Luk 6:1-26

Luk 6:1-26 Bibeli Mimọ (YBCV)

O si ṣe li ọjọ isimi keji lẹhin ekini, Jesu kọja larin oko ọkà; awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si nya ipẹ́ ọkà, nwọn nfi ọwọ́ ra a jẹ. Awọn kan ninu awọn Farisi si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nṣe eyi ti kò yẹ lati ṣe li ọjọ isimi? Jesu si da wọn li ohùn, wipe, Ẹnyin kò kawe to bi eyi, bi Dafidi ti ṣe, nigbati ebi npa on tikararẹ̀ ati awọn ti o wà lọdọ rẹ̀; Bi o ti wọ̀ ile Ọlọrun lọ, ti o si mu akara ifihàn ti o jẹ, ti o si fifun awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀ pẹlu; ti kò yẹ fun u lati jẹ, bikoṣe fun awọn alufa nikanṣoṣo? O si wi fun wọn pe, Ọmọ-enia li oluwa ọjọ isimi. O si ṣe li ọjọ isimi miran, ti o wọ̀ inu sinagogu lọ, o si nkọ́ni: ọkunrin kan si mbẹ nibẹ̀ ti ọwọ́ rẹ̀ ọtún rọ. Ati awọn akọwe ati awọn Farisi nṣọ ọ, bi yio mu u larada li ọjọ isimi; ki nwọn ki o le ri ọna ati fi i sùn. Ṣugbọn o mọ̀ ìro inu wọn, o si wi fun ọkunrin na ti ọwọ́ rẹ̀ rọ pe, Dide, ki o si duro lãrin. O si dide duro. Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Emi o bi nyin lẽre ohunkan; O tọ́ lati mã ṣe ore li ọjọ isimi, tabi lati mã ṣe buburu? lati gbà ẹmí là, tabi lati pa a run? Nigbati o si wò gbogbo wọn yiká, o wi fun ọkunrin na pe, Nà ọwọ́ rẹ. O si ṣe bẹ̃: ọwọ́ rẹ̀ si pada bọ̀ sipò gẹgẹ bi ekeji. Nwọn si kún fun ibinu gbigbona; nwọn si ba ara wọn rò ohun ti awọn iba ṣe si Jesu. O si ṣe ni ijọ wọnni, o lọ si ori òke lọ igbadura, o si fi gbogbo oru na gbadura si Ọlọrun. Nigbati ilẹ si mọ́, o pè awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀: ninu wọn li o si yàn mejila, ti o si sọ ni Aposteli; Simoni, (ẹniti o si sọ ni Peteru,) ati Anderu arakunrin rẹ̀, Jakọbu ati Johanu, Filippi ati Bartolomeu, Matiu ati Tomasi, Jakọbu ọmọ Alfeu, ati Simoni ti a npè ni Selote, Ati Juda arakunrin Jakọbu, ati Judasi Iskariotu ti iṣe onikupani. O si ba wọn sọkalẹ, o si duro ni pẹ̀tẹlẹ, pẹlu ọ̀pọ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ati ọ̀pọ ijọ enia, lati gbogbo Judea, ati Jerusalemu, ati àgbegbe Tire on Sidoni, ti nwọn wá lati gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀, ati lati gbà dida ara kuro ninu arùn wọn; Ati awọn ti ara kan fun ẹmi aimọ́: a si mu wọn larada. Gbogbo ijọ enia si nfẹ fi ọwọ́ kàn a; nitoriti aṣẹ njade lara rẹ̀, o si mu gbogbo wọn larada. Nigbati o si gbé oju rẹ̀ soke si awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o ni, Alabukun-fun li ẹnyin òtoṣi: nitori ti nyin ni ijọba Ọlọrun. Alabukun-fun li ẹnyin ti ebi npa nisisiyi: nitoriti ẹ ó yo. Alabukun-fun li ẹnyin ti nsọkun nisisiyi: nitoriti ẹnyin ó rẹrin. Alabukun-fun li ẹnyin, nigbati awọn enia ba korira nyin, ti nwọn ba yà nyin kuro ninu ẹgbẹ wọn, ti nwọn ba gàn nyin, ti nwọn ba ta orukọ nyin nù bi ohun buburu, nitori Ọmọ-enia. Ki ẹnyin ki o yọ̀ ni ijọ na, ki ẹnyin ki o si fò soke fun ayọ̀: sá wò o, ère nyin pọ̀ li ọrun: nitori bẹ̃ gẹgẹ li awọn baba wọn ṣe si awọn woli. Ṣugbọn egbé ni fun ẹnyin ọlọrọ̀! nitoriti ẹnyin ti ri irọra nyin na. Egbé ni fun ẹnyin ti o yó! nitoriti ebi yio pa nyin. Egbé ni fun ẹnyin ti nrẹrin nisisiyi! nitoriti ẹnyin o gbàwẹ, ẹnyin o si sọkun. Egbé ni fun nyin, nigbati gbogbo enia ba nsọrọ nyin ni rere! nitori bẹ̃ gẹgẹ li awọn baba wọn ṣe si awọn eke woli.

Luk 6:1-26 Yoruba Bible (YCE)

Ní Ọjọ́ Ìsinmi kan, bí Jesu ti ń la oko ọkà kan kọjá, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí já ọkà, wọ́n ń fi ọwọ́ ra á, wọ́n bá ń jẹ ẹ́. Àwọn kan ninu àwọn Farisi sọ pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń ṣe ohun tí kò tọ́ ní Ọjọ́ Ìsinmi?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ṣé ẹ kò ì tíì ka ohun tí Dafidi ṣe nígbà tí ebi ń pa òun ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀? Bí ó ti wọ ilé Ọlọrun lọ, tí ó mú burẹdi tí ó wà lórí tabili níwájú Oluwa, tí ó jẹ ẹ́, tí ó tún fún àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́ àfi àwọn alufaa nìkan?” Jesu bá sọ fún wọn pé, “Ọmọ-Eniyan ni Oluwa Ọjọ́ Ìsinmi.” Nígbà tí ó di Ọjọ́ Ìsinmi mìíràn, Jesu wọ inú ilé ìpàdé lọ, ó ń kọ́ àwọn eniyan. Ọkunrin kan wà níbẹ̀ tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ rọ. Àwọn amòfin ati àwọn Farisi ń ṣọ́ Jesu bí yóo ṣe ìwòsàn ní Ọjọ́ Ìsinmi kí wọ́n lè rí ẹ̀sùn fi kàn án. Ṣugbọn ó ti mọ ohun tí wọn ń rò ní ọkàn wọn. Ó sọ fún ọkunrin náà tí ọwọ́ rẹ̀ rọ pé, “Dìde kí o dúró ní ààrin.” Ọkunrin náà bá dìde dúró. Jesu wá sọ fún wọn pé, “Mo bi yín, èwo ni ó bá òfin mu, láti ṣe nǹkan rere tabi nǹkan burúkú ní Ọjọ́ Ìsinmi? Láti gba ẹ̀mí là, tabi láti pa á run?” Ó wá wo gbogbo wọn yíká, ó sọ fún ọkunrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ.” Ó ṣe bẹ́ẹ̀. Ọwọ́ rẹ̀ bá bọ́ sípò. Inú wọn ru sókè, wọ́n wá ń bá ara wọn jíròrò nípa ohun tí wọn ìbá ṣe sí Jesu. Ní ọjọ́ kan, Jesu lọ sí orí òkè, ó lọ gbadura. Gbogbo òru ni ó fi gbadura sí Ọlọrun. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó yan àwọn mejila ninu wọn, tí ó pè ní aposteli. Àwọn ni Simoni tí ó sọ ní Peteru ati Anderu arakunrin rẹ̀, Jakọbu ati Johanu, Filipi ati Batolomiu, Matiu ati Tomasi, Jakọbu ọmọ Alfeu ati Simoni tí ó tún ń jẹ́ Seloti, Judasi ọmọ Jakọbu ati Judasi Iskariotu, ẹni tí ó di ọ̀dàlẹ̀. Nígbà tí Jesu sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè pẹlu wọn, ó dúró ní ibi tí ilẹ̀ gbé tẹ́jú. Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ati ọ̀pọ̀ àwọn eniyan láti gbogbo Judia ati Jerusalẹmu ati Tire ati Sidoni, ní agbègbè ẹ̀bá òkun. Wọ́n wá gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ati pé kí ó lè wò wọ́n sàn kúrò ninu àìsàn wọn. Ó tún ń wo àwọn tí ẹ̀mí Èṣù ń dà láàmú sàn. Gbogbo àwọn eniyan ni ó ń wá a, kí wọ́n lè fi ọwọ́ kàn án nítorí agbára ń ti ara rẹ̀ jáde. Ó bá wo gbogbo wọn sàn. Ó bá gbé ojú sókè sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sọ fún wọn pé, “Ayọ̀ ń bẹ fún ẹ̀yin talaka, nítorí tiyín ni ìjọba Ọlọrun. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹ̀yin tí ebi ń pa nisinsinyii, nítorí ẹ óo yó. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sunkún nisinsinyii, nítorí ẹ óo rẹ́rìn-ín. “Ayọ̀ ń bẹ fun yín nígbà tí àwọn eniyan bá kórìíra yín, tí wọ́n bá le yín ní ìlú bí arúfin, tí wọ́n bá kẹ́gàn yín, tí wọ́n bá fi orúkọ yín pe ibi, nítorí Ọmọ-Eniyan. Ẹ máa yọ̀ ní ọjọ́ náà, kí ẹ sì máa jó, nítorí èrè pọ̀ fun yín ní ọ̀run. Irú nǹkan báwọ̀nyí ni àwọn baba wọn ṣe sí àwọn wolii. “Ṣugbọn ẹ̀yin ọlọ́rọ̀ gbé, nítorí ẹ ti jẹ ìgbádùn tiyín tán! Ẹ̀yin tí ẹ yó nisinsinyii, ẹ gbé, nítorí ebi ń bọ̀ wá pa yín. Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń yọ̀ nisinsinyii, ẹ gbé, nítorí ọ̀fọ̀ óo ṣẹ̀ yín, ẹ óo sì sunkún. “Nígbà tí gbogbo eniyan bá ń ròyìn yín ní rere, ẹ gbé, nítorí bẹ́ẹ̀ ni àwọn baba wọn ṣe sí àwọn èké wolii.

Luk 6:1-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní ọjọ́ ìsinmi kejì, Jesu ń kọjá láàrín oko ọkà; àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì ń ya ìpẹ́ ọkà, wọ́n sì ń jẹ ẹ́. Àwọn kan nínú àwọn Farisi sì wí fún wọn pé, “ki lo de tí ẹ̀yin fi ń ṣe èyí tí kò yẹ láti ṣe ní ọjọ́ ìsinmi?” Jesu sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin kò kà nípa ohun tí Dafidi ṣe, nígbà tí ebi ń pa òun tìkára rẹ̀ àti àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀; bi ó ti wọ ilé Ọlọ́run lọ, tí ó sì mú àkàrà ìfihàn tí ó sì jẹ ẹ́, tí ó sì fi fún àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú; tí kò yẹ fún un láti jẹ, bí kò ṣe fún àwọn àlùfáà nìkan ṣoṣo?” Ó sì wí fún wọn pé, “Ọmọ ènìyàn ni Olúwa ọjọ́ ìsinmi.” Ní ọjọ́ ìsinmi mìíràn, ó wọ inú Sinagọgu lọ, ó sì ń kọ́ni, ọkùnrin kan sì ń bẹ níbẹ̀ tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ rọ. Àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisi ń ṣọ́ ọ, bóyá yóò mú un láradá ní ọjọ́ ìsinmi; kí wọn lè rí ọ̀nà láti fi ẹ̀sùn kàn án. Ṣùgbọ́n ó mọ èrò inú wọn, ó sì wí fún ọkùnrin náà tí ọwọ́ rẹ̀ rọ pé, “Dìde, kí o sì dúró láàrín.” Ó sì dìde dúró. Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Èmi bi yín léèrè, Ó ha tọ́ láti máa ṣe rere ni ọjọ́ ìsinmi, tàbí láti máa ṣe búburú? Láti gba ọkàn là, tàbí láti pa á run?” Nígbà tí ó sì wo gbogbo wọn yíká, ó wí fún ọkùnrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ.” Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀: ọwọ́ rẹ̀ sì padà bọ̀ sípò gẹ́gẹ́ bí èkejì. Wọ́n sì kún fún ìbínú gbígbóná; wọ́n sì bá ara wọn rò ohun tí àwọn ìbá ṣe sí Jesu. Ni ọ̀kan nínú àwọn ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, Jesu lọ sí orí òkè láti gbàdúrà, ó sì fi gbogbo òru náà gbàdúrà sí Ọlọ́run. Nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀; nínú wọn ni ó sì yan méjìlá, tí ó sì sọ ní aposteli: Simoni (ẹni tí a pè ní Peteru) àti Anderu arákùnrin rẹ̀, Jakọbu, Johanu, Filipi, Bartolomeu, Matiu, Tomasi, Jakọbu ọmọ Alfeu, Simoni tí a ń pè ní Sealoti, Judea arákùnrin Jakọbu, àti Judasi Iskariotu tí ó di ọ̀dàlẹ̀. Ó sì bá wọn sọ̀kalẹ̀, ó sì dúró ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, àti ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn, láti gbogbo Judea, àti Jerusalẹmu, àti agbègbè Tire àti Sidoni, tí wọ́n wá láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti láti gba ìmúláradá kúrò nínú ààrùn wọn; Àti àwọn tí ara wọn kún fún ẹ̀mí àìmọ́; ni ó sì mú láradá. Gbogbo ìjọ ènìyàn sì ń fẹ́ láti fọwọ́ kàn án, nítorí tí àṣẹ ń jáde lára rẹ̀, ó sì mú gbogbo wọn láradá. Nígbà tí ó sì gbé ojú rẹ̀ sókè sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó ní: “Alábùkún fún ni ẹ̀yin òtòṣì, nítorí tiyín ni ìjọba Ọlọ́run. Alábùkún fún ni ẹ̀yin tí ebi ń pa nísinsin yìí; nítorí tí ẹ ó yóò. Alábùkún fún ni ẹ̀yin tí ń sọkún nísinsin yìí: nítorí tí ẹ̀yin ó rẹ́rìn-ín. Alábùkún fún ni ẹ̀yin, nígbà tí àwọn ènìyàn bá kórìíra yín, tí wọ́n bá yà yín kúrò nínú ẹgbẹ́ wọn, tí wọ́n bá gàn yín, tí wọ́n bá ta orúkọ yín nù bí ohun búburú, nítorí ọmọ ènìyàn. “Ẹ jẹ́ kí inú yín dùn, kí ẹ sì fò fún ayọ̀, nítorí púpọ̀ ní èrè yín ni ọ̀run. Báyìí ni àwọn baba yín ṣe ṣe sí àwọn wòlíì. “Ègbé ni fún ẹ̀yin ọlọ́rọ̀ nítorí ẹ ti gba ìtùnú yín. Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ó yó, nítorí ebi yóò pa yín, Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ń rẹ́rìn-ín nísinsin yìí, nítorí tí ẹ̀yin ó ṣọ̀fọ̀, ẹ̀yin ó sì sọkún. Ègbé ni fún yín, nígbà tí gbogbo ènìyàn bá ń sọ̀rọ̀ yín ní rere, nítorí bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwọn baba wọn ṣe sí àwọn wòlíì èké.