Luk 9:57-58
Luk 9:57-58 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe, bi nwọn ti nlọ li ọ̀na, ọkunrin kan wi fun u pe, Oluwa, Emi nfẹ lati ma tọ̀ ọ lẹhin nibikibi ti iwọ ba nlọ. Jesu si wi fun u pe, Awọn kọ̀lọkọlọ ni ihò, awọn ẹiyẹ oju ọrun si ni itẹ́; ṣugbọn Ọmọ-enia kò ni ibi ti yio fi ori rẹ̀ le.
Pín
Kà Luk 9Luk 9:57-58 Yoruba Bible (YCE)
Bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà, ẹnìkan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní, “N óo máa bá ọ lọ sí ibikíbi tí o bá ń lọ.” Jesu dá a lóhùn pé, “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ní ìtẹ́, ṣugbọn Ọmọ-Eniyan kò ní ibi tí yóo gbé orí rẹ̀ lé.”
Pín
Kà Luk 9Luk 9:57-58 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà, ọkùnrin kan wí fún un pé, “Olúwa, Èmi ń fẹ́ láti máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ní ibikíbi tí ìwọ bá ń lọ.” Jesu sì wí fún un pé, “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ní ìtẹ́; ṣùgbọ́n ọmọ ènìyàn kò ní ibi tí yóò fi orí rẹ̀ lé.”
Pín
Kà Luk 9