Mal 1:6
Mal 1:6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọmọ a ma bọla fun baba, ati ọmọ-ọdọ fun oluwa rẹ̀: njẹ bi emi ba ṣe baba, ọla mi ha da? bi emi ba si ṣe oluwa, ẹ̀ru mi ha da? li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi fun nyin: Ẹnyin alufa, ti ngàn orukọ mi. Ẹnyin si wipe, Ninu kini awa fi kẹ́gàn orukọ rẹ?
Mal 1:6 Yoruba Bible (YCE)
“Ọmọ a máa bọ̀wọ̀ fún baba rẹ̀, iranṣẹ a sì máa bẹ̀rù oluwa rẹ̀. Bí mo bá jẹ́ baba yín, ṣé ẹ̀ ń bọ̀wọ̀ fún mi? Bí mo bá sì jẹ́ oluwa yín, ṣé ẹ bẹ̀rù mi ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ń bi ẹ̀yin alufaa tí ẹ̀ ń tàbùkù orúkọ mi? Sibẹsibẹ ẹ̀ ń bèèrè pé, ‘Ọ̀nà wo ni a fi ń tàbùkù orúkọ rẹ?’
Mal 1:6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ọmọ a máa bu ọ̀wọ̀ fún baba rẹ̀, ọmọ ọ̀dọ̀ a sì máa bu ọlá fún olúwa rẹ̀. Ǹjẹ́ bí èmí bá jẹ́ baba, ọlá tí ó tọ́ sí mi ha dà? Bí èmi bá sì jẹ́ olúwa, ẹ̀rù tí ó tọ́ sí mi dà?” ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí. “Ẹ̀yin ni, ẹ̀yin àlùfáà, ni ẹ ń gan orúkọ mi. “Ṣùgbọ́n ẹ̀yin béèrè pé, ‘Báwo ni àwa ṣe gan orúkọ rẹ?’