Mal 1:1-5
Mal 1:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọ̀RỌ-ÌMỌ ọ̀rọ Oluwa si Israeli nipa ọwọ Malaki. Emi ti fẹ nyin, li Oluwa wi. Ṣugbọn ẹnyin wipe, Ninu kili o fẹ wa? Arakunrin Jakobu ki Esau iṣe? li Oluwa wi: bẹli emi sa fẹ Jakobu, Mo si korira Esau, mo si sọ awọn oke-nla rẹ̀ ati ilẹ nini rẹ̀ di ahoro fun awọn dragoni aginjù. Nitori Edomu wipe, A run wa tan, ṣugbọn awa o padà, a si kọ ibùgbe ahoro wọnni; bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; Nwọn o kọ, ṣugbọn emi o wo lulẹ; Nwọn o si pe wọn ni, Agbègbe ìwa buburu, ati awọn enia ti Oluwa ni ikọnnu si titi lai. Oju nyin o si ri, ẹnyin o si wipe, A o gbe Oluwa ga lati oke agbègbe Israeli wá.
Mal 1:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Iṣẹ́ tí OLUWA rán wolii Malaki sí àwọn ọmọ Israẹli nìyí. OLUWA ní, “Mo fẹ́ràn yín pupọ.” Ṣugbọn ẹ̀ ń bèèrè pé, “Kí ló fihàn pé o fẹ́ràn wa?” OLUWA dáhùn pé, “Ṣebí tẹ̀gbọ́n-tàbúrò ni Esau ati Jakọbu? Sibẹ mo fẹ́ràn Jakọbu, mo sì kórìíra Esau. Mo ti sọ gbogbo àwọn ìlú òkè Esau di ahoro, mo sì sọ ilẹ̀ ìní rẹ̀ di ilé ajáko tí ó wà ní aṣálẹ̀.” Bí Edomu bá sọ pé, “Ìlú wa ti di òkítì àlàpà, ṣugbọn a óo tún un kọ́.” Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo wá dáhùn pé, “Wọ́n lè máa kọ́ ọ, ṣugbọn n óo tún máa wó o lulẹ̀ títí tí àwọn eniyan yóo fi máa pè wọ́n ní orílẹ̀-èdè burúkú, àwọn ẹni tí OLUWA bínú sí títí lae.” Ẹ óo fi ojú ara yín rí i ẹ óo sì sọ pé, “OLUWA tóbi lọ́ba, kódà títí dé ilẹ̀ tí kì í ṣe ilẹ̀ Israẹli!”
Mal 1:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀: ọ̀rọ̀ OLúWA sí Israẹli láti ẹnu Malaki. “Èmí ti fẹ́ ẹ yín,” ni OLúWA wí. “Ṣùgbọ́n ẹ̀yin béèrè pé, ‘Báwo ni ìwọ ṣe fẹ́ wa?’ “Esau kì í ha ṣe arákùnrin Jakọbu bí?” ni OLúWA wí. “Síbẹ̀ èmi fẹ́ràn Jakọbu, ṣùgbọ́n Esau ni mo kórìíra, mo ti sọ àwọn òkè ńlá rẹ̀ di aṣálẹ̀, mo sì fi ìní rẹ̀ fún àwọn akátá aginjù.” Edomu lè wí pé, “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a run wá, àwa yóò padà wá, a ó sì tún ibùgbé náà kọ́.” Ṣùgbọ́n èyí ni ohun tí OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Àwọn lè kọ́, ṣùgbọ́n èmi yóò wó palẹ̀. Wọn yóò sì pè wọ́n ní ilẹ̀ búburú, àwọn ènìyàn tí wọ́n máa ń wà ní ìbínú OLúWA. Ẹ̀yin yóò sì fi ojú yín rí i, ẹ̀yin yóò sì wí pé, ‘Títóbi ni OLúWA, títóbi rẹ̀ tayọ kọjá agbègbè Israẹli.’