Mat 14:13-14
Mat 14:13-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati Jesu si gbọ́, o dide kuro nibẹ̀, o ba ti ọkọ̀ lọ si ibi ijù, on nikan; nigbati awọn enia si gbọ́, nwọn si ti ilu wọn rìn tọ̀ ọ li ẹsẹ. Jesu jade lọ, o ri ọ̀pọlọpọ enia, inu rẹ̀ si yọ́ si wọn, o si ṣe dida arùn ara wọn.
Mat 14:13-14 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Jesu gbọ́, ó wọ ọkọ̀ ojú omi kúrò níbẹ̀ lọ sí ibìkan tí eniyan kò sí, kí ó lè dá wà. Nígbà tí àwọn eniyan gbọ́, wọ́n gba ọ̀nà ẹlẹ́sẹ̀ láti ìlú wọn, wọ́n tẹ̀lé e. Bí ó ti ń gúnlẹ̀, ó rí ọ̀pọ̀ eniyan. Àánú wọn ṣe é, ó bá wo àwọn tí wọ́n ṣàìsàn ninu wọn sàn.
Mat 14:13-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí Jesu gbọ́ ìròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ó kúrò níbẹ̀, ó bá ọkọ̀ ojú omi lọ sí ibi kọ́lọ́fín kan ní èbúté láti dá wà níbẹ̀. Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì fi ẹsẹ̀ rìn tẹ̀lé e láti ọ̀pọ̀ ìlú wọn. Nígbà ti Jesu gúnlẹ̀, tí ó sì rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, inú rẹ̀ yọ́ sí wọn, ó sì mú àwọn aláìsàn láradá.