Luk 5:2-11

Luk 5:2-11 Yoruba Bible (YCE)

Ó rí àwọn ọkọ̀ meji létí òkun. Àwọn apẹja ti kúrò ninu àwọn ọkọ̀ yìí, wọ́n ń fọ àwọ̀n wọn. Jesu bá wọ inú ọ̀kan ninu àwọn ọkọ̀ náà tí ó jẹ́ ti Simoni, ó ní kí wọ́n tù ú kúrò létí òkun díẹ̀. Ni ó bá jókòó ninu ọkọ̀, ó ń kọ́ àwọn eniyan. Nígbà tí ó parí ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ, ó sọ fún Simoni pé, “Tu ọkọ̀ lọ sí ibú, kí o da àwọ̀n sí omi kí ó lè pa ẹja.” Simoni dáhùn pé, “Alàgbà, gbogbo òru ni a fi ṣiṣẹ́ láì rí ohunkohun pa, ṣugbọn nítorí ọ̀rọ̀ rẹ, n óo da àwọ̀n sí omi.” Nígbà tí ó dà á sinu omi, ẹja tí ó kó pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí àwọ̀n fẹ́ ya. Wọ́n bá ṣe àmì sí àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tí ó wà ninu ọkọ̀ keji pé kí wọ́n wá ràn wọ́n lọ́wọ́. Nígbà tí wọ́n dé, wọ́n da ẹja kún inú ọkọ̀ mejeeji, tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi fẹ́ rì. Nígbà tí Simoni Peteru rí i, ó kúnlẹ̀ níwájú Jesu, ó ní “Kúrò lọ́dọ̀ mi, nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí, Oluwa.” Nítorí ẹnu yà á ati gbogbo àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ fún ọpọlọpọ ẹja tí wọ́n rí pa. Ẹnu ya Jakọbu náà ati Johanu, àwọn ọmọ Sebede, tí wọ́n jẹ́ ẹlẹgbẹ́ Simoni. Jesu wá sọ fún Peteru pé, “Má bẹ̀rù. Láti ìgbà yìí lọ eniyan ni ìwọ yóo máa mú wá.” Nígbà tí wọ́n tu ọkọ̀ dé èbúté, wọ́n fi ohun gbogbo sílẹ̀, wọ́n ń tẹ̀lé e.

Luk 5:2-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ó rí ọkọ̀ méjì ti o wá létí adágún: èyí tí àwọn apẹja ti sọ̀kalẹ̀ kúrò nínú wọn, nítorí tí wọ́n ń fọ àwọ̀n wọn. Ó sì wọ ọ̀kan nínú àwọn ọkọ̀ náà, tí í ṣe ti Simoni, ó sì bẹ̀ ẹ́ kí ó tì í sí ẹ̀yìn díẹ̀ kúrò ní ilẹ̀. Ó sì jókòó, ó sì ń kọ́ ìjọ ènìyàn láti inú ọkọ̀ náà. Bí ó sì ti dákẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ, ó wí fún Simoni pé, “Tì í sí ibú, kí o sì ju àwọ̀n yín sí ìsàlẹ̀ fún àkópọ̀.” Simoni sì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Olùkọ́ni, gbogbo òru ni àwa fi ṣiṣẹ́, àwa kò sì mú nǹkan kan: ṣùgbọ́n nítorí ọ̀rọ̀ rẹ èmi ó ju àwọ̀n náà sí ìsàlẹ̀.” Nígbà tí wọ́n sì ti ṣe èyí, wọ́n kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹja: àwọ̀n wọn sì ya. Wọ́n sì pe àwọn ẹgbẹ́ wọn, tí ó wà nínú ọkọ̀ kejì, kí wọn kí ó wá ràn wọ́n lọ́wọ́. Wọ́n sì wá, wọ́n kó ẹja ọkọ̀ méjèèjì sì kún, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í rì. Nígbà tí Simoni Peteru sì rí i, ó wólẹ̀ lẹ́bàá eékún Jesu, ó wí pé, “Lọ kúrò lọ́dọ̀ mi Olúwa; nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí.” Ẹnu sì yà wọ́n, àti gbogbo àwọn tí ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀, fún àkópọ̀ ẹja tí wọ́n kó: Bẹ́ẹ̀ ni Jakọbu àti Johanu àwọn ọmọ Sebede, tí ń ṣe alábákẹ́gbẹ́ Simoni. Jesu sì wí fún Simoni pé, “Má bẹ̀rù; láti ìsinsin yìí lọ ìwọ ó máa mú ènìyàn.” Nígbà tí wọ́n sì ti mú ọkọ̀ wọn dé ilẹ̀, wọ́n fi gbogbo rẹ̀ sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn lọ.