Mat 13:18-23
Mat 13:18-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitorina ẹ gbọ́ owe afunrugbin. Nigbati ẹnikan ba gbọ́ ọ̀rọ ijọba, ti kò ba si yé e, nigbana li ẹni-buburu ni wá, a si mu eyi ti a fún si àiya rẹ̀ kuro. Eyi li ẹniti o gbà irugbin lẹba ọ̀na. Ẹniti o si gbà irugbin lori apata, on li o gbọ́ ọ̀rọ na, ti o si fi ayọ̀ gbà a kánkan. Ṣugbọn ko ni gbongbo ninu ara rẹ̀, o si pẹ diẹ li akokò kan; nigbati wahalà tabi inunibini si dide nitori ọ̀rọ na, lojukanna a kọsẹ̀. Eyi pẹlu ti o gbà irugbin sarin ẹgún li ẹniti o gbọ́ ọ̀rọ na; aniyan aiye yi, ati itanjẹ ọrọ̀ si fún ọ̀rọ na pa, bẹ̃li o si jẹ alaileso. Ṣugbọn ẹniti o gbà irugbin si ilẹ rere li ẹniti o gbọ́ ọ̀rọ na, ti o si yé e; on li o si so eso pẹlu, o si so omiran ọgọrọrun, omiran ọgọtọta, omiran ọgbọgbọ̀n.
Mat 13:18-23 Yoruba Bible (YCE)
“Ẹ gbọ́ ìtumọ̀ òwe afunrugbin. Ẹni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ìjọba ọ̀run, tí nǹkan tí ó gbọ́ kò yé e, tí èṣù wá, tí ó mú ohun tí a gbìn sọ́kàn rẹ̀ lọ: òun ni irúgbìn ti ẹ̀bá ọ̀nà. Irúgbìn ti orí ilẹ̀ olókùúta ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí ó fi tayọ̀tayọ̀ gbà á lẹsẹkẹsẹ. Ṣugbọn nítorí kò ní gbòǹgbò ninu ara rẹ̀, ọ̀rọ̀ náà yóo wà fún ìgbà díẹ̀. Nígbà tí inúnibíni tabi ìṣòro bá dé nítorí ọ̀rọ̀ náà, lẹsẹkẹsẹ a kùnà. Ti ààrin igi ẹlẹ́gùn-ún ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí àníyàn ayé yìí ati ìtànjẹ ọrọ̀ fún ọ̀rọ̀ náà pa, tí kò fi so èso. Ṣugbọn èyí tí a fún sórí ilẹ̀ rere ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí ọ̀rọ̀ náà yé, tí ó wá ń so èso, nígbà mìíràn, ọgọrun-un; nígbà mìíràn, ọgọta; nígbà mìíràn, ọgbọ̀n.”
Mat 13:18-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Nítorí náà, ẹ fi etí sí ohun tí òwe afúnrúgbìn túmọ̀ sí: Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ ọ̀rọ̀ nípa ìjọba ọ̀run ṣùgbọ́n tí kò yé e, lẹ́yìn náà èṣù á wá, a sì gba èyí tí a fún sí ọkàn rẹ̀ kúrò. Èyí ni irúgbìn ti a fún sí ẹ̀bá ọ̀nà. Ẹni tí ó sì gba irúgbìn tí ó bọ́ sí ilẹ̀ orí àpáta, ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, lọ́gán, ó sì fi ayọ̀ gba ọ̀rọ̀ náà. Ṣùgbọ́n nítorí kò ní gbòǹgbò, ó wà fún ìgbà díẹ̀; nígbà tí wàhálà àti inúnibíni bá dìde nítorí ọ̀rọ̀ náà ní ojú kan náà yóò sì kọsẹ̀. Ẹni tí ó si gba irúgbìn tí ó bọ́ sí àárín ẹ̀gún ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ṣùgbọ́n àwọn àníyàn ayé yìí, ìtànjẹ, ọrọ̀ sì fún ọ̀rọ̀ náà pa, ọ̀rọ̀ náà kò so èso nínú rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó gba irúgbìn tí ó bọ́ sí orí ilẹ̀ rere ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí ó sì yé e; òun sì so èso òmíràn ọgọ́rọ̀ọ̀rùn, òmíràn ọgọ́tọ̀ọ̀ta, òmíràn ọgbọọgbọ̀n.”