Luk 5:17-26

Luk 5:17-26 Bibeli Mimọ (YBCV)

O si ṣe ni ijọ kan, bi o si ti nkọ́ni, awọn Farisi ati awọn amofin joko ni ìha ibẹ̀, awọn ti o ti ilu Galili gbogbo, ati Judea, ati Jerusalemu wá: agbara Oluwa si mbẹ lati mu wọn larada. Sá si kiyesi i, awọn ọkunrin gbé ọkunrin kan ti o lẹ̀gba wá lori akete: nwọn nwá ọ̀na ati gbé e wọle, ati lati tẹ́ ẹ siwaju rẹ̀. Nigbati nwọn kò si ri ọ̀na ti nwọn iba fi gbé e wọle nitori ijọ enia, nwọn gùn oke àja ile lọ, nwọn sọ̀ ọ kalẹ li alafo àja ti on ti akete rẹ̀ larin niwaju Jesu. Nigbati o si ri igbagbọ́ wọn, o wi fun u pe, Ọkunrin yi, a dari ẹ̀ṣẹ rẹ jì ọ. Awọn akọwe ati awọn Farisi bẹ̀rẹ si igberò, wipe, Tali eleyi ti nsọ ọrọ-odi? Tali o le dari ẹ̀ṣẹ jìni bikoṣe Ọlọrun nikanṣoṣo? Ṣugbọn nigbati Jesu mọ̀ ìro inu wọn, o dahùn o si wi fun wọn pe, Kili ẹnyin nrò ninu ọkàn nyin? Ewo li o ya jù, lati wipe, A dari ẹ̀ṣẹ rẹ jì ọ; tabi lati wipe, Dide ki iwọ ki o si mã rìn? Ṣugbọn ki ẹnyin ki o le mọ̀ pe, Ọmọ-enia li agbara li aiye lati dari ẹ̀ṣẹ jìni, (o wi fun ẹlẹgba na pe,) Mo wi fun ọ, Dide, si gbé akete rẹ, ki o si lọ si ile rẹ. O si dide lọgan niwaju wọn, o gbé ohun ti o dubulẹ le, o si lọ si ile rẹ̀, o nyìn Ọlọrun logo. Ẹnu si yà gbogbo wọn, nwọn si nyìn Ọlọrun logo, ẹ̀ru si bà wọn, nwọn nwipe, Awa ri ohun abàmi loni.

Luk 5:17-26 Yoruba Bible (YCE)

Ní ọjọ́ kan bí Jesu ti ń kọ́ àwọn eniyan, àwọn Farisi ati àwọn amòfin jókòó níbẹ̀. Wọ́n wá láti gbogbo ìletò Galili ati ti Judia ati láti Jerusalẹmu. Agbára Oluwa wà pẹlu Jesu láti fi ṣe ìwòsàn. Àwọn ẹnìkan gbé ọkunrin arọ kan wá tí ó dùbúlẹ̀ sórí ibùsùn rẹ̀. Wọ́n ń wá ọ̀nà láti gbé e dé iwájú Jesu. Nígbà tí wọn kò rí ọ̀nà gbé e dé ọ̀dọ̀ rẹ̀ nítorí ọ̀pọ̀ eniyan, wọ́n gbé e gun orí òrùlé. Wọ́n bá dá òrùlé lu kí wọ́n fi lè gbé arọ náà pẹlu ibùsùn rẹ̀ sí ààrin àwọn eniyan níwájú Jesu. Nígbà tí Jesu rí igbagbọ wọn, ó ní, “Arakunrin, a dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.” Àwọn amòfin ati àwọn Farisi bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn sọ pé, “Ta ni eléyìí tí ó ń sọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun báyìí? Ta ni lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji eniyan lẹ́yìn Ọlọrun nìkan ṣoṣo?” Jesu ti mọ ohun tí wọ́n ń bá ara wọn sọ, ó bá dá wọn lóhùn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń ro irú èrò báyìí ní ọkàn yín? Èwo ni ó rọrùn jù, láti sọ pé, ‘A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́ ni,’ tabi láti sọ pé, ‘Dìde kí o máa rìn’? Ṣugbọn kí ẹ lè mọ̀ pé Ọmọ-Eniyan ní àṣẹ ní ayé láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji eniyan ni,” ó bá sọ fún arọ náà pé, “Mo sọ fún ọ, dìde, gbé ibùsùn rẹ, kí o máa lọ sí ilé rẹ.” Lẹsẹkẹsẹ ó dìde lójú gbogbo wọn, ó gbé ibùsùn rẹ̀, ó lọ sí ilé rẹ̀, ó ń yin Ọlọrun lógo. Ẹnu ya gbogbo àwọn eniyan. Wọ́n ń yin Ọlọrun lógo. Ẹ̀rù bà wọ́n pupọ. Wọ́n ń sọ pé, “Ìròyìn kò tó àfojúbà ni ohun tí a rí lónìí!”

Luk 5:17-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní ọjọ́ kan, bí ó sì ti ń kọ́ni, àwọn Farisi àti àwọn amòfin jókòó pẹ̀lú rẹ̀, àwọn tí ó ti àwọn ìletò Galili gbogbo, àti Judea, àti Jerusalẹmu wá: agbára Olúwa sì ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ láti mú wọn láradá. Sá à sì kíyèsi i, àwọn Ọkùnrin kan gbé ẹnìkan tí ó ní ààrùn ẹ̀gbà wà lórí àkéte: wọ́n ń wá ọ̀nà àti gbé e wọlé, àti láti tẹ́ ẹ síwájú Jesu. Nígbà tí wọn kò sì rí ọ̀nà tí wọn ìbá fi gbé e wọlé nítorí ìjọ ènìyàn, wọ́n gbé e gun òkè àjà ilé lọ, wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ sí àárín èrò ti òun ti àkéte rẹ̀ níwájú Jesu. Nígbà tí ó sì rí ìgbàgbọ́ wọn, ó wí pé, “Ọkùnrin yìí, a darí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.” Àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisi bẹ̀rẹ̀ sí í gbèrò wí pé, “Ta ni eléyìí tí ń sọ ọ̀rọ̀-òdì? Ta ni ó lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni bí kò ṣe Ọlọ́run nìkan ṣoṣo.” Jesu sì mọ èrò inú wọn, ó dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ fi ń ro nǹkan wọ̀nyí nínú ọkàn yín? Èwo ni ó yá jù: láti wí pé, ‘A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́,’ tàbí láti wí pé, ‘Dìde kí ìwọ sì máa rìn’? Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè mọ̀ pé ọmọ ènìyàn ní agbára ní ayé láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni.” Ó wí fún ẹlẹ́gbà náà pé, “Mo wí fún ọ, dìde, sì gbé àkéte rẹ, kí o sì máa lọ sí ilé!” Ó sì dìde lọ́gán níwájú wọn, ó gbé ohun tí ó dùbúlẹ̀ lé, ó sì lọ sí ilé rẹ̀, ó yin Ọlọ́run lógo. Ẹnu sì ya gbogbo wọn, wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo, ẹ̀rù sì bà wọ́n, wọ́n ń wí pé, “Àwa rí ohun ìyanu lónìí.”