Luk 9:51-62

Luk 9:51-62 Bibeli Mimọ (YBCV)

O si ṣe, nigbati ọjọ atigbà soke rẹ̀ pé, o gbé oju le gangan lati lọ si Jerusalemu. O si rán awọn onṣẹ lọ si iwaju rẹ̀: nigbati nwọn si lọ nwọn wọ̀ iletò kan ti iṣe ti ara Samaria lọ ipèse silẹ dè e. Nwọn kò si gbà a, nitoriti oju rẹ̀ dabi ẹnipe o nlọ si Jerusalemu. Nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ Jakọbu on Johanu si ri i, nwọn ni, Oluwa, iwọ ko jẹ ki awa ki o pè iná lati ọrun wá, ki a sun wọn lúlu, bi Elijah ti ṣe? Ṣugbọn Jesu yipada, o si ba wọn wi, o ni, Ẹnyin kò mọ̀ irú ẹmí ti mbẹ ninu nyin. Nitori Ọmọ-enia ko wá lati pa ẹmi enia run, bikoṣe lati gbà a là. Nwọn si lọ si iletò miran. O si ṣe, bi nwọn ti nlọ li ọ̀na, ọkunrin kan wi fun u pe, Oluwa, Emi nfẹ lati ma tọ̀ ọ lẹhin nibikibi ti iwọ ba nlọ. Jesu si wi fun u pe, Awọn kọ̀lọkọlọ ni ihò, awọn ẹiyẹ oju ọrun si ni itẹ́; ṣugbọn Ọmọ-enia kò ni ibi ti yio fi ori rẹ̀ le. O si wi fun ẹlomiran pe, Mã tọ̀ mi lẹhin. Ṣugbọn o wi fun u pe, Oluwa, jẹ ki emi ki o kọ́ lọ isinku baba mi na. Jesu si wi fun u pe, Jẹ́ ki awọn okú ki o mã sinkú ara wọn: ṣugbọn iwọ lọ ki o si mã wãsu ijọba Ọlọrun. Ẹlomiran si wi fun u pe, Oluwa, emi nfẹ lati mã tọ̀ ọ lẹhin; ṣugbọn jẹ ki emi ki o pada lọ idagbere fun awọn ara ile mi. Jesu si wi fun u pe, Kò si ẹni, ti o fi ọwọ́ rẹ̀ le ohun-elo itulẹ, ti o si wò ẹhin, ti o yẹ fun ijọba Ọlọrun.

Luk 9:51-62 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà tí ó tó àkókò tí a óo gbé Jesu lọ sókè ọ̀run, ọkàn rẹ̀ mú un láti lọ sí Jerusalẹmu. Ó bá rán àwọn oníṣẹ́ ṣiwaju rẹ̀. Wọ́n bá wọ inú ìletò àwọn ará Samaria kan láti ṣe ètò sílẹ̀ dè é. Ṣugbọn wọn kò gbà á, nítorí ó hàn dájú pé ó ń lọ sí Jerusalẹmu. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Jakọbu ati Johanu, rí i, wọ́n ní, “Oluwa, ṣé o fẹ́ kí á pe iná láti ọ̀run kí ó jó wọn pa?” Ṣugbọn Jesu yipada, ó bá wọn wí. Ni wọ́n bá lọ sí ìletò mìíràn. Bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà, ẹnìkan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní, “N óo máa bá ọ lọ sí ibikíbi tí o bá ń lọ.” Jesu dá a lóhùn pé, “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ní ìtẹ́, ṣugbọn Ọmọ-Eniyan kò ní ibi tí yóo gbé orí rẹ̀ lé.” Ó bá sọ fún ẹlòmíràn pé, “Máa tẹ̀lé mi.” Ṣugbọn onítọ̀hún dáhùn pé, “Alàgbà, jẹ́ kí n kọ́ lọ sìnkú baba mi ná.” Ṣugbọn Jesu sọ fún un pé, “Jẹ́ kí àwọn òkú máa sin òkú ara wọn. Ìwọ ní tìrẹ, wá máa waasu ìjọba Ọlọrun.” Ẹlòmíràn tún sọ fún un pé, “N óo tẹ̀lé ọ Oluwa. Ṣugbọn jẹ́ kí n kọ́kọ́ lọ dágbére fún àwọn ará ilé mi.” Ṣugbọn Jesu sọ pé, “Kò sí ẹni tí ó bá ti dá ọwọ́ lé lílo ẹ̀rọ-ìroko, tí ó bá tún ń wo ẹ̀yìn tí ó yẹ fún ìjọba Ọlọrun.”

Luk 9:51-62 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà tí ọjọ́ àti gbà á sókè ń súnmọ́, ó pinnu láti lọ sí Jerusalẹmu. Ó sì rán àwọn ìránṣẹ́ lọ sí iwájú rẹ̀. Nígbà tí wọ́n sì lọ wọ́n wọ ìletò kan tí í ṣe ti ará Samaria láti pèsè sílẹ̀ dè é. Wọn kò sì gbà á, nítorí pé ó ń lọ sí Jerusalẹmu. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ Jakọbu àti Johanu sì rí i, wọ́n ní, “Olúwa wa, jẹ́ kí a pe iná láti ọ̀run wá, kí a sì pa wọ́n run, bí Elijah ti ṣe?” Ṣùgbọ́n Jesu yípadà, ó sì bá wọn wí, ó ní, ẹ̀yin kò mọ irú ẹ̀mí tí ń bẹ nínú yín Nítorí ọmọ ènìyàn kò wá láti pa ẹ̀mí ènìyàn run, bí kò ṣe láti gbà á là. Wọ́n sì lọ sí ìletò mìíràn. Bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà, ọkùnrin kan wí fún un pé, “Olúwa, Èmi ń fẹ́ láti máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ní ibikíbi tí ìwọ bá ń lọ.” Jesu sì wí fún un pé, “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ní ìtẹ́; ṣùgbọ́n ọmọ ènìyàn kò ní ibi tí yóò fi orí rẹ̀ lé.” Ó sì wí fún ẹlòmíràn pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn.” Ṣùgbọ́n èyí wí fún un pé, “Olúwa, jẹ́ kí èmi lọ sìnkú baba mi ná.” Jesu sì wí fún un pé, “Jẹ́ kí àwọn òkú máa sìnkú ara wọn: ṣùgbọ́n ìwọ lọ kí o sì máa wàásù ìjọba Ọlọ́run.” Ẹlòmíràn sì wí fún un pé, “Olúwa, èmi yóò tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ṣùgbọ́n jẹ́ kí n kọ́kọ́ lọ dágbére fún àwọn ará ilé mi.” Jesu sì wí fún un pé, “Kò sí ẹni, tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ lé ohun èlò ìtulẹ̀, tí ó sì wo ẹ̀yìn, tí ó yẹ fún ìjọba Ọlọ́run.”