Mat 12:46-50
Mat 12:46-50 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati o nsọ̀rọ wọnyi fun awọn enia, wò o, iya rẹ̀ ati awọn arakunrin rẹ̀ duro lode, nwọn nfẹ ba a sọ̀rọ. Nigbana li ẹnikan wi fun u pe, Wo o, iya rẹ ati awọn arakunrin rẹ duro lode, nwọn nfẹ ba ọ sọ̀rọ. Ṣugbọn o dahùn o si wi fun ẹniti o sọ fun u pe, Tani iya mi? ati tani awọn arakunrin mi? O si nà ọwọ́ rẹ̀ si awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o wipe, Ẹ wò iya mi ati awọn arakunrin mi! Nitori ẹnikẹni ti o ba nṣe ifẹ Baba mi ti mbẹ li ọrun, on na li arakunrin mi, ati arabinrin mi, ati iya mi.
Mat 12:46-50 Yoruba Bible (YCE)
Bí Jesu ti ń bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀ ni ìyá rẹ̀ ati àwọn arakunrin rẹ̀ bá dé, wọ́n dúró lóde, wọ́n fẹ́ bá a sọ̀rọ̀. [ Ẹnìkan sọ fún un pé, “Ìyá rẹ ati àwọn arakunrin rẹ dúró lóde, wọ́n fẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀.”] Jesu dá a lóhùn pé, “Ta ni ìyá mi? Àwọn ta sì ni arakunrin mi?” Ó bá nawọ́ sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó ní, “Wò ó ìyá mi ati àwọn arakunrin mi nìwọ̀nyí. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ìfẹ́ Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run, òun ni arakunrin mi ati arabinrin mi ati ìyá mi.”
Mat 12:46-50 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún àwọn ènìyàn, wò ó, ìyá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ dúró lóde, wọ́n fẹ́ bá a sọ̀rọ̀. Nígbà náà ni ẹnìkan wí fún un pé, “Ìyá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ ń dúró dè ọ́ lóde wọ́n ń fẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀.” Ó sì fún ni èsì pé, “Ta ni ìyá mi? Ta ni àwọn arákùnrin mi?” Ó nawọ́ sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó wí pé, “Wò ó, ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi ni wọ̀nyí.” Nítorí náà, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ìfẹ́ Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run, ni arákùnrin mi àti arábìnrin mi àti ìyá mi.”