Mat 14:15-21
Mat 14:15-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati o di aṣalẹ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ tọ̀ ọ wá, wipe, Ibi ijù li eyi, ọjọ si kọja tan: rán ijọ enia lọ, ki nwọn ki o le lọ si iletò lọ irà onjẹ fun ara wọn. Jesu si wi fun wọn pe, Nwọn kò ni ilọ; ẹ fun wọn li onjẹ. Nwọn si wi fun u pe, Awa kò ni jù iṣu akara marun ati ẹja meji nihinyi. O si wipe, Ẹ mu wọn fun mi wá nihinyi. O si paṣẹ ki ijọ enia joko lori koriko, o si mu iṣu akara marun ati ẹja meji na; nigbati o gbé oju soke ọrun, o sure, o si bù u, o fi akara na fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si fifun ijọ enia. Gbogbo wọn si jẹ, nwọn si yó; nwọn si ko ajẹkù ti o kù jọ, agbọ̀n mejila kún. Awọn ti o si jẹ ẹ to ìwọn ẹgbẹ̃dọgbọn ọkunrin, li aikà awọn obinrin ati awọn ọmọde.
Mat 14:15-21 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n ní, “Aṣálẹ̀ ni ibí yìí, ọjọ́ sì ti lọ. Fi àwọn eniyan wọnyi sílẹ̀ kí wọ́n lè lọ ra oúnjẹ fún ara wọn ninu àwọn ìletò.” Ṣugbọn Jesu sọ fún wọn pé, “Kò yẹ kí wọ́n lọ; ẹ fún wọn ní oúnjẹ jẹ.” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Kò sí oúnjẹ níhìn-ín, àfi burẹdi marun-un ati ẹja meji.” Ó ní, “Ẹ kó wọn wá fún mi níhìn-ín.” Ó bá pàṣẹ pé kí àwọn eniyan jókòó lórí koríko. Ó mú burẹdi marun-un náà ati ẹja meji; ó gbé ojú sókè ọ̀run, ó dúpẹ́, ó bá bù wọ́n, ó kó wọn fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá pín in fún àwọn eniyan. Gbogbo wọn jẹ, wọ́n yó, àjẹkù sì kún apẹ̀rẹ̀ mejila. Àwọn eniyan tí ó jẹun tó ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) ọkunrin láì ka àwọn obinrin ati àwọn ọmọde.
Mat 14:15-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà ti ilẹ̀ ń ṣú lọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì wí pé, “Ibi yìí jìnnà sí ìlú ilẹ̀ sì ń ṣú lọ. Rán àwọn ènìyàn lọ sí àwọn ìletò kí wọ́n lè ra oúnjẹ jẹ.” Ṣùgbọ́n Jesu fèsì pé, “Kò nílò kí wọ́n lọ kúrò. Ẹ fún wọn ní oúnjẹ.” Wọ́n sì dalóhùn pé, “Àwa kò ní ju ìṣù àkàrà márùn-ún àti ẹja méjì lọ níhìn-ín.” Ó wí pé, “Ẹ mú wọn wá fún mi níhìn-ín yìí.” Lẹ́yìn náà, ó wí fún àwọn ènìyàn kí wọ́n jókòó lórí koríko. Lẹ́yìn náà, ó mú ìṣù àkàrà márùn-ún àti ẹja méjì. Ó gbé ojú rẹ̀ sí ọ̀run. Ó béèrè ìbùkún Ọlọ́run lórí oúnjẹ náà, Ó sì bù ú, ó sì fi àkàrà náà fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn láti pín in fún àwọn ènìyàn. Gbogbo wọn sì jẹ àjẹyó. Lẹ́yìn náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kó àjẹkù jọ, ó kún agbọ̀n méjìlá. Iye àwọn ènìyàn ni ọjọ́ náà jẹ́ ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (5,000) ọkùnrin, Láìka àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé.