Mat 18:15-20
Mat 18:15-20 Bibeli Mimọ (YBCV)
Pẹlupẹlu bi arakunrin rẹ ba sẹ̀ ọ, lọ sọ ẹ̀ṣẹ rẹ̀ fun u ti iwọ tirẹ̀ meji: bi o ba gbọ́ tirẹ, iwọ mu arakunrin rẹ bọ̀ sipò. Ṣugbọn bi kò ba gbọ́ tirẹ, nigbana ni ki iwọ ki o mu ẹnikan tabi meji pẹlu ara rẹ, ki gbogbo ọ̀rọ li ẹnu ẹlẹri meji tabi mẹta ba le fi idi mulẹ. Bi o ba si kọ̀ lati gbọ́ wọn, wi fun ijọ enia Ọlọrun: bi o ba si kọ̀ lati gbọ́ ti ijọ enia Ọlọrun, jẹ ki o dabi keferi si ọ ati agbowodè. Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ohunkohun ti ẹnyin ba dè li aiye, a o dè e li ọrun, ohunkohun ti ẹnyin ba si tú li aiye, a o tú u li ọrun. Mo wi fun nyin ẹ̀wẹ pe, Bi ẹni meji ninu nyin ba fi ohùn ṣọkan li aiye yi niti ohunkohun ti nwọn o bère; a o ṣe e fun wọn lati ọdọ Baba mi ti mbẹ li ọrun wá. Nitori nibiti ẹni meji tabi mẹta ba kó ara wọn jọ li orukọ mi, nibẹ̀ li emi o wà li ãrin wọn.
Mat 18:15-20 Yoruba Bible (YCE)
“Bí arakunrin rẹ bá ṣẹ̀ ọ́, tètè lọ bá a sọ̀rọ̀, ìwọ rẹ̀ meji péré. Bí ó bá gbà sí ọ lẹ́nu, o ti tún sọ ọ́ di arakunrin rẹ tòótọ́. Bí kò bá gbọ́, tún lọ bá a sọ ọ́, ìwọ ati ẹnìkan tabi ẹni meji; gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ninu àkọsílẹ̀ pé, ẹ̀rí ẹnu eniyan meji tabi mẹta ni a óo fi mọ òtítọ́ gbogbo ọ̀rọ̀. Bí kò bá gba tiwọn, sọ fún ìjọ. Bí kò bá gba ti ìjọ, kà á kún alaigbagbọ tabi agbowó-odè. “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ohunkohun tí ẹ bá dè ní ayé, ó di dídè ní ọ̀run; ohunkohun tí ẹ bá tú ní ayé, ó di títú ní ọ̀run. “Mo tún sọ fun yín pé bí ẹni meji ninu yín bá fi ohùn ṣọ̀kan ní ayé nípa ohunkohun tí wọn bá bèèrè, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún wọn láti ọ̀dọ̀ Baba mi tí ń bẹ lọ́run. Nítorí níbi tí ẹni meji tabi mẹta bá péjọ ní orúkọ mi, mo wà níbẹ̀ láàrin wọn.”
Mat 18:15-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Bí arákùnrin rẹ bá ṣẹ̀ ọ́, lọ ní ìkọ̀kọ̀ kí o sì sọ ẹ̀bi rẹ̀ fún un. Bí ó bá gbọ́ tìrẹ, ìwọ ti mú arákùnrin kan bọ̀ sí ipò. Ṣùgbọ́n bí òun kò bá tẹ́tí sí ọ, nígbà náà mú ẹnìkan tàbí ẹni méjì pẹ̀lú rẹ, kí ẹ sì tún padà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i, kí ọ̀rọ̀ náà bá le fi ìdí múlẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́rìí méjì tàbí mẹ́ta náà. Bí òun bá sì tún kọ̀ láti tẹ́tí sí wọn, nígbà náà sọ fún ìjọ ènìyàn Ọlọ́run. Bí o bá kọ̀ láti gbọ́ ti ìjọ ènìyàn Ọlọ́run, jẹ́ kí ó dàbí kèfèrí sí ọ tàbí agbowó òde. “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá dè ní ayé, ni a dè ní ọ̀run. Ohunkóhun ti ẹ̀yin bá sì ti tú ni ayé, á ò tú u ní ọ̀run. “Mo tún sọ èyí fún yín, bí ẹ̀yin méjì bá fi ohùn ṣọ̀kan ní ayé yìí, nípa ohunkóhun tí ẹ béèrè, Baba mi ti ń bẹ ní ọ̀run yóò sì ṣe é fún yín. Nítorí níbi ti ènìyàn méjì tàbí mẹ́ta bá kó ara jọ ni orúkọ mi, èmi yóò wà láàrín wọn níbẹ̀.”