Mat 14:1-12
Mat 14:1-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
LI akokò na ni Herodu tetrarki gbọ́ okikí Jesu, O si wi fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, Johanu Baptisti li eyi; o jinde kuro ninu okú; nitorina ni iṣẹ agbara ṣe hàn lara rẹ̀. Herodu sá ti mu Johanu, o dè e, o si fi i sinu tubu, nitori Herodia aya Filippi arakunrin rẹ̀. Johanu sá ti wi fun u pe, ko tọ́ fun ọ lati ni i. Nigbati o si nfẹ pa a, o bẹ̀ru ijọ enia, nitoriti nwọn kà a si wolĩ. Ṣugbọn nigbati a nṣe iranti ọjọ ibí Herodu, ọmọbinrin Herodia jó lãrin wọn, inu Herodu si dùn. Nitorina li o ṣe fi ibura ṣe ileri lati fun u li ohunkohun ti o ba bère. Ẹniti iya rẹ̀ ti kọ́ tẹlẹ ri, o wipe, Fun mi li ori Johanu Baptisti nihinyi ninu awopọkọ. Inu ọba si bajẹ: ṣugbọn nitori ibura rẹ̀, ati awọn ti o bá a joko tì onjẹ, o ni ki a fi fun u. O si ranṣẹ lọ, o bẹ́ Johanu li ori ninu tubu. A si gbé ori rẹ̀ wá ninu awopọkọ, a si fifun ọmọbinrin na; o si gbé e tọ̀ iya rẹ̀ lọ. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si wá, nwọn gbé okú rẹ̀ sin, nwọn si lọ, nwọn si wi fun Jesu.
Mat 14:1-12 Yoruba Bible (YCE)
Ní àkókò náà, Hẹrọdu ọba gbúròó Jesu. Ó wí fún àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ pé, “Johanu Onítẹ̀bọmi ni èyí. Òun ni ó jí dìde kúrò ninu òkú. Ìdí rẹ̀ nìyí tí ó fi ní agbára láti lè ṣe iṣẹ́ ìyanu.” Nítorí Hẹrọdu yìí ni ó ti pàṣẹ pé kí wọ́n mú Johanu, kí wọ́n dè é, kí wọ́n sì fi í sẹ́wọ̀n nítorí ọ̀rọ̀ Hẹrọdiasi, iyawo Filipi, arakunrin Hẹrọdu. Nítorí Johanu sọ fún Hẹrọdu pé kò tọ́ fún un láti fi Hẹrọdiasi ṣaya. Hẹrọdu fẹ́ pa á, ṣugbọn ó bẹ̀rù àwọn eniyan, nítorí wọ́n gbà pé wolii ni Johanu. Nígbà tí Hẹrọdu ń ṣe ọjọ́ ìbí rẹ̀, ọdọmọbinrin Hẹrọdiasi bẹ̀rẹ̀ sí jó lójú agbo. Èyí dùn mọ́ Hẹrọdu ninu tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi fi ìbúra ṣe ìlérí láti fún un ní ohunkohun tí ó bá bèèrè. Lẹ́yìn tí ìyá ọmọbinrin yìí ti kọ́ ọ ní ohun tí yóo bèèrè, ó ní, “Gbé orí Johanu Onítẹ̀bọmi wá fún mi nisinsinyii ninu àwo pẹrẹsẹ kan.” Ó dun ọba, ṣugbọn nítorí pé ó ti búra, ati nítorí àwọn tí ó wà níbi àsè, ó gbà láti fi fún un. Ọba bá ranṣẹ pé kí wọ́n bẹ́ Johanu lórí ninu ẹ̀wọ̀n tí ó wá. Wọ́n gbé orí rẹ̀ wá ninu àwo pẹrẹsẹ, wọ́n gbé e fún ọdọmọbinrin náà. Ó bá lọ gbé e fún ìyá rẹ̀. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu bá wá, wọ́n gbé òkú rẹ̀ lọ, wọ́n sin ín; wọ́n sì lọ ròyìn fún Jesu.
Mat 14:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní àkókò náà ni Herodu ọba tetrarki gbọ́ nípa òkìkí Jesu, ó wí fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, “Dájúdájú Johanu onítẹ̀bọmi ni èyí, ó jíǹde kúrò nínú òkú. Ìdí nìyí tí ó fi ní agbára láti ṣiṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí.” Nísinsin yìí Herodu ti mú Johanu, ó fi ẹ̀wọ̀n dè é, ó sì fi sínú túbú, nítorí Herodia aya Filipi arákùnrin rẹ̀, nítorí Johanu onítẹ̀bọmi ti sọ fún Herodu pé, “Kò yẹ fún ọ láti fẹ́ obìnrin náà.” Herodu fẹ́ pa Johanu, ṣùgbọ́n ó bẹ̀rù àwọn ènìyàn nítorí gbogbo ènìyàn gbàgbọ́ pé wòlíì ni. Ní ọjọ́ àsè ìrántí ọjọ́ ìbí Herodu, ọmọ Herodia obìnrin jó dáradára, ó sì tẹ́ Herodu lọ́run gidigidi. Nítorí náà ni ó ṣe fi ìbúra ṣe ìlérí láti fún un ní ohunkóhun ti ó bá béèrè fún. Pẹ̀lú ìmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ ìyá rẹ̀, ó béèrè pé, “Fún mi ni orí Johanu onítẹ̀bọmi nínú àwopọ̀kọ́”. Inú ọba bàjẹ́ gidigidi, ṣùgbọ́n nítorí ìbúra rẹ̀ àti kí ojú má ba à tì í níwájú àwọn àlejò tó wà ba jẹ àsè, ó pàṣẹ pé kí wọ́n fún un gẹ́gẹ́ bí o ti fẹ́. Nítorí náà, a bẹ́ orí Johanu onítẹ̀bọmi nínú ilé túbú. A sì gbé orí rẹ̀ jáde láti fi fún ọmọbìnrin náà nínú àwopọ̀kọ́, òun sì gbà á, ó gbé e tọ ìyá rẹ̀ lọ. Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu wá gba òkú rẹ̀, wọ́n sì sin ín. Wọ́n sì wá sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún Jesu.