Mat 1:1-25

Mat 1:1-25 Bibeli Mimọ (YBCV)

IWE iran Jesu Kristi, ọmọ Dafidi ọmọ Abrahamu. Abrahamu bí Isaaki; Isaaki si bí Jakọbu; Jakọbu si bí Juda ati awọn arakunrin rẹ̀; Juda si bí Faresi ati Sara ti Tamari; Faresi si bí Esromu; Esromu si bí Aramu; Aramu si bí Aminadabu; Aminadabu si bí Naaṣoni; Naaṣoni si bí Salmoni; Salmoni si bí Boasi ti Rakabu; Boasi si bí Obedi ti Rutu; Obedi si bí Jesse; Jesse si bí Dafidi ọba. Dafidi ọba si bí Solomoni lati ọdọ ẹniti o ti nṣe aya Uria; Solomoni si bí Rehoboamu; Rehoboamu si bí Abia; Abia si bí Asa; Asa si bí Jehosafati; Jehosafati si bí Joramu; Joramu si bí Osia; Osia si bí Joatamu; Joatamu si bí Akasi; Akasi si bí Hesekiah; Hesekiah si bí Manasse; Manasse si bí Amoni; Amoni si bí Josiah; Josiah si bí Jekoniah ati awọn arakunrin rẹ̀, nigba ikolọ si Babiloni. Lẹhin ikolọ si Babiloni ni Jekoniah bí Sealtieli; Sealtieli si bí Serubabeli; Serubabeli si bí Abiudu; Abiudu si bí Eliakimu; Eliakimu si bí Asoru; Asoru si bí Sadoku; Sadoku si bí Akimu; Akimu si bí Eliudu; Eliudu si bí Eleasa; Eleasa si bí Matani; Matani si bí Jakọbu; Jakọbu si bí Josefu ọkọ Maria, lati ọdọ ẹniti a bí Jesu, ti a npè ni Kristi. Bẹ̃ni gbogbo iran lati Abrahamu wá de Dafidi jẹ iran mẹrinla; ati lati Dafidi wá de ikolọ si Babiloni jẹ iran mẹrinla; ati lati igba ikólọ si Babiloni de igba Kristi o jẹ iran mẹrinla. Bi ibí Jesu Kristi ti ri niyi: li akokò ti a fẹ Maria iya rẹ̀ fun Josefu, ki nwọn to pade, a ri i, o lóyun lati ọwọ́ Ẹmí Mimọ́ wá. Josefu ọkọ rẹ̀, ti iṣe olõtọ enia, ko si fẹ dojutì i ni gbangba, o fẹ ikọ̀ ọ silẹ ni ìkọkọ. Ṣugbọn nigbati o nrò nkan wọnyi, wò o, angẹli Oluwa yọ si i li oju alá, o wipe, Josefu, iwọ ọmọ Dafidi, má fòiya lati mu Maria aya rẹ si ọdọ; nitori eyi ti o yún ninu rẹ̀, lati ọwọ́ Ẹmí Mimọ́ ni. Yio si bí ọmọkunrin kan, Jesu ni iwọ o pè orukọ rẹ̀: nitori on ni yio gbà awọn enia rẹ̀ là kuro ninu ẹ̀ṣẹ wọn. Gbogbo eyi si ṣẹ, ki eyi ti a ti sọ lati ọdọ Oluwa wá li ẹnu woli ki o le ṣẹ, pe, Kiyesi i, wundia kan yio lóyun, yio si bí ọmọkunrin kan, nwọn o mã pè orukọ rẹ̀ ni Emmanueli, itumọ eyi ti iṣe, Ọlọrun wà pẹlu wa. Nigbati Josefu dide ninu orun rẹ̀, o ṣe bi angẹli Oluwa ti wi fun u, o si mu aya rẹ̀ si ọdọ: On ko si mọ̀ ọ titi o fi bí akọbi rẹ̀ ọmọkunrin: o si pè orukọ rẹ̀ ni JESU.

Mat 1:1-25 Yoruba Bible (YCE)

Èyí ni àkọsílẹ̀ ìran Jesu Kristi, ọmọ Dafidi, ọmọ Abrahamu. Abrahamu bí Isaaki, Isaaki bí Jakọbu, Jakọbu bí Juda ati àwọn arakunrin rẹ̀. Juda bí Peresi ati Sera, ìyá wọn ni Tamari. Peresi bí Hesironi, Hesironi bí Ramu. Ramu bí Aminadabu, Aminadabu bí Naṣoni, Naṣoni bí Salimoni. Salimoni bí Boasi, ìyá Boasi ni Rahabu, Boasi bí Obedi. Ìyá Obedi ni Rutu. Obedi bí Jese. Jese bí Dafidi ọba. Dafidi bí Solomoni. Aya Uraya tẹ́lẹ̀ ni ìyá Solomoni. Solomoni bí Rehoboamu, Rehoboamu bí Abija, Abija bí Asa. Asa bí Jehoṣafati, Jehoṣafati bí Joramu, Joramu bí Usaya. Usaya bí Jotamu, Jotamu bí Ahasi, Ahasi bí Hesekaya. Hesekaya bí Manase, Manase bí Amosi, Amosi bí Josaya. Josaya bí Jekonaya ati àwọn arakunrin rẹ̀ ní àkókò tí wọn kó àwọn ọmọ Israẹli lẹ́rú lọ sí Babiloni. Lẹ́yìn tí wọn kó wọn lẹ́rú lọ sí Babiloni, Jekonaya bí Ṣealitieli, Ṣealitieli bí Serubabeli. Serubabeli bí Abihudi, Abihudi bí Eliakimu, Eliakimu bí Asori. Asori bí Sadoku, Sadoku bí Akimu, Akimu bí Eliudi. Eliudi bí Eleasari, Eleasari bí Matani, Matani bí Jakọbu. Jakọbu bí Josẹfu ọkọ Maria, ẹni tí ó bí Jesu tí à ń pè ní Kristi. Nítorí náà, gbogbo ìran Jesu láti ìgbà Abrahamu títí di ti Dafidi jẹ́ mẹrinla; láti ìgbà Dafidi títí di ìgbà tí wọn kó àwọn ọmọ Israẹli lẹ́rú lọ sí Babiloni jẹ́ ìran mẹrinla; láti ìgbà tí wọn kó wọn lẹ́rú lọ sí Babiloni títí di àkókò Kristi jẹ́ ìran mẹrinla. Bí ìtàn ìbí Jesu Kristi ti rí nìyí. Nígbà tí Maria ìyá rẹ̀ wà ní iyawo àfẹ́sọ́nà Josẹfu, kí wọn tó ṣe igbeyawo, a rí i pé Maria ti lóyún láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́. Eniyan rere ni Josẹfu ọkọ rẹ̀, kò fẹ́ dójú tì í, ó fẹ́ rọra kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní bòńkẹ́lẹ́. Bí ó ti ń ronú bí yóo ti gbé ọ̀rọ̀ náà gbà, angẹli Oluwa kan fara hàn án lójú àlá. Ó sọ fún un pé, “Josẹfu, ọmọ Dafidi, má bẹ̀rù láti mú Maria aya rẹ sọ́dọ̀, nítorí láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ ni oyún tí ó ní. Yóo bí ọmọkunrin kan, o óo sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jesu nítorí òun ni yóo gba àwọn eniyan rẹ̀ là kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ wọn.” Gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí OLUWA ti sọ láti ẹnu wolii nì lè ṣẹ pé, “Wundia kan yóo lóyún, yóo bí ọmọkunrin kan; wọn yóo pe orúkọ rẹ̀ ní Imanuẹli.” (Ìtumọ̀, “Imanuẹli” ni “Ọlọrun wà pẹlu wa.”) Nígbà tí Josẹfu jí láti ojú oorun, ó ṣe gẹ́gẹ́ bí angẹli Oluwa náà ti pàṣẹ fún un. Ó mú iyawo rẹ̀ sọ́dọ̀. Kò sì bá a lòpọ̀ rárá títí ó fi bímọ. Ó sì pe orúkọ ọmọ náà ní Jesu.

Mat 1:1-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ìwé ìran Jesu Kristi, ẹni tí í ṣe ọmọ Dafidi, ọmọ Abrahamu: Abrahamu ni baba Isaaki; Isaaki ni baba Jakọbu; Jakọbu ni baba Juda àti àwọn arákùnrin rẹ̀, Juda ni baba Peresi àti Sera, Tamari sì ni ìyá rẹ̀, Peresi ni baba Hesroni: Hesroni ni baba Ramu; Ramu ni baba Amminadabu; Amminadabu ni baba Nahiṣoni; Nahiṣoni ni baba Salmoni; Salmoni ni baba Boasi, Rahabu sí ni ìyá rẹ̀; Boasi ni baba Obedi, Rutu sí ni ìyá rẹ̀; Obedi sì ni baba Jese; Jese ni baba Dafidi ọba. Dafidi ni baba Solomoni, ẹni tí ìyá rẹ̀ jẹ́ aya Uriah tẹ́lẹ̀ rí. Solomoni ni baba Rehoboamu, Rehoboamu ni baba Abijah, Abijah ni baba Asa, Asa ni baba Jehoṣafati; Jehoṣafati ni baba Jehoramu; Jehoramu ni baba Ussiah; Ussiah ni baba Jotamu; Jotamu ni baba Ahaṣi; Ahaṣi ni baba Hesekiah; Hesekiah ni baba Manase; Manase ni baba Amoni; Amoni ni baba Josiah; Josiah sì ni baba Jekoniah àti àwọn arákùnrin rẹ̀ ní àkókò ìkólọ sí Babeli. Lẹ́yìn ìkólọ sí Babeli: Jekoniah ni baba Ṣealitieli; Ṣealitieli ni baba Serubbabeli; Serubbabeli ni baba Abihudi; Abihudi ni baba Eliakimu; Eliakimu ni baba Asori; Asori ni baba Sadoku; Sadoku ni baba Akimu; Akimu ni baba Elihudi; Elihudi ni baba Eleasari; Eleasari ni baba Mattani; Mattani ni baba Jakọbu; Jakọbu ni baba Josẹfu, ẹni tí ń ṣe ọkọ Maria, ìyá Jesu, ẹni tí í ṣe Kristi. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo wọ́n jẹ́ ìran mẹ́rìnlá láti orí Abrahamu dé orí Dafidi, ìran mẹ́rìnlá á láti orí Dafidi títí dé ìkólọ sí Babeli, àti ìran mẹ́rìnlá láti ìkólọ títí dé orí Kristi. Bí a ṣe bí Jesu Kristi nìyìí: Ní àkókò ti àdéhùn ìgbéyàwó ti parí láàrín Maria ìyá rẹ̀ àti Josẹfu, ṣùgbọ́n kí wọn tó pàdé, a rí i ó lóyún láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́. Nítorí Josẹfu ọkọ rẹ̀ tí í ṣe olóòtítọ́ ènìyàn kò fẹ́ dójútì í ní gbangba, ó ní èrò láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó ro èrò yìí tán, angẹli Olúwa yọ sí i ní ojú àlá, ó wí pé, “Josẹfu, ọmọ Dafidi, má fòyà láti fi Maria ṣe aya rẹ, nítorí oyún tí ó wà nínú rẹ̀ láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ ni. Òun yóò sì bí ọmọkùnrin, ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jesu, nítorí òun ni yóò gba àwọn ènìyàn rẹ̀ là kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.” Gbogbo nǹkan wọ̀nyí sì ṣẹ láti mú ọ̀rọ̀ Olúwa ṣẹ èyí tí a sọ láti ẹnu wòlíì rẹ̀ wá pé: “Wúńdíá kan yóò lóyún, yóò sì bí ọmọkùnrin kan, yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Emmanueli,” èyí tí ó túmọ̀ sí, “Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa.” Nígbà tí Josẹfu jí lójú oorun rẹ̀, òun ṣe gẹ́gẹ́ bí angẹli Olúwa ti pàṣẹ fún un. Ó mú Maria wá sílé rẹ̀ ní aya. Ṣùgbọ́n òun kò mọ̀ ọ́n títí tí ó fi bí ọmọkùnrin, òun sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Jesu.