Luk 6:20-21
Luk 6:20-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati o si gbé oju rẹ̀ soke si awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o ni, Alabukun-fun li ẹnyin òtoṣi: nitori ti nyin ni ijọba Ọlọrun. Alabukun-fun li ẹnyin ti ebi npa nisisiyi: nitoriti ẹ ó yo. Alabukun-fun li ẹnyin ti nsọkun nisisiyi: nitoriti ẹnyin ó rẹrin.
Luk 6:20-21 Yoruba Bible (YCE)
Ó bá gbé ojú sókè sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sọ fún wọn pé, “Ayọ̀ ń bẹ fún ẹ̀yin talaka, nítorí tiyín ni ìjọba Ọlọrun. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹ̀yin tí ebi ń pa nisinsinyii, nítorí ẹ óo yó. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sunkún nisinsinyii, nítorí ẹ óo rẹ́rìn-ín.
Luk 6:20-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí ó sì gbé ojú rẹ̀ sókè sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó ní: “Alábùkún fún ni ẹ̀yin òtòṣì, nítorí tiyín ni ìjọba Ọlọ́run. Alábùkún fún ni ẹ̀yin tí ebi ń pa nísinsin yìí; nítorí tí ẹ ó yóò. Alábùkún fún ni ẹ̀yin tí ń sọkún nísinsin yìí: nítorí tí ẹ̀yin ó rẹ́rìn-ín.