Mat 13:24-32
Mat 13:24-32 Bibeli Mimọ (YBCV)
Owe miran li o pa fun wọn, wipe: Ijọba ọrun dabi ọkunrin ti o fún irugbin rere si oko rẹ̀: Ṣugbọn nigbati enia sùn, ọtá rẹ̀ wá, o fún èpo sinu alikama, o si ba tirẹ̀ lọ. Ṣugbọn nigbati ẽhu rẹ̀ sọ jade, ti o si so eso, nigbana li èpo buburu fi ara hàn pẹlu. Bẹ̃li awọn ọmọ-ọdọ bãle na tọ̀ ọ wá, nwọn wi fun u pe, Oluwa, irugbin rere ki iwọ fún sinu oko rẹ? nibo li o ha ti li èpo buburu? O si wi fun wọn pe, Ọtá li o ṣe eyi. Awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ si bi i pe, Iwọ ha fẹ́ ki a lọ fà wọn tu kuro? O si wipe, Bẹ̃kọ, nigbati ẹnyin ba ntu èpo kuro, ki ẹnyin ki o má bà tu alikama pẹlu wọn. Ẹ jẹ ki awọn mejeji ki o dàgba pọ̀ titi di igba ikorè: li akokò ikorè emi o si wi fun awọn olukore pe, Ẹ tètekọ kó èpo jọ, ki ẹ di wọn ni ití lati fi iná sun wọn, ṣugbọn ẹ kó alikama sinu abà mi. Owe miran li o pa fun wọn, wipe, Ijọba ọrun dabi wóro irugbin mustardi kan, eyiti ọkunrin kan mu ti o si gbìn sinu oko rẹ̀: Eyiti o kére jù gbogbo irugbin lọ; ṣugbọn nigbati o dàgba, o tobi jù gbogbo ewebẹ lọ, o si di igi, tobẹ ti awọn ẹiyẹ oju ọrun si wá, nwọn ngbé ori ẹ̀ka rẹ̀.
Mat 13:24-32 Yoruba Bible (YCE)
Ó tún pa òwe mìíràn fún wọn. Ó ní, “Bí ìjọba ọ̀run ti rí nìyí. Ó dàbí ọkunrin kan tí ó gbin irúgbìn rere sí oko rẹ̀. Nígbà tí àwọn eniyan sùn, ọ̀tá rẹ̀ wá, ó gbin èpò sáàrin ọkà, ó bá lọ. Nígbà tí ọkà dàgbà, tí ó yọ ọmọ, èpò náà dàgbà. Àwọn ẹrú baálé náà bá wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n bi í pé, ‘Alàgbà, ṣebí irúgbìn rere ni o gbìn sí oko, èpò ti ṣe débẹ̀?’ Ó dá wọn lóhùn pé, ‘Ọ̀tá ni ó ṣe èyí.’ Àwọn ẹrú rẹ̀ ní, ‘Ṣé kí á lọ tu wọ́n dànù?’ Ó bá dá wọn lóhùn pé, ‘Rárá o! Bí ẹ bá wí pé ẹ̀ ń tu èpò, ẹ óo tu ọkà náà. Ẹ jẹ́ kí àwọn mejeeji jọ dàgbà pọ̀ títí di ìgbà ìkórè. Ní àkókò ìkórè, n óo sọ fún àwọn olùkórè pé: ẹ kọ́ kó èpò jọ, kí ẹ dì wọ́n nítìí-nítìí, kí ẹ dáná sun ún. Kí ẹ wá kó ọkà jọ sinu abà mi.’ ” Ó tún pa òwe mìíràn fún wọn. Ó ní, “Báyìí ni ìjọba ọ̀run rí. Ó dàbí wóró musitadi tí ẹnìkan gbìn sinu oko rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni ó kéré jùlọ ninu gbogbo irúgbìn, sibẹ nígbà tí ó bá dàgbà, a tóbi ju gbogbo ewébẹ̀ lọ. A di igi, tí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run óo wá ṣe ìtẹ́ wọn lára ẹ̀ka rẹ̀.”
Mat 13:24-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Jesu tún pa òwe mìíràn fún wọn: “Ìjọba ọ̀run dàbí àgbẹ̀ kan tí ó gbin irúgbìn rere sí oko rẹ̀; Ṣùgbọ́n ní òru ọjọ́ kan, nígbà tí ó sùn, ọ̀tá rẹ̀ wá sí oko náà ó sì gbin èpò sáàrín alikama, ó sì bá tirẹ̀ lọ. Nígbà tí alikama náà bẹ̀rẹ̀ sí dàgbà, tí ó sì so èso, nígbà náà ni èpò náà fi ara hàn. “Àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ àgbẹ̀ náà wá, wọ́n sọ fún un pé, ‘Ọ̀gá, irúgbìn rere kọ́ ni ìwọ ha gbìn sí oko rẹ nì? Báwo ni èpò ṣe wà níbẹ̀ nígbà náà?’ “Ó sọ fún wọn pé, ‘Ọ̀tá ni ó ṣe èyí.’ “Àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ tún bí i pé, ‘Ǹjẹ́ ìwọ ha fẹ́ kí a fa èpò náà tu kúrò?’ “Ó dá wọn lóhùn pé, ‘Rárá, nítorí bí ẹ̀yin bá ń tu èpò kúrò, ẹ ó tu alikama dànù pẹ̀lú rẹ̀. Ẹ jẹ́ kí àwọn méjèèjì máa dàgbà pọ̀, títí di àsìkò ìkórè. Èmi yóò sọ fún àwọn olùkórè náà láti kọ́kọ́ ṣa àwọn èpò kúrò kí wọ́n sì dìwọ́n ní ìtí, kí a sì sun wọn, kí wọ́n sì kó alikama sínú àká mi.’ ” Jesu tún pa òwe mìíràn fún wọn: “Ìjọba ọ̀run dàbí èso hóró musitadi, èyí tí ọkùnrin kan mú tí ó gbìn sínú oko rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ èso tí ó kéré púpọ̀ láàrín èso rẹ̀, síbẹ̀ ó wá di ohun ọ̀gbìn tí ó tóbi jọjọ. Ó sì wá di igi tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì wá, wọ́n sì fi ẹ̀ka rẹ ṣe ibùgbé.”