Mat 14:25-33
Mat 14:25-33 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati o di iṣọ kẹrin oru, Jesu tọ̀ wọn lọ, o nrìn lori okun. Nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ri i ti o nrìn lori okun, ẹ̀ru bà wọn, nwọn wipe, Iwin ni; nwọn fi ibẹru kigbe soke. Ṣugbọn lojukanna ni Jesu wi fun wọn pe, Ẹ tújuka; Emi ni; ẹ má bẹ̀ru. Peteru si dá a lohùn, wipe, Oluwa, bi iwọ ba ni, paṣẹ ki emi tọ̀ ọ wá lori omi. O si wipe, Wá. Nigbati Peteru sọkalẹ lati inu ọkọ̀ lọ, o rìn loju omi lati tọ̀ Jesu lọ. Ṣugbọn nigbati o ri ti afẹfẹ le, ẹru ba a; o si bẹ̀rẹ si irì, o kigbe soke, wipe, Oluwa, gbà mi. Lojukanna Jesu si nà ọwọ́ rẹ̀, o dì i mu, o si wi fun u pe, Iwọ onigbagbọ́ kekere, ẽṣe ti iwọ fi nṣiyemeji? Nigbati nwọn si bọ́ sinu ọkọ̀, afẹfẹ dá. Nigbana li awọn ti mbẹ ninu ọkọ̀ wá, nwọn si fi ori balẹ fun u, wipe, Lõtọ Ọmọ Ọlọrun ni iwọ iṣe.
Mat 14:25-33 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó di nǹkan bí agogo mẹta òru, Jesu ń bọ̀ lọ́dọ̀ wọn, ó ń rìn lójú omi òkun. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rí i tí ó ń rìn lójú omi, ẹ̀rù bà wọ́n gan-an, wọ́n ń sọ pé, “Iwin ni!” Wọ́n bá kígbe, nítorí ẹ̀rù bà wọ́n. Lẹsẹkẹsẹ Jesu sọ fún wọn pé, “Ẹ ṣe ara gírí. Èmi ni. Ẹ má bẹ̀rù!” Peteru sọ fún un pé, “Oluwa, bí ó bá jẹ́ pé ìwọ ni, sọ pé kí n máa rìn bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ lójú omi.” Jesu bá sọ fún un pé, “Máa bọ̀!” Ni Peteru bá sọ̀kalẹ̀ ninu ọkọ̀, ó rìn lójú omi lọ sọ́dọ̀ Jesu. Ṣugbọn nígbà tí ó rí i tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́, ẹ̀rù bà á, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí rì. Ó bá kígbe pé, “Oluwa, gbà mí!” Lẹsẹkẹsẹ Jesu bá fà á lọ́wọ́, ó sọ fún un pé, “Ìwọ onigbagbọ kékeré yìí! Kí ni ó mú ọ ṣe iyè meji?” Bí wọ́n ti wọ inú ọkọ́ ni afẹ́fẹ́ bá rọlẹ̀. Àwọn tí ó wà ninu ọkọ̀ júbà rẹ̀, wọ́n ń sọ pé, “Lóòótọ́, Ọmọ Ọlọrun ni ọ́!”
Mat 14:25-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní déédé ago mẹ́rin òwúrọ̀, Jesu tọ̀ wọ́n wá, ó ń rìn lórí omi. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rí i tí ó ń rìn lójú omi, ẹ̀rù ba wọn gidigidi, wọ́n rò pé “iwin ni” wọ́n kígbe tìbẹ̀rù tìbẹ̀rù. Lójúkan náà, Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ mú ọkàn le! Èmi ni ẹ má ṣe bẹ̀rù.” Peteru sì ké sí i pé, “Olúwa, bí ó bá jẹ́ pé ìwọ ni nítòótọ́, sọ pé kí n tọ̀ ọ́ wà lórí omi.” Jesu dá a lóhùn pé, “Ó dára, máa bọ̀ wá.” Nígbà náà ni Peteru sọ̀kalẹ̀ láti inú ọkọ̀. Ó ń rìn lórí omi lọ sí ìhà ọ̀dọ̀ Jesu. Nígbà tí ó rí afẹ́fẹ́ líle, ẹ̀rù bà á, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rì. Ó kígbe lóhùn rara pé, “Gbà mí, Olúwa.” Lójúkan náà, Jesu na ọwọ́ rẹ̀, ó dìímú, ó sì gbà á. Ó sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ṣiyèméjì ìwọ onígbàgbọ́ kékeré?” Àti pé, nígbà ti wọ́n sì gòkè sínú ọkọ̀, ìjì náà sì dúró jẹ́ẹ́. Nígbà náà ni àwọn to wà nínú ọkọ̀ náà foríbalẹ̀ fún un wọ́n wí pé, “Nítòótọ́ ọmọ Ọlọ́run ni ìwọ í ṣe.”