, O si wipe, Nitori eyi li ọkunrin yio ṣe fi baba ati iya rẹ̀ silẹ, yio famọ́ aya rẹ̀; awọn mejeji a si di ara kan. Nitorina nwọn ki iṣe meji mọ́ bikoṣe ara kan. Nitorina ohun ti Ọlọrun ba so ṣọkan, ki enia ki o máṣe yà wọn. Nwọn wi fun u pe, Ẽṣe ti Mose fi aṣẹ fun wa, wipe, ki a fi iwe ikọsilẹ fun u, ki a si kọ̀ ọ silẹ? O wi fun wọn pe, Nitori lile àiya nyin ni Mose ṣe jẹ fun nyin lati mã kọ̀ aya nyin silẹ, ṣugbọn lati igba àtetekọṣe wá kò ri bẹ̃. Mo si wi fun nyin, ẹnikẹni ti o ba kọ̀ aya rẹ̀ silẹ, bikoṣepe nitori àgbere, ti o si gbé omiran ni iyawo, o ṣe panṣaga: ẹnikẹni ti o ba si gbé ẹniti a kọ̀ silẹ ni iyawo, o ṣe panṣaga. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wi fun u pe, Bi ọ̀ran ọkunrin ba ri bayi si aya rẹ̀, kò ṣànfani lati gbé iyawo. Ṣugbọn o wi fun wọn pe, Gbogbo enia kò le gbà ọ̀rọ yi, bikoṣe awọn ẹniti a fi bùn. Awọn iwẹfa miran mbẹ, ti a bí bẹ̃ lati inu iya wọn wá: awọn iwẹfa miran mbẹ ti awọn araiye sọ di iwẹfa: awọn iwẹfa si wà, awọn ti o sọ ara wọn di iwẹfa nitori ijọba ọrun. Ẹniti o ba le gbà a, ki o gbà a. Nigbana li a gbé awọn ọmọ-ọwọ wá sọdọ rẹ̀ ki o le fi ọwọ́ le wọn, ki o si gbadura: awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si ba wọn wi. Ṣugbọn Jesu ni, Jọwọ awọn ọmọ kekere, ẹ má si ṣe da wọn lẹkun ati wá sọdọ mi; nitori ti irú wọn ni ijọba ọrun. O si fi ọwọ́ le wọn, o si lọ kuro nibẹ̀.

Mat 19:1-15 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà tí Jesu parí àwọn ọ̀rọ̀ wọnyi, ó kúrò ní Galili, ó dé ìgbèríko Judia ní òdìkejì odò Jọdani. Ọ̀pọ̀ eniyan ni ó ń tẹ̀lé e tí ó sì wòsàn níbẹ̀. Àwọn Farisi wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń dán an wò; wọ́n bi í pé, “Ǹjẹ́ ó tọ̀nà pé kí ọkunrin kọ iyawo rẹ̀ sílẹ̀ fún ìdí kankan?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹ kò mọ̀ pé ẹni tí ó dá wọn ní ìbẹ̀rẹ̀, takọ-tabo ni ó dá wọn, tí ó sì wí pé, ‘Ìdí nìyí tí ọkunrin yóo fi fi baba ati ìyá rẹ́ sílẹ̀ tí yóo fara mọ́ iyawo rẹ̀. Àwọn mejeeji yóo wá di ara kan?’ Èyí ni pé wọn kì í tún ṣe ẹni meji mọ́, bíkòṣe ọ̀kan. Nítorí náà ohun tí Ọlọrun bá ti so pọ̀, eniyan kò gbọdọ̀ yà á.” Wọ́n bá tún bi í pé, “Kí ló dé tí Mose fi pàṣẹ pé kí ọkọ fún aya ní ìwé ìkọ̀sílẹ̀, kí ó sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Nítorí líle ọkàn yín ni Mose fi gbà fun yín láti kọ aya yín sílẹ̀. Ní ìbẹ̀rẹ̀ kò rí bẹ́ẹ̀. Mo sọ fun yín pé ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ tí kò bá jẹ́ nítorí àgbèrè, tí ó bá fẹ́ ẹlòmíràn, ó ṣe àgbèrè.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé, “Bí ọ̀ràn láàrin ọkunrin ati obinrin bá rí bẹ́ẹ̀, kò ṣe anfaani láti gbeyawo.” Ṣugbọn ó sọ fún wọn pé, “Kì í ṣe gbogbo eniyan ni ó lè gba nǹkan yìí, àfi àwọn tí Ọlọrun bá fi fún láti gbà á. Nítorí àwọn ẹlòmíràn jẹ́ akúra kí á tó bí wọn, eniyan sọ àwọn mìíràn di akúra; àwọn ẹlòmíràn sì sọ ara wọn di akúra nítorí ti ìjọba ọ̀run. Ẹni tí ó bá lè gba èyí, kí ó gbà á.” Ní àkókò yìí ni wọ́n gbé àwọn ọmọde wá sọ́dọ̀ Jesu, kí ó lè gbé ọwọ́ lé wọn, kí ó sì súre fún wọn. Ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá àwọn tí wọn gbé wọn wá wí. Ṣugbọn Jesu sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọde wá sọ́dọ̀ mi; ẹ má dí wọn lọ́nà, nítorí ti irú wọn ni ìjọba ọ̀run.” Ó bá gbé ọwọ́ lé wọn; ó sì kúrò níbẹ̀.

Mat 19:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Lẹ́yìn tí Jesu ti parí ọ̀rọ̀ yìí, ó kúrò ní Galili. Ó sì yípo padà sí Judea, ó gba ìhà kejì odò Jordani. Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó sì mú wọn láradá níbẹ̀. Àwọn Farisi wá sọ́dọ̀ rẹ̀ láti dán an wò. Wọ́n bi í pé, “Ǹjẹ́ ó tọ̀nà fún ọkùnrin láti kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ nítorí ohunkóhun?” Ó dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ẹyin kò ti kà á pé ‘ẹni tí ó dá wọn ní ìgbà àtètèkọ́ṣe, Ọlọ́run dá wọn ni ti akọ ti abo.’ Ó sì wí fún un pé, ‘Nítorí ìdí èyí ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, òun yóò sì dàpọ̀ mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan.’ Wọn kì í túnṣe méjì mọ́, ṣùgbọ́n ara kan. Nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run bá ti so ṣọ̀kan, kí ẹnikẹ́ni má ṣe yà wọ́n.” Wọ́n bi í pé: “Kí ni ìdí tí Mose fi pàṣẹ pé, ọkùnrin kan lè kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ nípa fífún un ní ìwé ìkọ̀sílẹ̀?” Jesu dáhùn pé, “Nítorí líle àyà yín ni Mose ṣe gbà fún yín láti máa kọ aya yín sílẹ̀. Ṣùgbọ́n láti ìgbà àtètèkọ́ṣe wá, kò rí bẹ́ẹ̀. Mo sọ èyí fún yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, láìṣe pé nítorí àgbèrè, tí ó bá sì fẹ́ ẹlòmíràn, ó ṣe panṣágà.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Bí ọ̀rọ̀ bá rí báyìí láàrín ọkọ àti aya, kó ṣàǹfààní fún wa láti gbé ìyàwó.” Jesu dáhùn pé, “Gbogbo ènìyàn kọ́ ló lé gba ọ̀rọ̀ yìí, bí kò ṣe iye àwọn tí a ti fún. Àwọn mìíràn jẹ́ akúra nítorí bẹ́ẹ̀ ní a bí wọn, àwọn mìíràn ń bẹ tí ènìyàn sọ wọn di bẹ́ẹ̀; àwọn mìíràn kọ̀ láti gbé ìyàwó nítorí ìjọba ọ̀run. Ẹni tí ó bá lè gbà á kí ó gbà á.” Lẹ́yìn náà a sì gbé àwọn ọmọ ọwọ́ wá sọ́dọ̀ Jesu, kí ó lè gbé ọwọ́ lé wọn, kí ó sì gbàdúrà fún wọn. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá àwọn tí ó gbé wọn wá wí. Ṣùgbọ́n Jesu dáhùn pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọdé wá sọ́dọ̀ mi, ẹ má ṣe dá wọn lẹ́kun, nítorí irú wọn ni ìjọba ọ̀run.” Lẹ́yìn náà, ó gbé ọwọ́ lé wọn, ó sì kúrò níbẹ̀.