Mat 12:34-35
Mat 12:34-35 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹnyin ọmọ paramọlẹ, ẹnyin ti iṣe enia buburu yio ti ṣe le sọ̀rọ rere? nitori ninu ọ̀pọlọpọ ohun inu li ẹnu isọ. Enia rere lati inu iṣura rere ọkàn rẹ̀ ni imu ohun rere jade wá: ati enia buburu lati inu iṣura buburu ni imu ohun buburu jade wá.

Mat 12:34-35 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ̀yin ìran paramọ́lẹ̀ yìí! Báwo ni ọ̀rọ̀ yín ti ṣe lè dára nígbà tí ẹ̀yin fúnra yín kò dára? Nítorí ohun tí ó bá kún inú ọkàn ni ẹnu ń sọ jáde. Ẹni rere a máa sọ ọ̀rọ̀ rere jáde láti inú ìṣúra rere; eniyan burúkú a sì máa sọ ọ̀rọ̀ burúkú jáde láti inú ìṣúra burúkú.
Mat 12:34-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ̀yin ọmọ paramọ́lẹ̀, báwo ni ẹ̀yin tí ẹ jẹ búburú ṣe lè sọ̀rọ̀ rere? Ọkàn ènìyàn ni ó ń darí irú ọ̀rọ̀ tí ó lè jáde lẹ́nu rẹ̀. Ẹni rere láti inú yàrá ìṣúra rere ọkàn rẹ̀ ní mú ohun rere jáde wá: àti ẹni búburú láti inú ìṣúra búburú ni; mu ohun búburú jáde wá.