Luk 5:4-5
Luk 5:4-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi o si ti dakẹ ọ̀rọ isọ, o wi fun Simoni pe, Tì si ibu, ki o si jù àwọn nyin si isalẹ fun akopọ̀. Simoni si dahùn o si wi fun u pe, Olukọni, gbogbo oru aná li awa fi ṣìṣẹ, awa kò si mú nkan: ṣugbọn nitori ọrọ rẹ emi ó jù àwọn na si isalẹ.
Pín
Kà Luk 5Luk 5:4-5 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó parí ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ, ó sọ fún Simoni pé, “Tu ọkọ̀ lọ sí ibú, kí o da àwọ̀n sí omi kí ó lè pa ẹja.” Simoni dáhùn pé, “Alàgbà, gbogbo òru ni a fi ṣiṣẹ́ láì rí ohunkohun pa, ṣugbọn nítorí ọ̀rọ̀ rẹ, n óo da àwọ̀n sí omi.”
Pín
Kà Luk 5Luk 5:4-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí ó sì ti dákẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ, ó wí fún Simoni pé, “Tì í sí ibú, kí o sì ju àwọ̀n yín sí ìsàlẹ̀ fún àkópọ̀.” Simoni sì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Olùkọ́ni, gbogbo òru ni àwa fi ṣiṣẹ́, àwa kò sì mú nǹkan kan: ṣùgbọ́n nítorí ọ̀rọ̀ rẹ èmi ó ju àwọ̀n náà sí ìsàlẹ̀.”
Pín
Kà Luk 5