Luk 5:1-4
Luk 5:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Ní àkókò kan, bí Jesu ti dúró létí òkun Genesarẹti, ọ̀pọ̀ eniyan péjọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Ó rí àwọn ọkọ̀ meji létí òkun. Àwọn apẹja ti kúrò ninu àwọn ọkọ̀ yìí, wọ́n ń fọ àwọ̀n wọn. Jesu bá wọ inú ọ̀kan ninu àwọn ọkọ̀ náà tí ó jẹ́ ti Simoni, ó ní kí wọ́n tù ú kúrò létí òkun díẹ̀. Ni ó bá jókòó ninu ọkọ̀, ó ń kọ́ àwọn eniyan. Nígbà tí ó parí ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ, ó sọ fún Simoni pé, “Tu ọkọ̀ lọ sí ibú, kí o da àwọ̀n sí omi kí ó lè pa ẹja.”
Luk 5:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe, nigbati ijọ enia ṣù mọ́ ọ lati gbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun, ti o si duro leti adagun Genesareti, O ri ọkọ̀ meji ti nwọn gún leti adagun: ṣugbọn awọn apẹja sọkalẹ kuro ninu wọn, nwọn nfọ̀ àwọn wọn. O si wọ̀ ọkan ninu awọn ọkọ̀ na, ti iṣe ti Simoni, o si bẹ̀ ẹ ki o tẹ̀ si ẹhin diẹ kuro ni ilẹ. O si joko, o si nkọ́ ijọ enia lati inu ọkọ̀ na. Bi o si ti dakẹ ọ̀rọ isọ, o wi fun Simoni pe, Tì si ibu, ki o si jù àwọn nyin si isalẹ fun akopọ̀.
Luk 5:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì ṣe, nígbà tí ìjọ ènìyàn súnmọ́ ọn láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí ó sì dúró létí adágún Genesareti. Ó rí ọkọ̀ méjì ti o wá létí adágún: èyí tí àwọn apẹja ti sọ̀kalẹ̀ kúrò nínú wọn, nítorí tí wọ́n ń fọ àwọ̀n wọn. Ó sì wọ ọ̀kan nínú àwọn ọkọ̀ náà, tí í ṣe ti Simoni, ó sì bẹ̀ ẹ́ kí ó tì í sí ẹ̀yìn díẹ̀ kúrò ní ilẹ̀. Ó sì jókòó, ó sì ń kọ́ ìjọ ènìyàn láti inú ọkọ̀ náà. Bí ó sì ti dákẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ, ó wí fún Simoni pé, “Tì í sí ibú, kí o sì ju àwọ̀n yín sí ìsàlẹ̀ fún àkópọ̀.”