Mat 14:13-20

Mat 14:13-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà tí Jesu gbọ́ ìròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ó kúrò níbẹ̀, ó bá ọkọ̀ ojú omi lọ sí ibi kọ́lọ́fín kan ní èbúté láti dá wà níbẹ̀. Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì fi ẹsẹ̀ rìn tẹ̀lé e láti ọ̀pọ̀ ìlú wọn. Nígbà ti Jesu gúnlẹ̀, tí ó sì rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, inú rẹ̀ yọ́ sí wọn, ó sì mú àwọn aláìsàn láradá. Nígbà ti ilẹ̀ ń ṣú lọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì wí pé, “Ibi yìí jìnnà sí ìlú ilẹ̀ sì ń ṣú lọ. Rán àwọn ènìyàn lọ sí àwọn ìletò kí wọ́n lè ra oúnjẹ jẹ.” Ṣùgbọ́n Jesu fèsì pé, “Kò nílò kí wọ́n lọ kúrò. Ẹ fún wọn ní oúnjẹ.” Wọ́n sì dalóhùn pé, “Àwa kò ní ju ìṣù àkàrà márùn-ún àti ẹja méjì lọ níhìn-ín.” Ó wí pé, “Ẹ mú wọn wá fún mi níhìn-ín yìí.” Lẹ́yìn náà, ó wí fún àwọn ènìyàn kí wọ́n jókòó lórí koríko. Lẹ́yìn náà, ó mú ìṣù àkàrà márùn-ún àti ẹja méjì. Ó gbé ojú rẹ̀ sí ọ̀run. Ó béèrè ìbùkún Ọlọ́run lórí oúnjẹ náà, Ó sì bù ú, ó sì fi àkàrà náà fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn láti pín in fún àwọn ènìyàn. Gbogbo wọn sì jẹ àjẹyó. Lẹ́yìn náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kó àjẹkù jọ, ó kún agbọ̀n méjìlá.