Mal 2:13-16
Mal 2:13-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Eyi li ẹnyin si tún ṣe, ẹnyin fi omije, ati ẹkún, ati igbe, bò pẹpẹ Oluwa mọlẹ, tobẹ̃ ti on kò fi kà ọrẹ nyin si mọ, tabi ki o fi inu-didùn gbà nkan lọwọ nyin. Ṣugbọn ẹnyin wipe, Nitori kini? Nitori Oluwa ti ṣe ẹlẹri lãrin iwọ ati lãrin aya ewe rẹ, ẹniti iwọ ti nhùwa ẹ̀tan si: bẹ̃li ẹgbẹ́ rẹ li on sa iṣe, ati aya majẹmu rẹ. On kò ha ti ṣe ọkan? bẹ̃li on ni iyokù ẹmi. Ẽ si ti ṣe jẹ ọkan? ki on ba le wá iru-ọmọ bi ti Ọlọrun. Nitorina ẹ tọju ẹmi nyin, ẹ má si jẹ ki ẹnikẹni hùwa ẹ̀tan si aya ewe rẹ̀. Nitori Oluwa, Ọlọrun Israeli wipe, on korira ikọ̀silẹ: ẹnikan fi ìwa-ipá bò aṣọ rẹ̀ mọlẹ, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: nitorina ẹ ṣọ ẹmi nyin, ki ẹ má ṣe hùwa ẹ̀tan.
Mal 2:13-16 Yoruba Bible (YCE)
Ohun mìíràn tí ẹ tún ń ṣe nìyí. Ẹ̀ ń sọkún, omijé ojú yín ń ṣàn lára pẹpẹ OLUWA, ẹ̀ ń sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ sì ń ké, nítorí pé OLUWA kò gba ọrẹ tí ẹ mú wá fún un. Ẹ̀ ń bèèrè pé, “Kí ló dé tí kò fi gbà á?” Ìdí rẹ̀ ni pé, OLUWA ni ẹlẹ́rìí majẹmu tí ẹ dá pẹlu aya tí ẹ fẹ́ nígbà èwe yín, tí ẹ sì ṣe aiṣootọ sí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé olùrànlọ́wọ́ yín ni, òun sì ni aya tí ẹ bá dá majẹmu. Ṣebí ara kan náà ati ẹ̀jẹ̀ kan náà ni Ọlọrun ṣe ìwọ pẹlu rẹ̀? Kí ló dé tí Ọlọrun fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí rẹ̀ ni pé, Ọlọrun ń fẹ́ irú ọmọ tí yóo jẹ́ tirẹ̀. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra yín, kí ẹ má ṣe hùwà aiṣootọ sí aya tí ẹ fẹ́ nígbà èwe yín. “Mo kórìíra ìkọ̀sílẹ̀ láàrin tọkọtaya, mo kórìíra irú ìwà ìkà bẹ́ẹ̀ sí olólùfẹ́ ẹni. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má ṣe jẹ́ alaiṣootọ sí aya yín. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí!”
Mal 2:13-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èyí ni ohun mìíràn tí ẹ̀yin sì túnṣe: Ẹ̀yin fi omijé bo pẹpẹ OLúWA mọ́lẹ̀. Ẹ̀yin sọkún, ẹ̀yin sì ba ara jẹ́ nítorí tì Òun kò ka ọrẹ yín sí mọ́, tàbí kí ó fi inú dídùn gba nǹkan yìí lọ́wọ́ yín. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wí pé, “Nítorí kín ní?” Nítorí OLúWA ti ṣe ẹlẹ́rìí láàrín ìwọ àti láàrín aya èwe rẹ, ẹni tí ìwọ ti ń hùwà ẹ̀tàn sí i: bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkejì rẹ ni òun jẹ́, àti aya májẹ̀mú rẹ. Ọlọ́run kò ha ti ṣe wọ́n ní ọ̀kan? Ni ara àti ni ẹ̀mí tirẹ̀ ni. Èéṣe tí Ọlọ́run da yín lọ́kàn? Kí òun bá à lè wá irú-ọmọ bí ti Ọlọ́run. Nítorí náà, ẹ tọ́jú ẹ̀mí yín, ẹ má sì ṣe hùwà ẹ̀tàn sí aya èwe yín. “Ọkùnrin tí ó bá kórìíra, tí ó sì kọ ìyàwó rẹ̀,” Ṣe ìwà ipá sí ẹni tí ó yẹ kí ó dá ààbò bò, ni OLúWA Ọlọ́run Israẹli wí, Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ ẹ̀mí yín, kí ẹ má ṣe hùwà ẹ̀tàn.