Luk 5:5-8
Luk 5:5-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Simoni si dahùn o si wi fun u pe, Olukọni, gbogbo oru aná li awa fi ṣìṣẹ, awa kò si mú nkan: ṣugbọn nitori ọrọ rẹ emi ó jù àwọn na si isalẹ. Nigbati nwọn si ti ṣe eyi, nwọn kó ọpọlọpọ ẹja: àwọn wọn si ya. Nwọn si ṣapẹrẹ si ẹgbẹ wọn, ti o wà li ọkọ̀ keji, ki nwọn ki o wá ràn wọn lọwọ. Nwọn si wá, nwọn si kún ọkọ̀ mejeji, bẹ̃ni nwọn bẹ̀rẹ si irì. Nigbati Simoni Peteru si ri i, o wolẹ lẹba ẽkun Jesu, o wipe, Lọ kuro lọdọ mi; nitori ẹlẹṣẹ ni mi, Oluwa.
Luk 5:5-8 Yoruba Bible (YCE)
Simoni dáhùn pé, “Alàgbà, gbogbo òru ni a fi ṣiṣẹ́ láì rí ohunkohun pa, ṣugbọn nítorí ọ̀rọ̀ rẹ, n óo da àwọ̀n sí omi.” Nígbà tí ó dà á sinu omi, ẹja tí ó kó pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí àwọ̀n fẹ́ ya. Wọ́n bá ṣe àmì sí àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tí ó wà ninu ọkọ̀ keji pé kí wọ́n wá ràn wọ́n lọ́wọ́. Nígbà tí wọ́n dé, wọ́n da ẹja kún inú ọkọ̀ mejeeji, tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi fẹ́ rì. Nígbà tí Simoni Peteru rí i, ó kúnlẹ̀ níwájú Jesu, ó ní “Kúrò lọ́dọ̀ mi, nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí, Oluwa.”
Luk 5:5-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Simoni sì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Olùkọ́ni, gbogbo òru ni àwa fi ṣiṣẹ́, àwa kò sì mú nǹkan kan: ṣùgbọ́n nítorí ọ̀rọ̀ rẹ èmi ó ju àwọ̀n náà sí ìsàlẹ̀.” Nígbà tí wọ́n sì ti ṣe èyí, wọ́n kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹja: àwọ̀n wọn sì ya. Wọ́n sì pe àwọn ẹgbẹ́ wọn, tí ó wà nínú ọkọ̀ kejì, kí wọn kí ó wá ràn wọ́n lọ́wọ́. Wọ́n sì wá, wọ́n kó ẹja ọkọ̀ méjèèjì sì kún, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í rì. Nígbà tí Simoni Peteru sì rí i, ó wólẹ̀ lẹ́bàá eékún Jesu, ó wí pé, “Lọ kúrò lọ́dọ̀ mi Olúwa; nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí.”