Luk 5:36-39
Luk 5:36-39 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si pa owe kan fun wọn pẹlu pe, Kò si ẹniti ifi idãsa aṣọ titun lẹ ogbologbo ẹ̀wu; bikoṣepe titun fà a ya, ati pẹlu idãsà titun kò si ba ogbologbo aṣọ rẹ. Kò si si ẹniti ifi ọti-waini titun sinu ogbologbo ìgo; bikoṣepe ọti-waini titun bẹ́ ìgo na, a si danù, ìgo a si bajẹ. Ṣugbọn ọti-waini titun li a ifi sinu igo titun; awọn mejeji a si ṣe dede. Kò si si ẹniti imu ìsà ọti-waini tan, ti o si fẹ titun lojukanna: nitoriti o ni, ìsà san jù.
Luk 5:36-39 Yoruba Bible (YCE)
Jesu wá pa òwe kan fún wọn pé, “Kò sí ẹni tí ó jẹ́ ya lára ẹ̀wù titun kí ó fi lẹ ògbólógbòó ẹ̀wù. Bí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó ti ba ẹ̀wù titun jẹ́, aṣọ titun tí ó sì fi lẹ ògbólógbòó ẹ̀wù kò bá ara wọn mu. Kò sí ẹni tíí fi ọtí titun sinu ògbólógbòó àpò awọ. Bí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ọtí titun yóo bẹ́ àpò, ọtí yóo tú dànù, àpò yóo sì tún bàjẹ́. Ṣugbọn ninu àpò awọ titun ni wọ́n ń fi ọtí titun sí. Kò sí ẹni tí ó bá ti mu ọtí tí ó mú, tíí fẹ́ mu ọtí àṣẹ̀ṣẹ̀pọn. Nítorí yóo sọ pé, ‘Ọtí tí ó mú ni ó dára.’ ”
Luk 5:36-39 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì pa òwe yìí fún wọn wí pé: “Kò sí ẹni tó lè ya aṣọ tuntun kí ó sì rán mọ́, èyí tó ti gbó. Tí ó ba ṣe èyí, yóò ba aṣọ tuntun jẹ́, èyí tí ó tuntun náà kì yóò sì dọ́gba pẹ̀lú èyí tí ó ti gbó. Àti wí pé, kò sí ẹni tí ó lè dá ọtí wáìnì tuntun sínú ògbólógbòó ìgò-awọ, tí ó bá ṣe èyí, wáìnì tuntun yóò fa awọ náà ya, wáìnì náà yóò dànù, awọ náà a sì bàjẹ́. Nítorí náà, ó tọ́ kí á da wáìnì tuntun sínú awọ tuntun. Kò sì ẹni tí yóò fẹ́ láti mu wáìnì tuntun lẹ́yìn tí ó bá ti mu ògbólógbòó tán, nítorí yóò wí pé, ‘Èyí tí ó jẹ́ ògbólógbòó dára jù.’ ”