Mat 12:28-31
Mat 12:28-31 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn bi o ba ṣe pe Ẹmí Ọlọrun li emi fi nlé awọn ẹmi èṣu jade, njẹ ijọba Ọlọrun de ba nyin. Tabi ẹnikan yio ti ṣe wọ̀ ile alagbara lọ, ki o si kó o li ẹrù, bikoṣepe o kọ́ dè alagbara na? nigbana ni yio si kó o ni ile. Ẹniti kò ba wà pẹlu mi, o nṣe odi si mi; ẹniti kò ba si bá mi kopọ̀, o nfọnka. Nitorina ni mo wi fun nyin, gbogbo irú ẹ̀ṣẹ-kẹṣẹ ati ọrọ-odi li a o darijì enia; ṣugbọn ọrọ-odi si Ẹmí Mimọ́, on li a ki yio darijì enia.
Mat 12:28-31 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé nípa Ẹ̀mí Ọlọrun ni mo fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, a jẹ́ pé ìjọba Ọlọrun ti dé ba yín. “Báwo ni ẹnìkan ṣe lè wọ ilé alágbára lọ, kí ó kó o lẹ́rù, bí kò bá kọ́kọ́ de alágbára náà? Bí ó bá kọ́kọ́ dè é ni yóo tó lè kó o lẹ́rù. “Ẹni tí kò bá ṣe tèmi, ó lòdì sí mi. Ẹni tí kò bá máa bá mi kó nǹkan jọ, ó ń fọ́nká ni. Ìdí nìyí tí mo fi sọ fun yín pé gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ati gbogbo ìsọ̀rọ̀ òdì ni a óo dárí rẹ̀ ji eniyan; ṣugbọn ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ òdì sí Ẹ̀mí Mímọ́ kò ní rí ìdáríjì.
Mat 12:28-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé nípa Ẹ̀mí Ọlọ́run ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, a jẹ́ pé ìjọba Ọlọ́run ti dé bá yín. “Tàbí, báwo ni ẹnikẹ́ni ṣe lè wọ ilé alágbára lọ kí ó sì kó ẹrù rẹ̀, bí kò ṣe pé ó kọ́kọ́ di alágbára náà? Nígbà náà ni ó tó lè kó ẹrù rẹ̀ lọ. “Ẹni tí kò bá wà pẹ̀lú mi, òun lòdì sí mi, ẹni tí kò bá mi kójọpọ̀ ń fọ́nká. Nítorí èyí, mo wí fún yín, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àti ọ̀rọ̀-òdì ni a yóò dárí rẹ̀ jí ènìyàn, ṣùgbọ́n ìṣọ̀rọ̀-òdì-sí Ẹ̀mí Mímọ́ kò ní ìdáríjì.