Mat 14:34-36
Mat 14:34-36 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati nwọn si rekọja si apakeji, nwọn de ilẹ awọn ara Genesareti. Nigbati awọn enia ibẹ̀ si mọ̀ pe on ni, nwọn ranṣẹ lọ si gbogbo ilu na yiká, nwọn si gbé gbogbo awọn ọlọkunrùn tọ̀ ọ́ wá. Nwọn bẹ̀ ẹ pe, ki nwọn ki o sá le fi ọwọ́ kàn iṣẹti aṣọ rẹ̀: ìwọn gbogbo awọn ti o si fi ọwọ́ kàn a, di alara dida ṣáṣá.
Mat 14:34-36 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn tí wọ́n ti gúnlẹ̀, wọ́n dé ilẹ̀ Genesarẹti. Àwọn eniyan ibẹ̀ ti dá a mọ̀, wọ́n bá ranṣẹ lọ sí gbogbo agbègbè ibẹ̀; wọ́n gbé gbogbo àwọn tí ara wọn kò dá wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Wọ́n ń bẹ̀ ẹ́ pé kí wọn sá lè fi ọwọ́ kan etí ẹ̀wù rẹ̀. Gbogbo àwọn tí wọ́n fi ọwọ́ kàn án ni ó mú lára dá.
Mat 14:34-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí wọn rékọjá sí apá kejì wọ́n gúnlẹ̀ sí Genesareti. Nígbà tiwọn mọ̀ pé Jesu ni, wọn sì ránṣẹ́ sí gbogbo ìlú náà yíká. Wọ́n sì gbé gbogbo àwọn aláìsàn tọ̀ ọ́ wá. Àwọn aláìsàn bẹ̀ ẹ́ pé kí ó gba àwọn láyè láti fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀, gbogbo àwọn tí ó ṣe bẹ́ẹ̀ sì rí ìwòsàn.