Luk 5:1-16

Luk 5:1-16 Bibeli Mimọ (YBCV)

O si ṣe, nigbati ijọ enia ṣù mọ́ ọ lati gbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun, ti o si duro leti adagun Genesareti, O ri ọkọ̀ meji ti nwọn gún leti adagun: ṣugbọn awọn apẹja sọkalẹ kuro ninu wọn, nwọn nfọ̀ àwọn wọn. O si wọ̀ ọkan ninu awọn ọkọ̀ na, ti iṣe ti Simoni, o si bẹ̀ ẹ ki o tẹ̀ si ẹhin diẹ kuro ni ilẹ. O si joko, o si nkọ́ ijọ enia lati inu ọkọ̀ na. Bi o si ti dakẹ ọ̀rọ isọ, o wi fun Simoni pe, Tì si ibu, ki o si jù àwọn nyin si isalẹ fun akopọ̀. Simoni si dahùn o si wi fun u pe, Olukọni, gbogbo oru aná li awa fi ṣìṣẹ, awa kò si mú nkan: ṣugbọn nitori ọrọ rẹ emi ó jù àwọn na si isalẹ. Nigbati nwọn si ti ṣe eyi, nwọn kó ọpọlọpọ ẹja: àwọn wọn si ya. Nwọn si ṣapẹrẹ si ẹgbẹ wọn, ti o wà li ọkọ̀ keji, ki nwọn ki o wá ràn wọn lọwọ. Nwọn si wá, nwọn si kún ọkọ̀ mejeji, bẹ̃ni nwọn bẹ̀rẹ si irì. Nigbati Simoni Peteru si ri i, o wolẹ lẹba ẽkun Jesu, o wipe, Lọ kuro lọdọ mi; nitori ẹlẹṣẹ ni mi, Oluwa. Hà si ṣe e, ati gbogbo awọn ti mbẹ pẹlu rẹ̀, fun akopọ̀ ẹja ti nwọn kó: Bẹ̃ ni Jakọbu ati Johanu awọn ọmọ Sebede, ti nṣe olupẹja pọ pẹlu Simoni. Jesu si wi fun Simoni pe, Má bẹ̀ru; lati isisiyi lọ iwọ o ma mú enia. Nigbati nwọn si ti mu ọkọ̀ wọn de ilẹ, nwọn fi gbogbo rẹ̀ silẹ, nwọn si tọ̀ ọ lẹhin lọ. O si ṣe, nigbati o wọ̀ ilu kan, kiyesi i, ọkunrin kan ti ẹ̀tẹ bò: nigbati o ri Jesu, o wolẹ, o si mbẹ̀ ẹ, wipe, Oluwa, bi iwọ ba fẹ, iwọ le sọ mi di mimọ́. O si nà ọwọ́ rẹ̀, o fi kàn a, o ni, Mo fẹ: iwọ di mimọ́. Lọgan ẹ̀tẹ si fi i silẹ lọ. O si kílọ fun u pe, ki o máṣe sọ fun ẹnikan: ṣugbọn ki o lọ, ki o si fi ara rẹ hàn fun alufa, ki o si ta ọrẹ fun iwẹnumọ́ rẹ, gẹgẹ bi Mose ti paṣẹ fun ẹrí si wọn. Ṣugbọn si iwaju li okikí rẹ̀ nkàn kalẹ: ọ̀pọ ijọ enia si jumọ pade lati gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀, ati lati gbà dida ara lọdọ rẹ̀ kuro lọwọ ailera wọn. O si yẹra si ijù, o si gbadura.

Luk 5:1-16 Yoruba Bible (YCE)

Ní àkókò kan, bí Jesu ti dúró létí òkun Genesarẹti, ọ̀pọ̀ eniyan péjọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Ó rí àwọn ọkọ̀ meji létí òkun. Àwọn apẹja ti kúrò ninu àwọn ọkọ̀ yìí, wọ́n ń fọ àwọ̀n wọn. Jesu bá wọ inú ọ̀kan ninu àwọn ọkọ̀ náà tí ó jẹ́ ti Simoni, ó ní kí wọ́n tù ú kúrò létí òkun díẹ̀. Ni ó bá jókòó ninu ọkọ̀, ó ń kọ́ àwọn eniyan. Nígbà tí ó parí ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ, ó sọ fún Simoni pé, “Tu ọkọ̀ lọ sí ibú, kí o da àwọ̀n sí omi kí ó lè pa ẹja.” Simoni dáhùn pé, “Alàgbà, gbogbo òru ni a fi ṣiṣẹ́ láì rí ohunkohun pa, ṣugbọn nítorí ọ̀rọ̀ rẹ, n óo da àwọ̀n sí omi.” Nígbà tí ó dà á sinu omi, ẹja tí ó kó pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí àwọ̀n fẹ́ ya. Wọ́n bá ṣe àmì sí àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tí ó wà ninu ọkọ̀ keji pé kí wọ́n wá ràn wọ́n lọ́wọ́. Nígbà tí wọ́n dé, wọ́n da ẹja kún inú ọkọ̀ mejeeji, tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi fẹ́ rì. Nígbà tí Simoni Peteru rí i, ó kúnlẹ̀ níwájú Jesu, ó ní “Kúrò lọ́dọ̀ mi, nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí, Oluwa.” Nítorí ẹnu yà á ati gbogbo àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ fún ọpọlọpọ ẹja tí wọ́n rí pa. Ẹnu ya Jakọbu náà ati Johanu, àwọn ọmọ Sebede, tí wọ́n jẹ́ ẹlẹgbẹ́ Simoni. Jesu wá sọ fún Peteru pé, “Má bẹ̀rù. Láti ìgbà yìí lọ eniyan ni ìwọ yóo máa mú wá.” Nígbà tí wọ́n tu ọkọ̀ dé èbúté, wọ́n fi ohun gbogbo sílẹ̀, wọ́n ń tẹ̀lé e. Ní àkókò kan nígbà tí Jesu wà ninu ìlú kan, ọkunrin kan tí ẹ̀tẹ̀ bò ní gbogbo ara rí i. Ó bá wá dojúbolẹ̀, ó ń bẹ̀ ẹ́ pé, “Alàgbà, bí o bá fẹ́, o lè sọ ara mi di mímọ́.” Jesu bá na ọwọ́, ó fi kàn án, ó ní, “Mo fẹ́ kí ara rẹ di mímọ́.” Lẹsẹkẹsẹ àrùn ẹ̀tẹ̀ náà fi í sílẹ̀. Jesu bá kìlọ̀ fún un pé, “Má ṣe sọ fún ẹnikẹ́ni, ṣugbọn lọ fi ara rẹ han alufaa, kí o ṣe ìrúbọ fún ìsọdi-mímọ́ rẹ, gẹ́gẹ́ bí Mose ti pàṣẹ. Èyí yóo jẹ́ ẹ̀rí fún wọn pé ara rẹ ti dá.” Ṣugbọn ńṣe ni ìròyìn rẹ̀ túbọ̀ ń tàn kálẹ̀. Ọ̀pọ̀ eniyan wá ń péjọ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ati kí ó lè wò wọ́n sàn kúrò ninu àìlera wọn. Ṣugbọn aṣálẹ̀ ni ó máa ń lọ láti dá gbadura.

Luk 5:1-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ó sì ṣe, nígbà tí ìjọ ènìyàn súnmọ́ ọn láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí ó sì dúró létí adágún Genesareti. Ó rí ọkọ̀ méjì ti o wá létí adágún: èyí tí àwọn apẹja ti sọ̀kalẹ̀ kúrò nínú wọn, nítorí tí wọ́n ń fọ àwọ̀n wọn. Ó sì wọ ọ̀kan nínú àwọn ọkọ̀ náà, tí í ṣe ti Simoni, ó sì bẹ̀ ẹ́ kí ó tì í sí ẹ̀yìn díẹ̀ kúrò ní ilẹ̀. Ó sì jókòó, ó sì ń kọ́ ìjọ ènìyàn láti inú ọkọ̀ náà. Bí ó sì ti dákẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ, ó wí fún Simoni pé, “Tì í sí ibú, kí o sì ju àwọ̀n yín sí ìsàlẹ̀ fún àkópọ̀.” Simoni sì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Olùkọ́ni, gbogbo òru ni àwa fi ṣiṣẹ́, àwa kò sì mú nǹkan kan: ṣùgbọ́n nítorí ọ̀rọ̀ rẹ èmi ó ju àwọ̀n náà sí ìsàlẹ̀.” Nígbà tí wọ́n sì ti ṣe èyí, wọ́n kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹja: àwọ̀n wọn sì ya. Wọ́n sì pe àwọn ẹgbẹ́ wọn, tí ó wà nínú ọkọ̀ kejì, kí wọn kí ó wá ràn wọ́n lọ́wọ́. Wọ́n sì wá, wọ́n kó ẹja ọkọ̀ méjèèjì sì kún, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í rì. Nígbà tí Simoni Peteru sì rí i, ó wólẹ̀ lẹ́bàá eékún Jesu, ó wí pé, “Lọ kúrò lọ́dọ̀ mi Olúwa; nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí.” Ẹnu sì yà wọ́n, àti gbogbo àwọn tí ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀, fún àkópọ̀ ẹja tí wọ́n kó: Bẹ́ẹ̀ ni Jakọbu àti Johanu àwọn ọmọ Sebede, tí ń ṣe alábákẹ́gbẹ́ Simoni. Jesu sì wí fún Simoni pé, “Má bẹ̀rù; láti ìsinsin yìí lọ ìwọ ó máa mú ènìyàn.” Nígbà tí wọ́n sì ti mú ọkọ̀ wọn dé ilẹ̀, wọ́n fi gbogbo rẹ̀ sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn lọ. Ó sì ṣe, nígbà tí Jesu wọ ọ̀kan nínú àwọn ìlú náà, kíyèsi i, ọkùnrin kan tí ẹ̀tẹ̀ bò wa síbẹ̀: nígbà tí ó rí Jesu, ó wólẹ̀, ó sì ń bẹ̀ ẹ́, wí pé, “Olúwa, bí ìwọ bá fẹ́, ìwọ lè sọ mí di mímọ́.” Jesu sì na ọwọ́ rẹ̀, ó fi kàn án, ó ní, “Mo fẹ́, ìwọ di mímọ́!” Lójúkan náà ẹ̀tẹ̀ sì fi í sílẹ̀ lọ. Ó sì kìlọ̀ fún u pé, “Kí ó má ṣe sọ fún ẹnìkan: ṣùgbọ́n kí ó lọ, kí ó sì fi ara rẹ̀ hàn fún àlùfáà, kí ó sì ta ọrẹ fún ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Mose ti pàṣẹ gẹ́gẹ́ bi ẹ̀rí fun wọn.” Ṣùgbọ́n òkìkí rẹ̀ ń kàn kálẹ̀: tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì jùmọ̀ pàdé láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti láti gba ìwòsàn lọ́dọ̀ rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àìlera wọn. Ṣùgbọ́n lọ́pọ̀ ìgbà ni Jesu a máa yẹra kúrò si ibi ìdákẹ́rọ́rọ́, òun á sì máa dá wà láti gbàdúrà.