Mat 12:43-45
Mat 12:43-45 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati ẹmi aimọ́ kan ba jade kuro lara enia, a ma rìn kiri ni ibi gbigbẹ, a ma wá ibi isimi, kì si iri. Nigbana ni o wipe, Emi o pada lọ si ile mi, nibiti mo gbé ti jade wá; nigbati o si de, o bá a, o ṣofo, a gbá a mọ́, a si ṣe e li ọṣọ. Nigbana li o lọ, o si mu ẹmi meje miran pẹlu ara rẹ̀, ti o buru jù on tikararẹ̀ lọ; nwọn bọ si inu rẹ̀, nwọn si ngbé ibẹ̀; igbẹhin ọkunrin na si buru jù iṣaju rẹ̀ lọ. Gẹgẹ bẹ̃ni yio ri fun iran buburu yi pẹlu.
Mat 12:43-45 Yoruba Bible (YCE)
“Nígbà tí ẹ̀mí èṣù jáde kúrò ninu ẹnìkan, ó bẹ̀rẹ̀ sí wá ilẹ̀ gbígbẹ láti sinmi. Ó ń wá ibi tí yóo fi ṣe ibùgbé, ṣugbọn kò rí. Ó bá ni, ‘N óo tún pada sí ilé mi, níbi tí mo ti jáde kúrò.’ Nígbà tí ó débẹ̀, ó rí i pé ibẹ̀ ṣófo, ati pé a ti gbá a, a sì ti tọ́jú rẹ̀ dáradára. Ó bá lọ, ó kó àwọn ẹ̀mí meje mìíràn lẹ́yìn tí wọ́n burú ju òun alára lọ, wọ́n bá wọlé, wọ́n ń gbé ibẹ̀. Ìgbẹ̀yìn ẹni náà wá burú ju ti àkọ́kọ́ lọ. Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún ìran burúkú yìí.”
Mat 12:43-45 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Nígbà tí ẹ̀mí búburú kan bá jáde lára ènìyàn, a máa rìn ní ibi gbígbẹ́, a máa wá ibi ìsinmi, kò sì ní rí i. Nígbà náà ni ẹ̀mí náà yóò wí pé, ‘Èmi yóò padà sí ara ọkùnrin tí èmí ti wá.’ Bí ó bá sì padà, tí ó sì bá ọkàn ọkùnrin náà ni òfìfo, a gbà á mọ́, a sì ṣe é ní ọ̀ṣọ́. Nígbà náà ni yóò lọ, yóò sì mú ẹ̀mí méje mìíràn pẹ̀lú ara rẹ̀, tí ó burú ju òun fúnra rẹ̀ lọ. Gbogbo wọn yóò sì wá sí inú rẹ̀, wọn yóò máa gbé ibẹ̀. Ìgbẹ̀yìn ọkùnrin náà a sì burú ju ìṣáájú rẹ̀ lọ; Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò rí fún ìran búburú yìí pẹ̀lú.”