Mat 18:28-35
Mat 18:28-35 Yoruba Bible (YCE)
“Nígbà tí ẹrú náà jáde, ó rí ẹrú, ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan tí ó jẹ ẹ́ ní eélòó kan. Ó bá dì í mú, ó fún un lọ́rùn, ó ní; ‘San gbèsè tí o jẹ mí.’ Ẹrú, ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ bá dọ̀bálẹ̀, ó ń bẹ̀ ẹ́ pé, ‘Ṣe sùúrù fún mi, n óo san án fún ọ.’ Ṣugbọn kò gbà; ẹ̀wọ̀n ni ó ní kí wọ́n lọ jù ú sí títí yóo fi san gbèsè tí ó jẹ. Nígbà tí àwọn ẹrú, ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ yòókù rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, inú bí wọn pupọ, wọ́n bá lọ ro ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún olówó wọn. Olówó ẹrú náà bá pè é, ó sọ fún un pé, ‘Ìwọ ẹrú burúkú yìí! Mo bùn ọ́ ní adúrú gbèsè nnì nítorí o bẹ̀ mí. Kò ha yẹ kí ìwọ náà ṣàánú ẹrú, ẹlẹgbẹ́ rẹ, bí mo ti ṣàánú rẹ?’ Inú bí olówó rẹ̀, ó bá fà á fún ọ̀gá àwọn ẹlẹ́wọ̀n pé kí wọ́n sọ ọ́ sẹ́wọ̀n títí yóo fi san gbogbo gbèsè tí ó jẹ tán. “Bẹ́ẹ̀ ni Baba mi ọ̀run yóo ṣe si yín bí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín kò bá fi tọkàntọkàn dáríjì arakunrin rẹ̀.”
Mat 18:28-35 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn nigbati ọmọ-ọdọ na jade lọ, o si ri ọkan ninu awọn ọmọ-ọdọ ẹgbẹ rẹ̀, ti o jẹ ẹ li ọgọrun owo idẹ: o gbé ọwọ́ le e, o fún u li ọrùn, o wipe, San gbese ti iwọ jẹ mi. Ọmọ-ọdọ ẹgbẹ rẹ̀ kunlẹ lẹba ẹsẹ rẹ̀, o si mbẹ̀ ẹ, wipe, Mu sũru fun mi, emi ó si san gbogbo rẹ̀ fun ọ. On kò si fẹ; o lọ, o gbé e sọ sinu tubu titi yio fi san gbese na. Nigbati awọn iranṣẹ ẹgbẹ rẹ̀ ri eyi ti a ṣe, ãnu ṣe wọn gidigidi, nwọn lọ nwọn si sọ gbogbo ohun ti a ṣe fun oluwa wọn. Nigbati oluwa rẹ̀ pè e tan, o wi fun u pe, A! iwọ iranṣẹ buburu yi, Mo fi gbogbo gbese nì jì ọ, nitoriti iwọ bẹ̀ mi: Iwọ kì isi ṣãnu iranṣẹ ẹgbẹ rẹ gẹgẹ bi mo ti ṣãnu fun ọ? Oluwa rẹ̀ si binu, o fi i fun awọn onitubu, titi yio fi san gbogbo gbese eyi ti o jẹ ẹ. Bẹ̃ na gẹgẹ ni Baba mi ti mbẹ li ọrun yio si ṣe fun nyin, bi olukuluku kò ba fi tọkàn-tọkan rẹ̀ dari ẹ̀ṣẹ arakunrin rẹ̀ jì i.
Mat 18:28-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ṣùgbọ́n bí ọmọ ọ̀dọ̀ náà ti jáde lọ, ó rí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ rẹ̀ tí ó jẹ ẹ́ ní ọgọ́rùn-ún owó idẹ, ó gbé ọwọ́ lé e, ó fún un ní ọrùn, ó wí pé, ‘san gbèsè tí o jẹ mí lójú ẹsẹ̀.’ “Ọmọ ọ̀dọ̀ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ náà sì wólẹ̀ lórí eékún níwájú rẹ̀, ò ń bẹ̀ ẹ́ pé, ‘Mú sùúrù fún mi, èmi yóò sì san án fún ọ.’ “Ṣùgbọ́n òun kọ̀ fún un. Ó pàṣẹ kí a mú ọkùnrin náà, kí a sì jù ú sínú túbú títí tí yóò fi san gbèsè náà tán pátápátá. Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, inú bí wọn gidigidi, wọ́n lọ láti lọ sọ fún olúwa wọn, gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀. “Nígbà tí olúwa rẹ̀ pè ọmọ ọ̀dọ̀ náà wọlé, ó wí fún un pé, ‘Ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ búburú, níhìn-ín ni mo ti dárí gbogbo gbèsè rẹ jì ọ́ nítorí tí ìwọ bẹ̀ mi. Kò ha ṣe ẹ̀tọ́ fún ọ láti ṣàánú fún àwọn ẹlòmíràn, gẹ́gẹ́ bí èmi náà ti ṣàánú fún ọ?’ Ní ìbínú, olówó rẹ̀ fi í lé àwọn onítúbú lọ́wọ́ láti fi ìyà jẹ ẹ́, títí tí yóò fi san gbogbo gbèsè èyí ti ó jẹ ẹ́. “Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sì ni Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run yóò sí ṣe sì ẹnìkọ̀ọ̀kan, bí ẹ̀yin kò bá fi tọkàntọkàn dárí ji àwọn arákùnrin yín.”