Mat 18:34-35
Mat 18:34-35 Bibeli Mimọ (YBCV)
Oluwa rẹ̀ si binu, o fi i fun awọn onitubu, titi yio fi san gbogbo gbese eyi ti o jẹ ẹ. Bẹ̃ na gẹgẹ ni Baba mi ti mbẹ li ọrun yio si ṣe fun nyin, bi olukuluku kò ba fi tọkàn-tọkan rẹ̀ dari ẹ̀ṣẹ arakunrin rẹ̀ jì i.
Mat 18:34-35 Yoruba Bible (YCE)
Inú bí olówó rẹ̀, ó bá fà á fún ọ̀gá àwọn ẹlẹ́wọ̀n pé kí wọ́n sọ ọ́ sẹ́wọ̀n títí yóo fi san gbogbo gbèsè tí ó jẹ tán. “Bẹ́ẹ̀ ni Baba mi ọ̀run yóo ṣe si yín bí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín kò bá fi tọkàntọkàn dáríjì arakunrin rẹ̀.”
Mat 18:34-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ìbínú, olówó rẹ̀ fi í lé àwọn onítúbú lọ́wọ́ láti fi ìyà jẹ ẹ́, títí tí yóò fi san gbogbo gbèsè èyí ti ó jẹ ẹ́. “Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sì ni Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run yóò sí ṣe sì ẹnìkọ̀ọ̀kan, bí ẹ̀yin kò bá fi tọkàntọkàn dárí ji àwọn arákùnrin yín.”