Luk 6:17-19
Luk 6:17-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ba wọn sọkalẹ, o si duro ni pẹ̀tẹlẹ, pẹlu ọ̀pọ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ati ọ̀pọ ijọ enia, lati gbogbo Judea, ati Jerusalemu, ati àgbegbe Tire on Sidoni, ti nwọn wá lati gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀, ati lati gbà dida ara kuro ninu arùn wọn; Ati awọn ti ara kan fun ẹmi aimọ́: a si mu wọn larada. Gbogbo ijọ enia si nfẹ fi ọwọ́ kàn a; nitoriti aṣẹ njade lara rẹ̀, o si mu gbogbo wọn larada.
Luk 6:17-19 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Jesu sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè pẹlu wọn, ó dúró ní ibi tí ilẹ̀ gbé tẹ́jú. Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ati ọ̀pọ̀ àwọn eniyan láti gbogbo Judia ati Jerusalẹmu ati Tire ati Sidoni, ní agbègbè ẹ̀bá òkun. Wọ́n wá gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ati pé kí ó lè wò wọ́n sàn kúrò ninu àìsàn wọn. Ó tún ń wo àwọn tí ẹ̀mí Èṣù ń dà láàmú sàn. Gbogbo àwọn eniyan ni ó ń wá a, kí wọ́n lè fi ọwọ́ kàn án nítorí agbára ń ti ara rẹ̀ jáde. Ó bá wo gbogbo wọn sàn.
Luk 6:17-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì bá wọn sọ̀kalẹ̀, ó sì dúró ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, àti ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn, láti gbogbo Judea, àti Jerusalẹmu, àti agbègbè Tire àti Sidoni, tí wọ́n wá láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti láti gba ìmúláradá kúrò nínú ààrùn wọn; Àti àwọn tí ara wọn kún fún ẹ̀mí àìmọ́; ni ó sì mú láradá. Gbogbo ìjọ ènìyàn sì ń fẹ́ láti fọwọ́ kàn án, nítorí tí àṣẹ ń jáde lára rẹ̀, ó sì mú gbogbo wọn láradá.