Luk 9:18-21
Luk 9:18-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe, nigbati o kù on nikan, o ngbadura, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si wà lọdọ rẹ̀: o si bi wọn pe, Tali awọn enia nfi emi pè? Nwọn si dahùn wipe, Johanu Baptisti; ṣugbọn ẹlomiran ni, Elijah ni; ati awọn ẹlomiran wipe, ọkan ninu awọn woli atijọ li o jinde. O si bi wọn pe, Ṣugbọn tali ẹnyin nfi emi ipè? Peteru si dahùn, wipe, Kristi ti Ọlọrun. O si kìlọ fun wọn, o si paṣẹ fun wọn, pe, ki nwọn ki o máṣe sọ ohun na fun ẹnikan.

Luk 9:18-21 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ kan, nígbà tí Jesu nìkan ń dá gbadura tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Ó bi wọ́n pé, “Ta ni àwọn eniyan rò pé mo jẹ́?” Wọ́n dáhùn pé, “Àwọn kan ní Johanu Onítẹ̀bọmi ni ọ́, ṣugbọn àwọn mìíràn ní, Elija ni ọ. Àwọn mìíràn tún sọ pé ọ̀kan ninu àwọn wolii àtijọ́ ni ó jí dìde.” Ó wá bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin ńkọ́? Ta ni ẹ rò pé mo jẹ́?” Peteru dáhùn pé, “Mesaya Ọlọrun ni ọ́.” Jesu wá kìlọ̀ fún wọn kí wọn má sọ fún ẹnikẹ́ni.
Luk 9:18-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì ṣe, nígbà tí ó ku òun nìkan ó gbàdúrà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀: ó sì bi wọ́n pé, “Ta ni àwọn ènìyàn ń fi mí pè?” Wọ́n sì dáhùn wí pé, “Johanu Onítẹ̀bọmi; ṣùgbọ́n ẹlòmíràn ní Elijah ni; àti àwọn ẹlòmíràn wí pé, ọ̀kan nínú àwọn wòlíì àtijọ́ ni ó jíǹde.” Ó sì bi wọ́n pé, “Ṣùgbọ́n ta ni ẹ̀yin ń fi èmi pè?” Peteru sì dáhùn, wí pe, “Kristi ti Ọlọ́run.” Ó sì kìlọ̀ fún wọn, pé, kí wọn má ṣe sọ èyí fún ẹnìkan.