Luk 6:32-35
Luk 6:32-35 Yoruba Bible (YCE)
“Bí ó bá jẹ́ pé àwọn tí ó fẹ́ràn yín nìkan ni ẹ fẹ́ràn kí ni fáàrí yín? Nítorí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pàápàá fẹ́ràn àwọn tí ó bá fẹ́ràn wọn. Bí ẹ bá ń ṣe rere sí àwọn tí wọn ń ṣe rere si yín, kí ni fáàrí yín? Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pàápàá ń ṣe bẹ́ẹ̀. Bí ẹ bá yá eniyan lówó tí ó jẹ́ ẹni tí ẹ nírètí pé yóo san án pada, kí ni fáàrí yín. Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pàápàá ń yá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ẹgbẹ́ wọn lówó kí wọn lè rí i gbà pada ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Ṣugbọn ẹ máa fẹ́ràn àwọn ọ̀tá yín; ẹ ṣoore. Ẹ máa yá eniyan lówó láì ní ìrètí láti gbà á pada. Èrè yín yóo pọ̀, ẹ óo wá jẹ́ ọmọ Ọ̀gá Ògo nítorí ó ń ṣoore fún àwọn aláìmoore ati àwọn eniyan burúkú.
Luk 6:32-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin bá fẹ́ àwọn tí ó fẹ́ yín, ọpẹ́ kí ni ẹ̀yin ní? Àwọn ‘ẹlẹ́ṣẹ̀’ pẹ̀lú ń fẹ́ àwọn tí ó fẹ́ wọn. Bí ẹ̀yin sì ṣoore fún àwọn tí ó ṣoore fún yín, ọpẹ́ kín ni ẹ̀yin ní? Àwọn ‘ẹlẹ́ṣẹ̀’ pẹ̀lú ń ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́. Bí ẹ̀yin bá fi fún ẹni tí ẹ̀yin ń retí láti rí gbà padà, ọpẹ́ kín ni ẹ̀yin ní? Àwọn ‘ẹlẹ́ṣẹ̀’ pẹ̀lú ń yá ‘ẹlẹ́ṣẹ̀,’ kí wọn lè gba ìwọ̀n bẹ́ẹ̀ padà. Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin fẹ́ àwọn ọ̀tá yín kí ẹ sì ṣoore, kí ẹ̀yin sì yá ẹlòmíràn, kí ẹ̀yin má ṣe retí láti rí nǹkan gbà padà; èrè yín yóò sì pọ̀, àwọn ọmọ Ọ̀gá-ògo ni a ó sì máa pè yín: nítorí tí ó ṣe rere fún aláìmoore àti fún ẹni búburú.
Luk 6:32-35 Bibeli Mimọ (YBCV)
Njẹ bi ẹnyin ba fẹ awọn ti o fẹ nyin, ọpẹ́ kili ẹnyin ni? awọn ẹlẹṣẹ pẹlu nfẹ́ awọn ti o fẹ wọn. Bi ẹnyin si ṣore fun awọn ti o ṣore fun nyin, ọpẹ́ kili ẹnyin ni? awọn ẹlẹṣẹ pẹlu nṣe bẹ̃ gẹgẹ. Bi ẹnyin si win wọn ni nkan lọwọ ẹniti ẹnyin ó reti ati ri gbà pada, ọpẹ́ kili ẹnyin ni? awọn ẹlẹṣẹ pẹlu nwin ẹlẹṣẹ, ki nwọn ki o le gbà iwọn bẹ̃ pada. Ṣugbọn ki ẹnyin ki o fẹ awọn ọtá nyin, ki ẹnyin ki o si ṣore, ki ẹnyin ki o si winni, ki ẹnyin ki o máṣe reti ati ri nkan gbà pada; ère nyin yio si pọ̀, awọn ọmọ Ọgá-ogo li a o si ma pè nyin: nitoriti o ṣeun fun alaimore ati fun ẹni-buburu.